Mo ná ₦60 mílíọ̀nù lórí Ummul Sani torí ìfẹ́ tí mo ni síi- Geng-Quangrong

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ọkunrin kan ọmọ orilẹede China, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, Frank Geng Quangrong ti sọrọ nile ẹjọ giga nipinlẹ Kano, lori ẹsun ti wọn fi kan pe o ṣekupa ọrẹbinrin rẹ, Ummukuthum Sani.

Geng ni oun ti na ọwọ to ju ọgọta milọnu naira lori ololufẹ oun, ẹni ọdun mejidinlogun, Ummukulthum Sani.

Ninu alaye rẹ, Geng ni oun salabapade Ummukulthum lati ọdọ ọrẹ oun kan, ti wọn si bẹrẹ ere ifẹ.

O ni, “ Ninu oṣu kẹfa lọdun 2020, Ummukulthum gba nọmba mi lọwọ ọrẹ rẹ, to si pe mi pe oun nifẹ mi, ati pe lagbara Ọlọrun, emi ni maa fẹ gẹgẹ bii iyawo.

“A bẹrẹ ere ifẹ lọdun 2020, to si bẹrẹ si ni bere owo lọwọ mi. Mo ma fun ni owo to ba bere fun nitori mo nifẹ rẹ.

“Mo fi Ọgọta milọnu ransẹ si ile fowopamọ rẹ, mo tun fun ni milọnu mejidinlogun ko fi bẹrẹ okowo, ati milọnu mẹrin fun eto ẹkọ rẹ lọ si fasiti.

Ohun to dun mi ju ni Ummukulthum lọ ṣe igbeyawo pẹlu Ọkunrin miiran yatọ si emi

Geng tẹsiwaju pe nigba to di ninu oṣu keji ọdun 2022, ni oun gbọ pe Ummukulthum ti ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin miiran, to si jẹ ẹdun ọkan fun oun pupọ, ti oun si gbera lọ si ilu Abuja .

“Ko dẹkun lati maa pemi, yoo tun bami sọrọ lori opo ibanidọrẹ Whatsapp, ti yoo si tun ma bere owo lọwọ mi.”

O ni lọjọ kẹtala, oṣu kẹsan an ọdun 2022, Ummukulthum bere owo lọwọ oun lati fi pari ile to n kọ lọwọ niluu Abuja.

Geng ni oun sọ fun Ummulthum pe oun ko lowo lọwọ lati fun ni o ba kọ lati maa gbe ipe oun ti oun ba ti pe.

“O ro pe n ko lowo lọwọ nitori n ko fun lowo bi ti tẹlẹ , o wa sọ fun mi pe oun ti ni ọkunrin miiran, to si fi aworan ọkunrin na ransẹ si lori Whatsapp, eyi to bimi ninu gan.

Ki ni ileẹjọ sọ?

Awọn olupẹjọ ni awọn n tẹle bii Geng ṣe sọrọ nile ẹjọ.

Hajiya Aisha Mahmud to jẹ ọga agba ni ileesẹ ijọba to n risi idajọ ni ki ileẹjọ fun awọn naa ni anfani lati ẹlẹrii wa si ileẹjọ.

“A ti bere lọwọ ileẹjọ lati jẹ ka pe ẹlẹri wa, ẹ sọ fun ileẹjọ ki wọn pe elẹri wa pada.

“A ko mọ iye ẹlẹri to fẹ pe nitori o sẹsẹ bẹrẹ loni.”

Adajọ Sanusi Ado ti wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejila ọsu kini ọdun 2023.