Mi ò bèèrè ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ mọ́lẹ́bi mi kankan lórí ẹ̀yà ara tí ọmọ mi nílò, ìdí ni pé ... - Ekweremadu

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Sẹnetọ Ike Ekweremadu ti wọn fẹsun kan pe o fẹ fowo ra kidirin ọkunrin kan to mu wa sil ilu Ọba lọna ti sọ eredi fun igbesẹ rẹ.

Lara awọn ibeere to n jẹ jade latẹyin wa ni pe kilode ti o n lọ ba ara ita fun kidinrin lai kọkọ beere lọwọ awọn mọlebi na rẹ boya wọn le fun ni kidirin.

Nigbati wọn gbọ igbejọ rẹ ni Old Bailey, wọn ni o kọ lati tọ awọn mọlebi rẹ lọ fun iranlọwọ ti o si fẹ fowo ra kidirin lọna aitọ.

Ekweremadu ẹni aadọta ọdun ni oun ko jẹbi ẹsun naa.

Sẹnetọ Ekweremadu, iyawo rẹ Beatrice, ọmọ wọn Sonia ati Dokita Obinna Obeta ni wọn jọ foju ba ile ẹjọ ti wọn si ni awọn ko jẹbi ẹsun ifipa mu ẹni ọdun mọkanlelogun wa si ilu Ọba lati ipinlẹ Eko lati yọnda kidirin rẹ.

Ṣaaju ni wọn ti gbo igbejọ lori ẹsun pe Ekweremadu fẹ san ẹgbẹrun meje owo ilẹ okeere fun ẹni ọdun mọkanlelogun naa ti ile ẹjọ forukọ bo lasiri ti wọn si ṣeleri lati baa wa iṣẹ niluu Ọba.

Lẹyin ti ayẹwo ile iwosan London's Royal Free Hospital fihan pe kidirin rẹ ko papọ mo ti ọmọ Sẹnetọ Ekweremadu, wọn gbiyanju lati wa kidirin mii lọ si orilẹ-ede Turkey.

Nigba ti wọn fi ẹjọ waa lẹnu wo lori idi ti ko fi beere kidirin lọwọ awọn mọlẹbi rẹ ó ni oun ko roo wi pe o nilo nitori oun kii ṣe oniṣe iṣegun, igbagbọ oun si ni wi pe ko si kidirin ti ko lee ṣiṣẹ fun ọmọ oun.

Àwíjàre Ike Ekweremadu.

Sẹnetọ Ekweremadu ni irọ to jina si ootọ ni wi pe oun sanwo fun ẹnikan lati wa ẹniti awọn o yoo kidirin rẹ tí won o si sanwo fun.

Ọgbẹni Davies fẹsun kan Ekweremadu wi pe o fẹ lọ si ile iwosan miiran ni orilẹ-ede Turkey lati yọ kidirin ẹniti wọn fẹ lo ti oun naa si sọ wi pe oun ko tan mọ idile Ekweremadu.

Sẹnetọ naa tun ni bẹẹ kọ ni ọrọ ri.

Nigba ti wọn bere idi ti Ekweremadu ṣe fẹ lo ile iwosan Orilẹ-ede Turkey, Ekweremadu ni iwosan orilẹ-ede naa dinwo ju ti ilu Ọba ni.

Ọgbẹni Davies ni pẹlu owo ati dukia Sẹnetọ Ekweremadu ni o fihan pe o ni ọrọ pupọ eyiti ti Sẹnetọ Ekweremadu ni kìí ṣe otitọ.