Obi pàdánù nílé ẹjọ́, Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún INEC láṣẹ láti ṣàtúntò BVAS fún ìdìbò gómìnà

Oríṣun àwòrán, inec
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to n gbọ awọn awuyewuye eto idibo sipo aarẹ ni Naijiria to waye loṣu to kọja ti fun ajọ INEC lanfani lati ṣe atunto ohun elo ayẹwo oludibo lọna igblode, BVAS to lo fun eto idibo sipo aarẹ.
Eyi tako ẹbẹ ti oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ gbe ka iwaju ile ẹjọ naa pe ko ka ajọ INEC lọwọ ko pe ko gbọdọ fọwọ kan ẹrọ igbalode BVAS naa, ati pe o gbọdọ gba oun laaye lati yẹ ẹ wo.
Awọn igbimọ adajọ mẹta to n gbọ ẹjọ naa ṣalaye pe dida INEC lọwọ kọ yoo pagidina eto idibo sipo gomina atawọn igbimọ̀ aṣofin ipinlẹ ti yoo waye lọjọ Satide, ọjọ kọkanla oṣu kẹta.
Agbẹjọro fun INEC ṣalaye pe ko yẹ ki Peter Obi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ bẹru ohunkohun nitori pe gbogbo ohun to wa lori awọn ẹrọ BVAS naa ni wọn yoo fi pamọ sinu agbada ayelujara 'server' wọn fun ẹnikẹni lati wo nigbakugba.
Awọn agbẹjọro to ṣoju fun Peter Obi ati Atiku Abubakar, ni awọn ohun ti awọn nilo fun ẹjọ awọn lo ṣeeṣe ki wọn parẹ bi ajọ INEC ba ṣe atunto BVAS rẹ hun
Ile ẹjọ kotẹmilọrun fun Obi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ laṣẹ lati yẹ awọn ohun elo gbogbo ti INEC lo fun eto idibo aarẹ to kọja lorilẹede Naijiria wo fun ẹjọ to pe tako idibo naa.
Amọṣa, ajọ eleto idibo INEC dide tako Obi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ lẹyin to ni oun fẹ ṣe atunto BVAS fun ati lo lasiko idibo gomina ti yoo waye lọjọ Satide.








