INEC gbọ́dọ̀ yanjú gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ tó wáyé lásìkò ìbò Ààrẹ ṣáájú ìdìbò gómìnà – Ìjọba Amẹrika

Mary Beth Leonard

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic

Lẹyin eto idibo to gbe Bola Tinubu wọle gẹgẹ Aarẹ Naijiria, ijọba ilẹ Amẹrika ti sọ pe eto idibo naa ko lọ bii awọn ọmọ Naijiria ṣe lero.

Aṣoju ijọba ilẹ Amẹrika si Naijiria, Mary Beth Leonard, lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan.

Leonard sọ pe ọpọ araalu lo n binu ti inu wọn ko si dun si esi ibo naa, bo tilẹ jẹ pe awọn kan n ṣajọyọ pe esi ibo ọhun lọ bi awọn ṣe fẹ.

O ni “O han gbangba pe gbogbo bi eto idibo ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji ṣe lọ kuna lati ri bi awọn ọmọ Naijiria ṣe lero.”

“Mo ti sọ lọpọ igba ṣaaju eto idibo naa pe Naijiria ti ṣe ọpọ aṣeyọri ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin lẹyin to ti pada si ijọba awarawa, ati pe bo ṣe n ṣe eto idibo rẹ wa lara awọn aṣeyọri ọhun.”

“Awọn eeyan Naijiria ti ṣe afihan bi ijọba awarawa ṣe ṣe pataki si wọn to lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, amọ ọpọ ninu wọn lo n binu ti wọn si wa ninu ibanujẹ bo tilẹ jẹ pe awọn kan ṣajọyọ pe eto idibo naa lọ bo sẹ yẹ.”

Leonard teṣiwaju pe ko yẹ ki awọn ọmọ Naijiria jẹ ki ọrọ oṣelu fa ipinya laarin wọn, ki ẹni ti esi ibo naa ko ba tẹ lọrun si gba ile ẹjọ lọ.

INEC gbọdọ yanju kudiẹkudiẹ to wa nilẹ ṣaaju idibo gomina

Aṣoju ilẹ Amẹrika ọhun wa ke si ajọ INEC lati tete yanju gbogbo awọn kudiẹkudiẹ to ṣi wa nilẹ ṣaaju eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta.

O sọ siwaju si pe INEC gbọgọ ṣe agbeyẹwo awọn iṣoro to waye ninu ibo Aarẹ ki wọn si ri daju pe iru rẹ ko waye ninu eto idibo gomina.

Leonard wa gboriyin fun Atiku Abubakar ati Peter Obi fun ipinnu wọn lati lọ sile ẹjọ dipo ki wọn da wahala silẹ.

O tun fi akoko naa ki ẹni to jawe olubori ninu eto idibo ọhun, Asiwaju Bola Tinubu ku oriire fun aṣeyọri rẹ ninu eto idibo ọhun.

Apapọ iye ibo to gbe Tinmubu wọle gẹgẹ bii Aarẹ ti awọn araalu dibo yan jẹ 8,794,726.