Àwọn olùfẹ̀hónúhàn 1,200 wọ gaù ní Brazil

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Brazil ti kede pe o to eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun meji ti yoo fi oju ba ile ẹjọ latari bi wọn ṣe kopa ninu ifẹhonuhan nile asofin Brazil.
Awọn alasẹ ni ọjọ marun un lati fi wọ awọn olufẹhonuhan to wa akata awọn ọlọpaa lọ si ile ẹjọ.
Ijọba ni wọn ti tun awọn miirsn silẹ ti wọn si ti kilọ fun wọn lati yago ninu iwa panle ti wọn fi ṣe ifẹhonuhan ọhun.
Bakan na ni wọn ni awọn si le pe wọn pada ti awọn ba nilọ wọn iwadii ti wọn n ṣe lọwọ bayii.
Ninu atẹjade kan to bọ sọwọ ileeṣẹ BBC, ijọba ni o ṣeṣe ki iwọdi miiran tu waye lati ọdọ awọn ololufẹ Aarẹ tẹlẹ lorilẹede naa. Jair Bolsonaro.
Yatọ si awọn olufẹhonuhan, Ijọba fi ofin de awọn ileeṣẹ to pese irin naa fun awọn olufẹhonuhan naa, ti wọn yoo si tun san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun owo ilẹ Brazil
Ijọba tun ti kedi awọn oludari ayelujara lati fi ofin de awọn kan ti wọn lo ayelujara lati darapọ ifẹhonuhan naa tabi ti wọn ni erongba lati bẹrẹ ifwọde miiran lorilẹede naa.
Ọjọ isẹgun ni ile igbimọ asofin lorilẹede naa buwọlu ofin ti fun awọn ọmọ ologun ni anfani lati pese aabo lorilẹede naa.















