Tinubu, má gbàgbé àtúntò Nàíjíríà, Atiku, Obi, ẹ gbà àlááfíà láàyè - Afenifere

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bola Tinubu
Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ki aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bọla Ahmed Tinubu ku oriire bo se jawe olubori ninu ibo aarẹ to kọja.
Wọn si ni aṣeyọri yoo mu isọkan wa si orilẹede Naijiria.
Atẹjade kan ti akọwe ipolongo fẹgbẹ Afenifere, Comrade Jare Ajayi buwọlu lati fi ki Bola Tinubu, aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan ku orire, ni eyi ti jẹyọ.
Afenifere ni ibo ti Tinubu ati Igbakeji rẹ, Kashim Shettima ri kaakiri orilẹede yii fihan pe awọn ọmọ Naijiria ni igbagbọ ninu rẹ lati se atunṣe tí yoo mu irọnu de ba Ilẹ yii.
Ẹgbẹ Yoruba naa ni aseyọri Tinubu ko jẹ iyalẹnu nítorí o kaju ipo, to si ni iriri ati oye lati jẹ olori ti yoo mu gbogbo ileri rẹ wa si ìmusẹ.
Ẹgbẹ Afenifere wa rọ Tinubu pe ko ma gbagbe adehun rẹ lori ọrọ atunto orilẹede Naijiria.
"Tinubu ni ero ati erongba yoo jẹ ki awọn ọmọ Naijiria ja aramọ ilọsiwaju Orilẹede sugbọn a rọ Tinubu ko ma jawa kulẹ.
"Tinubu gbọdọ ri pe gbogbo ileri to ṣe nigba to n gba iwe ẹri lọwọ alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu, wa si imusẹ.
"Tinubu gbọdọ rí pe alaafia jọba lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi o ṣe ṣe ileri."
Bakan naa ni Afenifere ke si awọn oludije yooku lati gba alaafia laaye lẹyin ti ajọ INEC kede ẹni to bori eto idibo.
Atẹjade naa wa rọ awọn oludije to ba kẹfin magomago ninu eto idibo lati morile ileẹjọ pẹlu alaafia lati tako esi idibo.
"Awọn ẹgbẹ oṣelu ati oludije ni anfani lati gbe ẹhonu wọn lọ ileẹjọ laisi rogbodiyan to le tabuku alaafia orilẹede Naijria."
Inú mí dùn pé ipò ààrẹ ti padà si ìhà Gúùsù Naijiria – Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Twitter
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria to dibo lati da agbara pada si Guusu orilẹede Naijiria.
Wike ni inu ọhun dun pe opin ẹnu awọn to lodi si ki ipo aarẹ maa yi lati ẹkun kan si omiran ti gbẹnu dakẹ bayii pẹlu bi Bla Ahmed Tinubu ṣe bori ni idibo sipo aarẹ.
Bola Tinubu to bori pẹlu ibo to le ni miliọnu mejọ lo wa lati iha Guusu orilẹede Naijiria.
Gomina Wike ọhun lo sọrọ lasiko ti o darapọ mọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lati ṣi ile epo 5,000,000-litre Aviation Fuel Dispensing Depot ni agbegbe papakọ ofurufu ni Alakia, nipinlẹ Eko.
Saaju idibo sipo aarẹ naa ni Wike ti fi idirẹmi ninu idibo abẹle lati dije du ipo aarẹ.
Lẹyin naa ni Wike ti bẹrẹ si ni fi aidunnu rẹ han si bi Atiku Abubakar sẹ jawe olubori ninu idibo naa.
Bakan naa ni Wike fi idunnu rẹ han si pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde fun bi o ṣe ṣe atilẹyin fun ki agbara ijọba pada si Guusu orilẹede Naijiria.












