Ìgbeyàwó 2000 forí ṣánpọ́n torí àṣìlò fóònù lọ́dún 2021

Ajọ to ga julọ fọrọ ẹsin Islam ni Orilẹ-ede Niger ti kéde pé ẹrọ alagbeka foonu ti da ọpọlọpọ ile ru, ti idile to le ni ẹgbẹrun kan abọ si ti tuka.
Ajọ na ni akọsilẹ ti fi han pe idile bii ẹgbẹrun mẹta ni ipinya ti de ba lọdun 2021 to kọja nitori bawọn iyawo se n wo foonu ọkọ wọn.
Ajọ naa, ninu atẹjade to fi lede ni oun ti n gba ọpọ idile nimọran lori isẹlẹ yii, ti adinku si ti ba awọn idile to n koju iṣoro ipinya.
Ọkan l'ara awọn adari ajọ to ga julọ fọrọ ẹsin Islam naa, Ustaz Mouha sọ fun akọroyin BBC wi pe ajọ IEN gbiyanju lati pẹtu si aawọ laarin tọkọtaya.
O ni eleyii si ti mu adinku ba iye awọn to fẹ pinya ninu igbeyawo wọn.
Mouha ni ẹrọ foonu jẹ ọkan ninu eroja to mu igbeyawo tuka kiakia lode oni, bẹẹ si ni laye atijọ ko si ẹrọ alagbeka foonu lọwọ awọn eeyan.
Sugbọn lode oni, o ni igbakigba ti ọkọ ba wo foonu iyawo rẹ, o seeṣe ki ariyanjiyan waye eyiti o dakun ipinya ninu igbeyawo.
Uztaz Mouha ni ẹtan ati irọ pipa lọpọlọpọ igba latọwọ awọn ọkunrin naa maa n se akoba fun idile.
Ahmad Maryama tii se oludari ajọ to risi idaabo bo ẹtọ awọn obinrin ati ọmọde ni ọpọlọpọ igba ni ajọ oun maa n se ijiroro itagbangba pelu awọn olori ilu ati awọn eeyan agbegbe wọn lori ewu tó wà ninu ipinya laarin lọkọ laya.














