Lalude fèsì lórí èèyàn tí Fadeyi Oloro jẹ́, ìdí táwọn òṣèré míì kìí ran àwọn àgbà lọ́wọ́ lọ́jọ́ ogbó

Lalude ati oloogbe Fadeyi Oloro

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Ki lo de to da bii pe awọn ọdọ to ni owo lọwọ ko ran awọn agba lọwọ titi ti ọlọjọ a fi de ba ẹni to ba ṣe aisan?

Lalude: Haa, eyi tẹẹ sọ yẹn ko ṣee tọpinpin o ...

Ọkan lara awọn agba oṣere fiimu Yoruba ti oun naa maa n ko iru ipa ti oloogbe Fadeyi Oloro maa n ko ninu ere Fatai Odua Adekunle Adetayo ti ọpọ mọ si Lalude ti ba BBC Yoruba sọrọ lori iru eeyan ti Baba Fadeyi Oloro jẹ ati iha ti awọn oṣere kọ si oloogbe naa.

Bo tilẹ jẹ pe ọtọọtọ ni ọgbọn amuludun ti amwọejeeji n maa lo ninu ipa ti wọn ba n ko ninu ere, kilaasi babalawo kan naa ni awọn onoworan ka wọn si.

“Ẹni gẹgẹ bi eeyan pataki lawujọ lao ka Fadeyi Oloro si tori pe ẹni to ba ṣe ere tiata de aye to ṣee de yẹn to fi lọ, eeyan pataki ni”.

Aworan Lalude ati Fadeyi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

O ni bo tilẹ jẹ pe o ṣe aarẹ ko to ku, ki eeyan ni agbara ti Ọlọrun ba fun eeyan ni anfani ati ṣe ere de ibi ti Fadeyi ṣee de yẹn ka fi ọpẹ fun Ọlọrun toripe oun lo mọ iku to fi n paayan.

“Ojo jẹ eeyan to ni iwa tutu, emi o ri ibi to ti ba eeyan ja ri, lawọn asiko taa ba pade, iṣe wa ṣi n dọgba pẹlu ara wọn gẹgẹ bii iṣẹ taa jọ n ṣe papọ.”

"Kò sí ẹni tó kọ́ ara wọn níṣẹ́ láàrín èmi àti Fadeyi Oloro, bí a ṣe jọ pàdé rèé"

Awọn agba oṣere

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Mi o kọ iṣẹ lọwọ Fadeyi, ko si kọ iṣẹ lọwọ mi”.

Fatai Odua ti ẹ mọ si Lalude ṣalaye pe Eko ni ohun wa ti Fadeyi si wa ni ilu Ado amọ , ọhun, koda pẹlu gbogbo awọn akẹgbẹ wa, a yọ mọ ara wa tori o ladun o larinrin.

“Torinaa, mi o kọ iṣẹ lọwọ rẹ ko si kọ iṣẹ lọwọ mi”.

Lalude dahun si ibeere lori pe ṣe irọ ni oun ati Fadeyi, o ni: “mi o mọ igba to bẹrẹ ere o amọ emi mọ pe mo bẹrẹ lọdun 1970”.

O ni Fadeyi o fi irọ ba oun lo toripe oun gan ko fi aaye irọ silẹ eyi to si jẹ ipa sisọ ootọ to fi silẹ lọ.

Ki lo de ti ẹyin oṣere Tiata kii ran ara yin lọwọ mọ paapaa ti agba tabi aisan ba de?

Lalude ati Fadeyi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC Yoruba: Gbogbo awọn ololufẹ ẹyin oṣere Tiata lo n sọ pe ẹ o ki n ran ara yin

lọwọ mọ, ti agba ba ti de, gbogbo awọn to kọ ẹkọ lara wọn o yọwọ,

ki lo de to da bii pe awọn ọdọ to ni owo lọwọ ko ran awọn agba

lọwọ titi ti ọlọjọ a fi de ba ẹni to ba ṣe aisan?

Lalude: Haa, eyi tẹẹ sọ yẹn ko ṣee tọpinpin o tori eniyan gẹgẹ bi eniyan,

iwa otitọ taa n hu loju aye ko to irọ taa n pa labẹ aṣọ.

Ẹẹ gbọ mi ye?

BBC Yoruba: Agbọye baba

Lalude: Iwa otitọ taa n hu loju aye ko to iwa irọ taa n hu ni kọrọ ti ko daa,

ṣe o yee yin?

Ati otitọ ati iwa ti ko dara yẹn, awọn gangan ni ipadepọ ọjọ iku.

Tori ọjọ kan leeyan maa jẹ ohun ti ko gbọdọ jẹ, ọjọ kan leeyan maa

rin irin to maa rin kẹyin.

To ba ti to asiko yẹn, ko ṣee wadii mọ, o ti di iṣẹ Ọlọrun, oun lo le

gbẹsan.

BBC Yoruba: Laarin ẹyin agbaagba oṣere, ṣe ibaṣepọ to dan mọran wa laarin

yin, ṣe ẹ pa baba Fadeyi oloro ti?

Lalude: Ẹnikan o pa ẹnikankan ti o, ab’ọrọ mi o yee yin? Ṣe ẹ rii, taa ba jọ n

ṣe nnkan, iha taa ba jọ kọ

si ara waloju aye ohun naa la maa ri teeyan o ba si mọ o.

Lalude kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pẹlu aṣiri ọrọ to tu sita pe:

“A ṣaa ri awọn to jẹ pe ninu awọn agbalagba wa ti wọn n fun ni owo oṣu, tawọn ẹgbẹ wa n fun wọn ni owo oṣu, ẹnh”.

O fi kun un pe nitoun, ọmọ kekere kankan ninu agbo oṣere Tiata o gbọdọ yaju si oun tori “mo ni mọto, mo kọle, mo bimọ, iyawo o si fi mi silẹ salọ, torinaa, ọmọ kekere kankan o gbọdọ yaju si mi nigba ti mi o ba ti lọ ba a pe mo nilo nkan, ki ni mo n wa kiri de ọdọ wọn.

Baba Lalude ni awọn ọmọ to ba wa rii pe awọn kọ ẹkọ lara awọn baba agba yii lo yẹ ki wọn ronu ara wọn wo daadaalati le mọ nnkan ti wọn ma ṣe fawọn ti wọn ri ẹkọ kọ lara rẹ yẹn ki ọjọ alẹ tiwọn naa maa baa ri bi wọn ṣe n ro o.