Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọmọdékùnrin ẹni ọdún 17 lórí ẹ̀sun pé o fún obìnrin mẹ́wàá lọ́yún

Oríṣun àwòrán, others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti ni ọwọ awọn ti tẹ ọmọkunrin kan, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Noble Uzuchi ati Chigozie Ogbonna, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn fun ẹsun pe wọn sisẹ pẹlu awọn agbọmọta, ti wọn si fun awọn obinrin mẹwaa lọyun.
Bakan an ni ọwọ tun tẹ awọn obinrin meji miiran, Favour Bright, ẹni ọgbọn ọdun ati Peace Alikoi, ẹni ogoji ọdun, to jẹ olori awọn agbọmọta.
Awọn afurasi mẹrin ọhun ni wọn ṣe isẹ labi wọn ni agbegbe Obio/Akpor nijọba ibilẹ Ikwerre nipinlẹ Rivers
Ileeṣẹ ọlọpaa tun kede pe awọn dọla awọn obinrin lọyun mẹwaa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Grace Iringe Koko, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin niluu Port Harcourt lọjọ Isẹgun ni kete ti awọn kẹfin awọn afurasi ni awọn yabo fun ni ibudo wọn.
“Lọjo keje, oṣu kinni, ọdun 2023, ni bi ago marun un ku isẹju diẹ ni a gbọ iroyin naa, ti a si yabo ile meji ni Igwuruta ati Omagwe ni bi ọwọ ti awọn afurasi naa.”
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Uzuchi ati Ogbonna ni wón gba lati ma ba awọn obinrin naa ti wọn yoo fi lọyun.
“Gbogbo awọn obinrin ti a dola lo jẹ mẹwaa, ti pupọ wọn si ti loyun.”
Iringe Koko ni iwadi ti fihan pe ni obinrin kan larin wọn ba ti bimọ, wọn yoo gba ọmọ lọwọ rẹ, ti wọn yoo si fun owo toto ẹgbẹrun lọna ọọdẹgbẹta naira .
“Gbogbo awọn obinrin ti a dola nibẹ lo ti jẹwọ fun pe wọn tan awọn wa sile naa nitori awọn la awọn isoro kan kọja.
“A gba ọkọ ayọkẹlẹ Pilot Jep lọwọ olori wọn.”















