INEC: Ọjọ idibo láti 2019 sí 2055 ti wà l‘ákọọ́lẹ̀

Awọn oludibo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ to n risi eto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede ọjọ idibo gbogbo-gboo lati ọdun 2019 si 2055.

Ọjọ idibo gbogbo-gboo tọdun 2019 ti waye lọjọ kẹrindinlogun, osu keji ati ojo keji, osu kẹta odun 2019. Bẹẹ si ni ti ọdun 2023 ti waye.

Eyi ti hande lati ọdun 2018 ti Alaga ajọ eleto idibo INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣe ikede yii nigba to n sepade pẹlu awọn adari ẹgbẹ oselu to wa lorilẹede Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe ohun ti wọn fi sinu alakalẹ ni pe lọdun 2023, idibo yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, osu keji ati ojo kẹrin, osu kẹta, ọdun naa.

Amọṣa, ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Keji lo pada waye eyi tii ṣe ọjọ Satide ti idibo ti gomina ati aṣoju-ṣofin yoo si waye ni ọjọ Kẹrinla Oṣu kẹta ọdun 2023.

Awọn deeti ọjọ idibo toku titi di ọdun 2055 ree

Mahmood Yakubu

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán, Idibo ọdun 2019 yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, osu Keji ati ojo keji, osu Kẹta, ọdun kan naa.

Ni 2027, ọjọ̀ idibo naa ni ogunjọ,osu Keji ati ojo kẹfa, osu Kẹta, ni 2031, o ma waye ni ọjọ karundinlogun, osu Keji ati ọjọ kini osu Kẹta.

Lọdun 2035, ojo kẹtadinlogun, osu Keji ati ojo kẹta, osu Kẹta ni yoo waye: pẹlu ọjọ kọkandinlogun, osu Keji ati ọjọ karun, osu Kẹta, ọdun 2039.

Ero idibo Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajọ Inec ni ipolongo ọjọ idibo saaju ọdun naa yoo mu idagbasoke ba eto oselu lorilẹede Naijria

Bakan naa, lọdun 2043, idibo yoo waye lọjọ kokanlelogun, osu Keji ati ọjọ keje, osu Kẹta ninu ọdun naa. Ti 2047 yoo waye lọjọ karundinlogun, osu Keji ati ojo keji, osu Kẹta.

Ọjọ idibo gbogboogbo ti ọdun 2051 ati tọdun 2055 yoo waye ni ọjọ kejidinlogun ninu osu Keji ati ọjọ keji osu Kẹta, pẹlu ogunjọ, osu Keji ati ọjọ kẹfa, osu Kẹta ninu ọdun 2055.

Alaga ajo Inec naa, fikun ọrọ rẹ wipe awọn orilẹede lagbaye to ti yege ninu eto oselu tiwantiwa, ma n se ikede ọjọ idibo ni ọgọọrọ ọdun sehin ko to di wipe, ọdun naa yoo de.

Yakubu salaye wipe idi ti awọn fi n se ipolongo yii sile ni lati jẹki awọn tọrọ naa kan se igbaradi to peye lakoko ati lati lati mu idagbasoke ba eto oselu lorilẹede Naijria.