‘Lọ́tẹ̀ yìí, BVAS yóò ṣiṣẹ́ dáadáa’ – Ohun márùn-ún tí INEC yóò ṣe ní ìdìbò gómìna ní March 11 rèé

Mahmood Yakubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria ti ni pe ẹrọ BVAS ti wọn n lo lasiko idibo yoo ṣiṣẹ daadaa lọtẹ yii ti Naijiria fẹ ṣe eto idibo awọn ipinlẹ ati ti ile igbimọ aṣoju-ṣofin.

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu fi aridaju yii han lẹyin to ṣe ipade pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ naa to fi mọ awọn alaga ajọ yii kaakiri awọn ipinlẹ orilẹede Naijiria eyi to waye nilu Abuja lọjọ Aiku ọjọ Kẹrin Oṣu Kẹta.

Eyi waye lẹyin ti ajọ INEC kede Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi oludije to jawe olubori pẹlu ida mẹtadinlogoji ninu gbogbo ibo fun ipo aarẹ.

“Ajọ yii ti fi kun akitiyan ṣiṣe ayẹwo awọn nnkan imọ ẹrọ lati rii daju wipe iṣoro ti a koju, paapaa nipa kiko awọn esi idibo sori ẹrọ kọmputa, eyi si ti ni iyanju.”

Ọjọgbọn Yakubu ni a ni igboya pe nibayii, ẹrọ kọmputa naa yoo ṣiṣẹ daradara.”

Igba yii ni yoo jẹ ẹkẹta laarin Oṣu meji ti alaga ajọ eleto idibo yoo ṣepade pẹlu awọn eeyan rẹ lori ọrọ idibo.

Lori ọrọ bi INEC ko ṣe ko gbogbo esi idibo sori ẹrọ ayarabiaṣa ti awọn oludije ẹgbẹ alatako meji si ni awọn yoo wọ INEC lọ sile ẹjọ, ajọ naa ti ṣalaye pe awọn kudi kudiẹ imọ rọ lo fa a ti awọn ko fi ri awọn esi idibo to wa lati ibudo idibo ko sori ẹrọ ayarabiaṣa.

Fun idi eyi, awọn nnkan marun yii ni Ọgbẹni Mahmood Yakubu ni yoo ṣẹlẹ lasiko idibo Gomina gẹgẹ bo ṣe bojuwo awọn ipenija ti wọn koju.

Ohun marun-un ti INEC yoo ṣe lasiko idibo Gomina

BVAS

Oríṣun àwòrán, OTHERS

  • INEC yoo ṣe idanilẹkọ mii fun awọn oṣiṣẹ sarenbaja ti wọn gba ti wọn kopa ninu eto idibo to kọja.
  • Lọjọ idibo gangan, INEC yoo lo ẹrọ Bimodal Voter Accreditation system (BVAS) lati mu ki iṣẹ ya.
  • Gbogbo oṣiṣẹ ti wọn ba gbamu pe o ṣe ṣegeṣege yala oṣiṣẹ sarenbaja ni tabi ojulowo oṣiṣẹ koda to fi mọ awọn ọga ajọ INEc nibẹ ti yoo ko ibo jọ tabi ṣe adari ikọ ko ni kopa ninu awọn eto idibo to ba n bọ.
  • Awọn alaga ajọ eleto idibo ni ipinlẹ yoo gbe igbesẹ ifiyajẹni lodi si ẹnikẹni ti wọn ba ri aridaju pe o ṣe lodi si ofin.

Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu alakalẹ, ipinlẹ mejidinlọgbọn ni yoo ṣe idibo gomina ati ti aṣoju-ṣofin ni ọjọ Kọkanla Oṣu Kẹta ti wọn si ni esi rẹ yoo jade lọjọ kan naa.

Ẹwẹ, ọjọ Iṣẹgun ọjọ Keje Oṣu Kẹta ni wọn ni awọn fun awọn Sẹnetọ ti wọn dibo yan ni iwe ẹri mo yege ni ibudo ikobojọ to wa ni Abuja nigba ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin yoo gba tiwọn ni ọjọ Kẹjọ Oṣu Kẹta ni ibi kan naa.