Adeleke kàn ń gba oríyín fún àṣeyọrí Oyetola ni - APC Osun

Aworan Gomina Ademola Adeleke ati Gomina Tẹle Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress APC nipinlẹ Osun, ti fi ẹsun kan iṣejọba Ademola Adeleke pe ko dẹkun lati gba oriyin awọn aṣeyọri Gomina Gboyega Oyetola.

APC Osun ni ko bojumu bi ijọba Ademola Adeleke se dawọ isẹ duro lori Fasiti Ilesha, eyi ti wọn ni Gomina tẹlẹ, Gboyega Oyetola ti pari gbogbo isẹ lori Fasiti naa.

Alaga fidihẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Tajudeen Lawal lo sọ eleyi nibi ipade kan ti wọn ṣe pẹlu awọn akọroyin niluu Osogbo l'Ọjọru.

Lawal ni owo to to aadọruun biliọnu naira ni o wa ni apo ijọba nigba ti Adeleke di gomina l'osu mẹta sẹyin.

Kola Olabisi, agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC, to lọ soju alaga ni ayẹyẹ ọgọrun-un ọjọ gẹgẹ bii gomina ti Adeleke ṣe ni ko bojumu rara, ati pe aadọrun bilọnu naira naa ni ijọba Adeleke ko ri nawọ si pe nnkan bayi lo fi se.

"Adeleke gba isẹ lọwọ awọn eleto ilera to to ẹẹdẹgbata niye nigbati ti eto ilera ṣimẹhẹ nipinlẹ naa.

"Adeleke n lo awọn janduku lati dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lasiko ti eto idibo Aarẹ ati ile igbimọ waye.

Ẹwẹ, ko tii si esi ti ijọba Ademola Adeleke fọ si gbogbo ọrọ ti ẹgbẹ oṣelu APc Osun lọ mọ ọ lẹsẹ yii.