Seyi Makinde ni mo n ṣe àtìlẹyìn ìbò gómínà fún l‘Oyo, kìí ṣe Teslim Folarin - Niyi Akintola

Niyi Akintola: Torí Tinubu ni mo ṣe kun àwọn mọ́tò ìpolongo ní ọ̀dà APC, kìí ṣe torí Folarin

aworan

Oríṣun àwòrán, Mallam kajola/Facebook

Oloye Adeniyi Akintola tii se eekan gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti kede pe oun ko fi igba kankan bu ọwọ lu oludije sipo gomina fẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, Teslim Folarin.

Amọ o wa fọwọ gbaya pe gbọingbọin ni oun wa lẹyin oludije gomina fẹgbẹ oselu PDP, Seyi Makinde lati se saa keji lori aleefa.

Akintola sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan to fisita ni Ọjọbọ lẹyin ti aworan rẹ ati Teslim Folarin gba igboro kan.

Agba amofin naa salaye pe oun ti yẹba ninu ọrọ oṣelu orilẹ-ede yii, gbogbo nnkan ti oun si n se lọwọ lọwọ lo wa lati inu ọkan.

O wa yan pe oun ko fi igba kankan ṣe atilẹyin fun Teslim Folarin amọ gomina Seyi Makinde ni oun n ba lọ ninu ibo gomina.

"Alaga APC l‘Oyo ati ọrẹ mi n bẹ mi ninu baalu lati satilẹyin fun Folarin amọ n ko gba"

Agba amofin Adeniyi Akintola tun fikun pe erongba oun ni lati ri wi pe ẹnikẹni ti yoo ba wọle gẹgẹ bi aarẹ tabi gomina ipinlẹ Oyo gbọdọ ni ifẹ araalu lọkan.

O ni idi ree ti oun fi n se atilẹyin fun Bola Tinubu gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ fẹgbẹ APC ati Gomina Seyi Makinde, oludije gomina fẹgbẹ PDP nipinlẹ Oyo.

Akintola, ninu atẹjade naa ṣalaye bo ti pade alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Isaac Omodewu ninu baalu lẹnu irinajo rẹ pada si Ibadan lati Abuja.

O sọ gbangba pe Omodewu ati ọrẹ oun kan tí ko darukọ, gbiyanju lati bẹ oun oun fun atilẹyin Teslim Folarin amọ oun ko gba.

O ni gbogbo mọto ti oun kun ni ọda APC ati aworan Tinubu lo wa fun lilo fun ipolongo Bola Tinubu nikan, kii se fun ti Folarin.