Dodo Farms: Ẹ wo bí àwọn ọmọ Yoruba ṣe làlùyọ nídìí iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Amerika

Àkọlé fídíò, Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà

Ọpọ ọmọ orilẹ-ede Naijiria lo ti fi ilẹ yii silẹ fo fẹrẹ roke okun ni ilepa ilẹ to lọọra.

Dokita, ójọgbọn, akọroyin, ayaworan ati ọpọlọpọ akọṣẹmọṣẹ miran bẹẹ, koda ẹni ti ko niṣẹ lọwọ paapaa.

ṣugbọn itan ilẹ ọlọraa ti gbogbo wọn yii n le yatọ nitori ọpọ lo n pada de ilẹ Amẹrika tabi awọn orilẹ-ede miran bẹẹ tan ti wọn wa di isansa, ati alarinkiri nitori iṣẹ ti wọn foju si ko waye.

Dodo farms

Oríṣun àwòrán, Dodo farms

Fun Ọjọgbọn Ọlaniyi Balogun, irinajo yii yatọ.

Ki o to kuro lorilẹ-ede Naijiria lọ ba iyawo rẹ ni Amẹrika lo ti sọ fun un pe, ko si iṣẹ miran ti oun nifẹ si lati ṣe lorilẹ-ede Amẹrika to fẹ ki oun wa ju iṣẹ agbẹ lọ.

Tọkọ-taya Olaniyi

Oríṣun àwòrán, Dodo farms

Lọna ati lee mu ala rẹ dohun, Ọjọgbọn Balogun lọ kọ bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ agbẹ Amẹrika fun oṣu mẹfa ki o to wa bẹrẹ ti ara rẹ gan an.

Ẹ wo ọrọ ree lẹnu ọlọrọ...

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: