Bí ìgbẹ́jọ́ lórí ohun tó ṣekúpa Whitney Adeniran ṣe lọ lónìí rèé

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland, Whitney Adeniran tó papòdà ní oṣù tó kọjá.

Ní ilé ẹjọ́ Májísíréètì tó wà ní Ogba, Ikeja ni ẹjọ́ náà ti ń wáyé, níwájú adájọ́ Olanike Fajana.

Gbajúgbajà agbẹjọ́rò nnì, Femi Falana ló ń gba ẹjọ́ rò fún àwọn ẹbí Adeniran tó jẹ́ ẹbí olóògbé, tí Enitan Olukayode sì ń gba ẹjọ́ rò fún ilé ẹ̀kọ́ Chrisland.

Akin George ló ń ṣojú ìjọba ìpínlẹ̀ Eko nínú ìgbẹ́jọ́ náà.

Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀, Falana sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ní ẹlẹ́rìí méjì tí yóò máa jẹ́jọ́ tako ilé ẹ̀kọ́ Chrisland lórí ohun tó ṣokùnfà ikú ọmọ náà.

Àmọ́ agbẹjọ́rò Chrisland, Enitan Olukayode sọ fún ilé ẹjọ́ pé ẹlẹ́rìí bíi mẹ́jọ ni àwọn ní láti fìdí ẹjọ́ àwọn múlẹ̀.

Bákan náà ló sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ti ṣaájú kọ̀wé ránṣẹ́ láti bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ gba àwọn láàyè láti lo ṣàmúlò àwọn èsì àyẹ̀wò ohun tó ṣokùnfà ikú Whitney fún àyẹ̀ò tó péye lọ́dọ̀ ti wọn náà.

Femi Falana wá sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé ikọ̀ òun kò ì tíì rí ìwé náà gbà àti pé òun kò ní le sọ ohunkóhun lórí rẹ̀ báyìí ná.

Adájọ́ Fajana wá darí agbẹjọ́rò Chrisland láti gbé ìbéèrè wọn gba ọ̀nà tó yẹ kí ilé ẹja le fèsì le bó ṣe tọ́.

Adájọ́ wá sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ Kẹta àti ọjọ́ Kẹrin oṣù Kẹrin ọdún 2023 láti tẹ̀síwájú lórí ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún.

Ẹ forí jì wá, àdánù ńlá ni ikú Whitney Adeniran jẹ́ fún wa – ilé ẹ̀kọ́ Chrisland

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland ti tọrọ àforíjì lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ wọn, Whitney Adeniran tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń ṣe eré ìdárayá.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí ilé ẹ̀kọ́ náà fi sórí Instagram wọn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹta ni wọ́n ti ń bèèrè fún àforíjì àwọn ènìyàn lórí ikú ọmọ náà.

Wọ́n ní àdánù ńlá ni ikú ọmọ náà jẹ́ fún àwọn àti pé ọkàn àwọn pami fún àwọn ẹbí olóògbé ọ̀hún.

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ẹbí Whitney àti gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀ bí wọ́n ṣe ní nǹkan ńlá ni ilé ẹ̀kọ́ àwọn pàdánù lórí ikú ọmọ náà.

A ò fẹ́ ìfaǹfà la ṣe dákẹ́ láì sọ ohunkóhun

Bákan náà ni àwọn aláṣẹ́ náà tún tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn káàkiri Nàìjíríà nítorí bí àwọn ṣe kọ̀ láti sọ ohunkóhun láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Wọ́n ní ìdí tí àwọn fi dákẹ́ ni pé ikú ọmọ náà bá àwọn lójijì àti pé àwọn kò fẹ́ máa tàkurọ̀sọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn kí àwọn tún má lọ sọ àwọn nǹkan tó yẹ.

Àwọn aláṣẹ náà fi kun pé àwọn kọ̀ láti sọ̀rọ̀ nítorí àwọn fẹ́ fún àwọn òbí Whitney láàyè láti ṣọ̀fọ̀ ọmó wọn ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.

“Ọmọ ológo tó gbájúmọ́ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀, a ò le gbàgbé rẹ̀ títí láé.”

A ò ní èròńgbà láti hú òkú Whitney fún àyẹ̀wò mìíràn

Àtẹ̀jáde tí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland fi síta náà ní àwọn ò gbèrò láti tún òkú Whitney hú fún àyẹ̀wò mìíràn.

Wọ́n ní àhésọ ọ̀rọ̀ lásán ni ìròyìn tí àwọn ènìyàn kan ń gbé kiri pé ilé ẹ̀kọ́ àwọn ń bèèrè fún pé kí àwọn tún òkú ọmọ náà hú.

Wọ́n sọ síwájú pé àwọn kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nítorí òbí ni àwọn náà jẹ́ àti pé àwọn kò le gbèrò láti máa fi ara ni ọmọ tó ń sùn láyà olùgbàlà.

Wọ́n ní dípò bẹ́ẹ̀ àwọn ní èròńgbà láti fi ohun kan sọ orí Whitney kí orúkọ rẹ̀ má ba à parẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn tún ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti ri dájú pé ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ kẹ́sẹ járí.

Wọ́n fi kun pé àwọn kò ní fi àwọn mọ̀lẹ́bí Adeniran sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe ti ń ṣe láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Ilé ẹ̀kọ́ Chrisland yóò wà ní títì pa kí ìwádìí lè tẹ̀síwájú – Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko

Whitney Omodesola Adeniran

Oríṣun àwòrán, Daily Post

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe ile ẹkọ girama Chrisland yoo wa ni titi pa ni bayii ti iwadii iku akẹkọọ Whitney Omodesola Adeniran ṣi n lọ lọwọ.

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ sọ pe ọmọ ọdun mejila naa ṣubu lulẹ lasiko ere idaraya onilejile to waye ni papa iṣere kan niluu Eko.

Lẹyin rogbodiyan to waye latari iku ọmọ naa, ijọba Eko, lati ọwọ adajọ agba ipinlẹ naa, Moyosore Onigbanjo, paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Ninu atẹjade kan, kọmiṣọna eto ẹkọ ipinlẹ ọhun, Folasade Adefisayo sọ pe lai ṣe akoba fun ilana ofin, igbeṣe lati gbe ile ẹkọ ọhun ti pa waye lọna ati ṣe iwadii siwaju.

O ni “lẹẹkan sii, a ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, a si n fi da awọ olugbe ipinlẹ Eko loju pe ko si ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iku ọmọ naa ti ko ni foju wina ofin.”

Kọmiṣọna ọhun tun ṣe alakalẹ awọn igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Eko ti gbe lori iku ọmọ naa.

O ni apapọ igbimọ to n ja fun ẹtọ ọmọde nipinlẹ Eko ko sinmi lori ọrọ ọhun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbimọ naa ti ṣabẹwo si ọgba ile ẹkọ Christland, to fi mọ papa iṣere Agege ti iṣẹlẹ iku rẹ ti waye.

O fi kun pe awọn tun ti ṣabẹwo ibanikẹdun si mọlebi ọmọ naa.

Ni ti igbesẹ lati gbe ile ẹkọ ọhun ti pa, o ni “A ti ile ẹkọ naa latari pe iṣẹlẹ ọhun da lori abo awọn ọmọde.”

“Igbesẹ naa yoo tun fun wa lanfani lati ṣe iwadii ti ko ni magomago kankan ninu, yoo si fun gbogbo awọn ti ọrọ ọhun kan lanfani ati kẹdun.”

A ò ní gbà kí wọ́n tún òkú Whitney Adeniran hú - ìjọba Eko fèsì

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ní àwọn kò ní gbà kí ilé ẹ̀kọ́ Chrisland hú òkú Whitney Adeniran lẹ́yìn tí àwọn òbí rẹ̀ ti sín.

Nínú oṣù Kejì ọdún 2023 ni Whitney Adeniran, ọmọ ọdún méjìlá, akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Chrisland, Opebi, ìpínlẹ̀ Eko dágbére fáyé lásìkò tí wọ́n ń ṣe eré ìdárayá ní ilé ẹ̀kọ́ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ará ìlú ní iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Eko, Grace Alo fi síta lọ́ja Àbámẹ́ta ló ti sọ̀rọ̀ náà.

