Ìgbé ayé rúdurùdu àti ìnira là ń gbé torí ìdúnkokò àwọn jàǹdùkú agbébọn

Aworan afihan agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olugbe ilu Kidandan nijọba ibilẹ Giwa ni Kaduna ti ke gbajare lori bi wọn ṣe n koju idunkoko lọwọ awọn janduku agebọn.

Wọn lawọn ko ribi lọ soko lọ ṣiṣẹ pẹlu bi awọn alaburu yi ṣe n kọlu wọn ti wọn si n gba owo iṣakọlẹ lọwọ ẹnikẹni to ba fẹ lọ soko.

Awọn eeyan yi sọ pe aimọye oṣu lawọn janduku yi ti n ṣe ikọlu sawọn eyi to mu ẹmi awọn eeyan awọn kan lọ.

Ninu awọn araalu yi to ba BBC sọrọ ṣalaye pe ni bayii awọn janduku yi n pa aja awọn ti awọn agbofinro ko si ribi koju wọn.

Nigba mii ti wọn ba wa, wọn yoo yinbọn lalẹ ki wọn to lọ.Nigba mii si re wọn yoo gbe alupupu wọn sẹgbẹ igbo ti wọn yoo si wọ inu ilu wa lati wa ji awọn eeyan gbe salọ''

O ni lọna ati mu ayedẹrun lawọn tun fi da owo jọ lati gba arakunrin kan to jẹ agunbanirọ to ni sọọbu kan to ti n ta oogun.

Araaalu to ba wa sọrọ yi ni igbe aye rudurudu lawọn n gbe tori awọn janduku yi.

''Awọn eeyan ko le fẹdọ lori oronro nibi tohun ti pe awọn agbofinro wa nii.Lọsan gaan lawọn agbebọn yi n rin kaakiri tori pe wọn o lọkan lati doju kọ wọn''

O tẹsiwaju pe ''awa taa loko taa n da ko ribi lọ si oko ayafi ti eeyan ba kan si ọkan ninu awọn aṣoju awọn janduku yi. Bi o ba san owo tan ni wọn o ṣẹṣẹ yan eeyan kan lati tẹle ọ lọ si oko rẹ lati lọ mu nkan oko wa sile''

Ọkan lara olugbe ilu naa sọ pe igbe aye inira lawọn n gbe.

O ni ''bo ba di lalẹ wọn a maa wa ji eeyan gbe to si mu ki ọpọ eeyan sa nilu.Ti ẹ ba de abule gaan idaju ilu lo ti sa lọ tan''

Awọn araalu sọ pe ireti to ku tawọn ni bayii ni pe ki awọn ijọba fi agbofinro ti yoo lee daabo bo awọn ranṣẹ si ijọba ibilẹ Giwa.

Ki ni awọn ọlọpaa ri si ọrọ yii?

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kaduna sọ pe ohun to n ṣokunfa ipenija aabo to mẹhẹ ni Giwa ko sẹyin aima tete kan si awọn lati ọdọ awọn araalu.

ASP Mansir Hasan ni alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kaduna.

O sọ pe : ''Wọn kii tete fi ọrọ to wa leti bo ba ṣe n ṣẹlẹ afigba ti wọn ba l tan.Awọn eeyan a maa ri wọn ṣugbọn wọn kii ta wa lolobo bi nkan ba ṣe n waye''

ASP Hasan sọ pe laipẹ lawọn joko ijiroro pẹlu awọn araalu to fi mọ alaga ijọba ibilẹ Giwa ati awọn kansilọ nibi tawọn ti sọrọ nipa ipese aabo to peye fawọn eeyan ilu.