'Mo ti ń múra láti "japa" tẹ́lẹ̀ kí n tó borí nínú ìbò aṣojúṣòfin'

Oríṣun àwòrán, Engr. Esosa Iyawe Fanpage
Esosa Iyawe, to ṣẹṣẹ jawe olubori ninu idibo sipo aṣojuṣofin ẹkun Oredo, nipinlẹ Edo ti sọ iriri rẹ fun araye.
O ni o ti pẹ ti oju oun ti wa lara ipo aṣaaju, amọ oun korira bi awọn oloṣelu Naijiria ṣe hu iwa ni oun ṣe n yẹba.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch lo ti ṣalaye ọrọ naa.
Iyawe sọ pe “Ki eeyan to le wọ inu oṣelu ni Naijiria, o gbọdọ ni owo gọbọi tabi ko ṣe awọn nnkankan ti a ko le maa sọ ki wọn to le gbe e jade gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ.”
O sọ siwaju sii pe oun ti n gbero lati fi Naijiria silẹ ki oun to wọ eto oṣelu ati pe afojusun oun lati tun ilu ṣe lo mu ki oun di oloṣelu.
O ni: “Lakoko igba kan, mo n gbero lati fi Naijiria silẹ lọ si orilẹede mii nitori ko si nnkankan ti a n ri nidi iṣẹ wa latari bi owo dollar ṣe n lọ soke.”
“Bo tilẹ jẹ Naijiria ni ọpọ alumọni ti awọn orilẹ-ede ti a n salọ ko si ni idamẹwaa awọn nnkan ti a ni, wọn n gbe igbe aye irọrun nibẹ ju ti wa nibi lọ.”
“Amọ nigba to ya, mo pinnu lati dije pẹlu igbagbọ pe ti Peter Obi ba wọle gẹgẹ bii Aarẹ, mo maa wa lara awọn ti yoo ṣe ofin ti yoo ran an lọwọ lati tun Naijiria ṣe.”
Ẹni ogoji ọdun naa ni gbogbo awọn to dije ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo Aarẹ to kọja ti n gbaradi lati ri daju pe ẹgbẹ naa ko fidi rẹmi lawọn idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu yii.
Akẹkọọjade ile ẹkọ Benson Idahosa University, ni Iyawe ko to dije fun ipi aṣojuṣofin ọhun.