Alo ní ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti gbọ́ sí ìfaànfà tó ń wáyé lórí èròńgbà láti lọ hú òkú ọmọ náà láti ṣe àyẹ̀wò mìíràn fun.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti ń gbọ́ fìnfìn pé wọ́n ń gbèrò láti hú òkú ọmọ náà, ó ní àwọn kò ì tíì rí ìbéèrè ilé ẹ̀kọ́ náà gbà àti pé àwọn kò ní fi ààyè gba irú rẹ̀ tí wọ́n bá wá.

Ó ṣàlàyé pé lábẹ́ òfin ọdún 2015, ìdí tí wọ́n fẹ́ fi hú òkú ọmọ náà kò sí nínú nǹkan tí àwọn fi lè buwọ́lu ìrúfẹ́ ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ló ní àwọn kò fẹ́ kí ọgbẹ́ ọkàn àti ìdáàmù tí àwọn ẹbí ọmọ náà ń kojú pọ̀ jù bó ṣe yẹ lọ.

“À ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n sì ti sọ àrídájú rẹ̀ fún wa pé àwọn máa fi ẹ̀dà ìwé ẹjọ́ ọmọ náà máa dé iwájú ẹ̀ka tó ń báni ṣe ẹjọ́ lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹta fún ìgbésẹ̀ òfin tó péye.”

Ẹ ó rántí pé èsì àyẹ̀wò ilé ìwòsàn LASUTH ní asphyxia àti pé ọmọ náà gan mọ́ iná ló pa á.

Aspphysia ni kí èémí ènìyàn ṣàdédé dúró ní òjijì nítorí kò sí èémí tó lára.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Ẹ gbà mí o! Ilé ẹ̀kọ́ Chrisland fẹ́ kí ọlọ́páá hú òkú ọmọ mi láti tún àyẹ̀wò ṣe - Ìyá Whitney Adeniran

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, bam.babycity

Ẹ o ranti pe ni owurọ yii ni iya Whitney Adeniran, akẹkọọ Christland College to di oloogbe, ti ke gbajare sita lori igbesẹ tuntun mii to ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa fẹ gbe.

Iya Akẹkọọ ọhun, Blessing, sọ loju opo Instagram rẹ pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa lo tun kan si awọn ọlọpaa lẹyin ti oun sin ọmọ oun tan lọjọbọ.

O ni ile ẹkọ ni oun tun fẹ ṣe ayẹwo oku ọmọ oun lẹẹkeji lẹyin ti wọn ti kọkọ ṣe ayẹwo akọkọ, eyii to fi han pe ṣe oloogbe ọhun gan mọ ina ku ni.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Ọjọbọ ni wọn sin oku Whitney pẹlu omije loju iya rẹ atawọn ẹbi mii ti wọn peju sibi eto isinku ọhun.

"Wọn fẹ wu oku ọmọ mi lati tun maa ge ara rẹ ni igekuge.”

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instgagram rẹ, ni iya ọmọ ọhun ti ke sita bẹẹ.

O ni “Christland!!! Ẹ maa ṣe erekere yin o!!!”

“Wọn ṣẹṣẹ pe mi bayii ni pe awọn ọlọpaa sọ pe awọn fẹ tun ayẹwo oku ọmọ mi ṣe.”

“Wọn fẹ wu oku ọmọ mi lati tun maa ge ara rẹ ni igekuge.”

Ikede mama naa lo mu ki ọpọ eeyan maa ba daro, ti wọn si n fapa janu pe ki lo de ti wọn yoo tun se hu oku ọmọ naa sita.

Bakan naa ni ọpọ eeyan n gbara ta pe igbesẹ naa lo mu akọtun ibanujẹ bawọn obi akẹkọ naa.

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, bam.babycity

Ki ni esi ayẹwo akọkọ sọ pe o ṣokunfa iku Whitney Adeniran?

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe ina mọnamọna lo ṣokunfa iku Whitney Adeniran, akẹkọọ Christland to jẹ ọmọ ọdun mejila to ku lasiko ere idaraya ile ẹkọ rẹ.

Ninu atẹjade kan ti adajọ agbajọ ipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo, SAN, fi lede, lo ti sọ bẹẹ.

