INEC fi kún ọjọ́ gbígba káàdì ìdìbò

Oríṣun àwòrán, others
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria INEC ti kede afikun ọjo si ọjọ ti awọn araalu ni anfani lati gba kaadi idibo fun eto idibo ọdun 2023.
Saaju ni ajọ ọhun ti kede pe awọn yoo fi opin si igba kaadi idibo lọjọ kejilelogun ọsu kini ódun yii sugbọn wọn ti sọ di ọjọ kọkandilọgbọn oṣu kini ọdun ta wa yii.
Ikede yii waye lẹyin ipade ti ajọ naa ṣe Lọjọbọ ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kọmisọna ajọ INEC, Festus Okoye fi ransẹ si awọn akọroyin,
O ni
“Ajọ INEC ti pinnu lati jẹ ki awọn oludibo to fi orukọ silẹ gba kaadi idibo wọn saaju eto idbo. Fun isi eyi, ati fi ọjọ mẹjọ kun ọjọ to yẹ ki gbigba kaadi idibo wa sopin.
“O yẹ ki gbigba kaadi idibo wa sopin lọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun, sugbọn a ti fi ọsẹ kan kun, ti yoo si wa sopin lọjọ kọkandinlọgbọn .
“Asiko ti awọn eeyan le gba kaadi idibo wọn ago mẹsan an arọ di ago mẹta ọsan. A sisẹ ni ipari ọsẹ ati ọjọ isinmi pẹlu.”
Aipẹ yii ni ajọ INEC kede pe mimi kan ko ni mi awọn lati sun eto idibo siwaju.
Alaga Ajọ naa, Mahmood Yakubu ni gbogbo eto lo ti wa nilẹ eyi ti yoo mu eto idibo lọ lai si rogbodiyan rara.
Yakubu ni ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọ fi ọkan wọn balẹ lori ọrọ eto idibo.















