March 18 ló yẹ kí ọmọ mi ṣe ìgbéyàwó, INEC tó sún ìdìbò sí ọjọ naa bá ǹkan jẹ́ fún wa – Bàbá ìyàwó

Ẹru Iyawo

Baba arabinrin to fẹ ṣe igbeyawo ni Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹta, ọdun 2023 ti fi aidunnu rẹ han si bi Ajọ eleto idibo INEC ṣe sun ọjọ idibo si ọjọ igbeyawo ọmọ rẹ.

Ajọ INEC kede ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹta,ọdun 2023 gẹgẹ bi ọjọ ti idibo sipo gomina ati idibo si ile igbimọ aṣofin labẹle yoo waye ni awọn ipinlẹ.

Ohun ti o ma n ṣẹlẹ ni ọjọ idibo ni pe awọn eniyan ko ni lee ri ni oju popo to fi mọ ohun irinṣẹ ni ọjọ naa.

Nitori naa kii ṣi ayẹyẹ ni ọjọ idibo kaakiri orilẹede Naijiria, ti awọn eniyan si ma n pe ni opin ọṣẹ ti kii ṣi ayẹyẹ igbeyawo ni Naijiria.

‘’Inu mi bajẹ gidi si igbeṣẹ INEC yii amọ a gbọdọ tẹle ofin ijọba’’

Amọ ọpọlọpọ awọn eniyan ni iroyin ba ni ojiji ti wọn si ti sun ọjọ ayẹyẹ siwaju nitori igbeṣẹ ajọ INEC.

Ọkan lara wọn ni Alhaji Shuaibu Idi Amin to n gbe ni ilu Kano, to si ti pese ohun gbogbo fun igbeyawo ọmọ rẹ obinrin ki ajọ INEC to kede ọjọ idibo tuntun naa.

Alhaji Shuaibu to ba BBC Pidgin sọrọ ni gbogbo ẹru iyawo to n ko lọ si ile ọkọ to fi mọ awọn ounjẹ ti wọn yoo ṣe ni ọjọ naa lo ti wa nilẹ.

‘’Gbogbo eto ti to fun igbeyawo ọmọ mi, atilẹ ti pin kaadi ipe wa si ibi igbeyawo ọmọ mi naa.’’

‘’Inu mi bajẹ gidi si igbeṣẹ INEC yii amọ a gbọdọ tẹle ofin ijọba’’

Alhaji fikun un pe awọn mọlẹbi oun lati ilu Bauchi ti gbaradi lati wa si ibi igbeyawo naa ni ilu Kano.

‘’Mo ni lati pe wọn pe ki wọn ma wa mọ nitori a nilo ọjọ tuntun miran lati ṣe igbeyawo ọmọ mi’’.

Bakan naa lo ni ọjọ igbeyawo tuntun naa ni awọn mọlẹbi mejeeji yoo jiroro le lori ki o lee rọrun fun wọn.

‘’ A maa nilo lati joko pẹlu mọlẹbi ọkọ afẹṣọna ọmọ mi lati jiroro lori ọjọ tuntun ti igbeyawo naa yoo waye.’’

Kini idi ti INEC fi sun eto idibo si iwaju?

Lẹyin ti ileẹjọ paṣẹ ki INEC ṣe atuntọ ẹrọ eto idibo BVAS ki idibo sipo gomina ati ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni wọn gbe igbeṣẹ naa.

Ajọ INEC kede pe awọn ti fi ọṣẹ kan kun ọjọ ti idibo to yẹ ko waye ni Naijiria ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹta.

Ileẹjọ fun INEC laṣẹ lati ṣe atunto ẹrọ BVAS naa fun eto idibo to n bọ.

Amọ ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ti gbe INEC lọ si ileẹjọ wi pe atunto BVAS ko ni fun wọn ni ẹri ti wọn nilo lati ṣafihan ẹsun magomago ti wọn fi kan INEC lasiko eto idibo sipo aarẹ to gbe Bola Ahmed Tinubu wọle gẹgẹ bi aarẹ ni Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, INEC ni igbẹjọ to waye ni ileẹjọ naa lo fa ifaṣẹyin fun ajọ naa lati tete ṣe awọn eto to yẹ fun idibo naa, ohun lo si mu ki wọn sun siwaju.

Ẹrọ BVAS naa ni o ma n ṣe ayẹwo oju ati ika awọn oludibo lati fihan an pe oludibo naa pegede lati dibo yan ẹni ti ọkan wọn fẹ ninu eto idibo naa.