O ni ayẹwo ti ile iwosan ẹkọṣe iṣẹgun ipinlẹ Eko, LASUTH, ṣe lo fi han bẹẹ.

Atẹjade naa ni “Ijọba ipinlẹ Eko ba awọn mọlẹbi oloogbe kẹdun, a si fi da awọn eeyan ipinlẹ Eko loju pe ẹnikẹni ti ọrọ iku ọmọ naa ba kan yoo foju bale ẹjọ laipẹ.”

Ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2023 ni Onigbanjo paṣẹ ki wọn ṣewadii ohun to ṣokufa iku ọmọ naa lasiko ti wọn n ṣe ere idaraya onilejile ile ẹkọ ọhun ni papa iṣere kan niluu Eko.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Ijọba Eko sabẹwo ibanikẹdun si ẹbi Whitney Adeniran

Wayi o, Ijọba ipinlẹ Eko ti se abẹwo sile ẹbi Whitney Adeniran, to si fọwọ sọya fun wọn pe gbogbo ọna ni oun yoo fi wa idajọ ododo fun oloogbe naa.

Atẹjade kan ti Kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Eko, Folashade Adefisayo fisita lo sisọ loju ọrọ naa.

O wa kede abẹwo ikọ rẹ sile oloogbe akẹkọọ Chrisland to ku naa lasiko ere idaraya 7onilejile ileẹkọ naa.

Bakan naa ni kọmisana eto ẹkọ nipinlẹ Eko wa fidi rẹ mulẹ pe gomina Babajide Sanwo-Olu yoo saayan to ba yẹ lati gbe ẹnikẹni to ba wa nidi iku akẹkọọ naa lọ sile ẹjọ.

O wa kede fawọn obi akẹkọọ naa pe ileesẹ Eto ẹkọ nipinlẹ Eko ba wọn kẹkun, ti awọn si wa pẹlu ẹbi naa lasiko ti wọn n poungbẹ fun idajọ ododo lori iku ọmọ wọn.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 4

Bawo ni Whitney Adeniran, akẹkọọ Chrisland se ku ati awọn ohun to ti waye

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Whitney Adeniran, tii se ọmọ ọdun mejila lo jẹ akẹkọọ ile ẹkọ girama Chrisland to wa ni adugbo Opebi nilu Eko.

Eto idije ere idaraya onilejile ti ile ẹkọ rẹ seto ni akẹkọọ naa lọ amọ ti ko pada wa sile mọ.

Sadede ni ile ẹkọ Chrisland bun awọn obi rẹ gbọ pe ọmọde binrin naa n saisan, to si subu lulẹ lasiko ere idaraya onilejile naa, to si ku loju ẹsẹ.

Iroyin ibanujẹ yii lo mu ki mama ati baba ọmọdebinrin naa bọ sori ayelujara lati ke sawọn ọmọ Naijiria pe ki wọn gba awọn.

Wọn ni ọmọ awọn ko se aisan kankan ko to kuro nile, to si ya awọn lẹnu pe iroyin iku rẹ ni wọn mu wa fun awọn.

Mama Whitney tun ke gbajare pe lẹyin ọjọ diẹ, awọn akẹkọọ ti isẹlu iku ọmọ oun soju wọn nibi ere idaraya naa sọ fun oun pe Whitney gan mọ ina ni.

Idi ree ti ẹbi naa se n ke si ileẹkọ Chrisland pe ko sọ otitọ ọrọ to wa nidi iku ọmọ naa fun awọn nitori awijare rẹ pe ọmọ awọn subu, to si ku, ko jẹ itẹwọgba.

Iroyin iku akẹkọọ naa di eyi to gbajugbaja lori ayelujara, ti ijọba ipinlẹ Eko si pasẹ pe ki wọn lọ se ayẹwo awọn dokita lati mọ iru iku to pa akẹkọ naa.

Nibayii, esi ayẹwo naa ti jade, to si ti foju han pe Whitney Adeniran, akẹkọọ Chrisland gan mọ ina ni.

Wọn ti sin akẹkẹ naa lẹyin ayẹwo ọhun, ti ijọba ipinlẹ Eko si leri leka pe ohun yoo sewadi awọn eeyan to lọwọ ninu isẹlẹ naa lati foju wọn ba ile ẹjọ.