Ọgbọ̀n èèyàn kú, bí ìjà ńlá ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin agbébọn àti Fijilańté

Oríṣun àwòrán, AFP
Àwọn agbéṣùnmọ̀mí tún ti ṣekúpa ọgbọ̀n èèyàn míì ní ìpínlẹ̀ Kaduna àti Katsina láàrin òpin ọ̀sẹ̀ yìí.
Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Katsina, tíí ṣe ìpínlẹ̀ ààrẹ Muhammadu Buhari, sọ pé kò dín ní ènìyàn ogún tí àwọn sin, lẹ́yìn tí ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn agbébọn àti àwọn fijilanté.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ti ṣòfin kónílé ó gbélé ní àwọn agbègbè kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Zango Kataf lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú Ungwan Wakili.
Agbebọn dú obinrin ati ọmọde mẹwaa lrun lẹkun guusu Kaduna
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ìpínlẹ̀ náà ní àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó lé ní mẹ́wàá, tó fi mọ́ obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ni àwọn oníṣẹ́ ibi náà dú lọ́rùn ní ẹkun gúúsù Kaduna, nígbà tí wọ́n ya bò wọ́n.
Àwọn olùgbé àdúgbò náà ní ọ̀pọ̀ òkú ni àwọn ṣe àwárí nígbà tí àwọn ń wá àwọn ará ìlé wọn tó sọnù.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Zango Kataf, Francis Sani Zimbo sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé nítorí àti fòpin sí ìkọlù bẹ́ẹ̀ ni àwọn ṣe gbé òfin kónílé gbélé kalẹ̀.
Ìkọlù àwón agbébọn ni ìṣòro kan gbòógì tí àwọn ènìyàn ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá ń kojú pẹ̀lú bí alékún ṣe ti bá àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ní agbègbè náà.
Boko Haram pa apẹja ọgbọ̀n, UN figbe ta

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@PEACOCK
Ajọ iṣọkan agbaye, UN, ti bu ẹnu atẹ lu bi ikọ alakatakiti ẹsin, Boko Haram ṣe pa o kere tan, ọgbọn eeyan ni ipinlẹ Borno.
Apẹja lawọn eeyan naa ti wọn pade iku ojiji ni ijọba ibilẹ Gamborun Ngala, nibi ti pupọ ninu awọn olugbe rẹ jẹ apẹja ati agbẹ.
Ẹba ilu Mukdolo, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ Boko haram pọ si ni ikọlu naa ti waye.
Iroyin ni asiko ti awọn oloogbe naa n lọ wa ounjẹ oojọ wọn ni Boko Haram, ti wọn jẹ ti iha ISWAP ti kọlu wọn.
Eeyan mẹsan an lo moribọ pẹlu ọgbẹ ọta ibọn
Nnkan bii ọgbọn eeyan lawọn alakatakiti ẹsin ọhun da ibọn bo, awọn kan lara wọn ṣeṣe yanayana, nigba ti ko si ẹni to mọ ibi ti awọn mii bayii.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ori alupupu lawọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram naa ti dana ibọn ya awọn eeyan ọhun.
A gbọ pe eeyan mẹsan an lo moribọ, amọ pẹlu ọgbẹ ọta ibọn lara wọn.
Iroyin ni awọn agbebọn naa ti ranṣe si awọn eeyan ọhun ṣaaju pe ki wọn yẹba fun agbegbe ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ẹnikan to yọju sibi eto sinku awọn oloogbe naa ṣalaye fun BBC pe inu iporuru ọkan lawọn olugbe ilu naa n gbe bayii.
Ajọ iṣọkan agbaye, UN, ti wa bu ẹnu atẹ lu ikọlu awọn alaiṣẹ naa.
UN ni o kere tan, 350,000 eeyan lo ti padanu wọn sọwọ Boko Haram, nigba ti aimoye miliọnu eeyan di alairilegbe.
Ijọba Borno yọju si mọlẹbi awọn oloogbe
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ti yọju si mọlẹbi awọn eeyan naa lati ba wọn kẹdun.
Aafin Shehu Dikwa, iyẹn Alhaji Ibrahim Ibn Ibrahim El-Kanemi, lo ti ba wọn eeyann naa pade.
Zulum ba wọn kẹdun iku awọ mọlẹbi wọn, o si gbadura fun awọn oloogbe naa pẹlu.
O ni “Lorukọ ijọba atawọn eeyan ipinlẹ Bornu, mo ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi awọn to ku lasiko ti wọn n wa ounjẹ ojọ wọn.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















