''Mo jẹ gbèsè tí apá mi kò ká torí mò ń wá iṣẹ́ ìyanu lọ́dọ̀ pásítọ̀''

Aworan

Arabinrin Evarline Okello ti sọ iriri rẹ pẹlu ẹkun kikoro lẹyin to ya owo lati fi san owo agba iyanu fun pasitọ.

Arabinrin Okello n gbe ni agbegbe Kibera ni Nairobi to jẹ olu ilu orilẹede Kenya.

Okello pẹlu omije ni oju ni oun ko lee san owo ile tabi fun awọn ọmọ oun mẹrin ni ounjẹ oojọ wọn mọ nitori gbese.

Lasiko ti arabinrin naa n sọ iriri rẹ fun BBC, o ni iṣoro oun bẹrẹ lasiko ti oun gbọ nipa pasitọ kan to gbona jain, ti yoo fi opin si iṣoro oun ti pasitọ naa ba gbadura fun oun.

‘’Pasitọ naa beere fun $115 (£96; 15,000 Kenyan shillings), ki ohun fi le gbadura fun un’’

‘’Owo yii ni wọn n pe ni ọrẹ atinuwa fun itẹsiwaju ti wọn n pe ni ‘’seed offering’’ ni Ede Gẹẹsi.’’

Arabinrin Okello naa ya owo naa lọwọ ọrẹ rẹ lati ta pasitọ ni ọrẹ nitori adura ti pasitọ ba gba yoo ṣi ọna iyanu silẹ fun arabinrin naa.

Wọn ti lẹ sọ fun obinrin naa pe laarin o

Amọ o ṣeni ni aanu pe agba iyanu naa ko waye, ohun gbogbo tilẹ bajẹ si ni fun obinrin naa.

‘’Ohun gbogbo tilẹ wa buru si o si ti mu aye su mi’’

Iṣẹ iyanu agba iyanu...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn eniyan to n koju ọwọngogo ounjẹ ati ile gbigbe ni orilẹede Kenya ti mu ki iya ati iṣẹ peleke si lorilẹede naa lati bi oṣu kẹsan an ọdun to kọja.

Onimọ nipa ihuwasi eniyan, Dokia Gladys Nyachieo lati fasiti orilẹede Kenya ni awọn eniyan n wa ọna abayọ si iṣoro wọn ni wọn ṣe wa ki iṣẹlẹ iyanu ṣẹlẹ.

Amọ wiwa iṣẹ iyanu yii bẹrẹ lasiko iwaasu ti awọn pasito n fun awọn eniyan pe igbagbọ ninu Ọlọrun kii jẹ ki eniyan tosi, pẹlu igbagbọ pe ti o ba fun ni, waa ri gba ni ilọpọ ọgọrun ati ju bẹẹ lọ.

Lara awọn pasito to gbe iwaasu ti wọn pe ni Prospẹrity gospel wa si ilẹ Afrika ni Reinhard Bonke ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti awọn orilẹede Naijiria ati Kenya si gba iwaasu naa bi ẹni gba igba ọtin.

Idi ti ẹyawo fi pọ yanturu...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ nipa ihuwasi eniyan yii tun tẹsiwaju ninu idi ti awọn eniyan fi n jẹ gbese lasiko yii paapaa ni orilẹede Kenya ati ilẹ Afrika ni apapọ.

Dokita Nyachieo ni awọn eniyan ri owo ya lọgọọrọ lori ẹrọ ayelujara lai si idiwọ fun wọn lo tun faa.

Iru iriri yii lo ṣẹlẹ si arakunrin Dennis Opili to ti n wa iṣẹ fun bi ọdun mẹta lai ri, to si ba ọrẹ rẹ sọrọ fun ọna abayọ.

‘’Ọrẹ mi sọ fun mi pe ile ijọsin kan wa to jẹ pe ti wọn ba ti ta pasitọ ni orẹ, iṣẹ yoo wa fun mi’’

Ọrẹ rẹ sọ fun pe $180 owo ilẹ okeere ni yoo ma da ni ọjọọjọ Isinmi ni ṣọọṣi fun oṣu mẹta.

Eyi lo mu ki arakunrin naa lo yawo lori ẹrọ ayelujara lẹyin ti owo rẹ tan.

‘’Mo gbagbọ ninu ohun ti pasitọ sọ fun mi ki n le ri iṣẹ nitorinaa ko ba mi lẹru lati ya owo.’’

‘’Nitori ero mi nipe wẹrẹ ti mo ba bẹrẹ iṣẹ ni maa san awọn owo ti mo ya pada.’’

‘’Mo ṣi gbagbọ ninu Ọlọrun amọ awọn pasitọ ni wọn n fi ipa gba owo ni ọwọ awọn eniyan’’

Aworan

Amọ nigba ti arakunrin naa ko ko firi iṣẹ kankan lo bẹrẹ si ni woye pe o ṣeese ki wọn ti lu oun ni jibiti.

Lẹyin naa ni awọn ileeṣẹ to ya owo lọwọ rẹ bẹrẹ si ni le kiri lati gba owo wọn pada.

Aya rẹ bẹrẹ si ni ja nitori bi awọn to jẹ ni gbese ṣe bẹrẹ si ni pe lori ẹrọ rẹ eleyii to mu ki aya rẹ ja.

Amọ a dupẹ pe o ri iṣẹ kekere tan to si fi san lara owo to jẹ awọn ileeṣẹ ẹyawo ati awọn ọrẹ pẹlu

Ninu ọrọ rẹ, arakunrin naa ni oun ko sọ igbagbọ oun nu nitori iṣẹlẹ naa, amọ awọn pasitọ ti wọn n fi ipa gba owo ni ọwọ awọn eniyan n ba igbagbọ jẹ.

Awọn miran to tun sọ iriri wọn salaye bi awọn pasitọ kan ṣe kan an nipa fun wọn lati san idamẹwa ati ọrẹ atinuwa to fi mọ ọrẹ akanṣẹ fun pasitọ wọn.