Bunmi Solabi: Òṣìṣẹ́ Báńkì tó di 'mẹ́kò' sọ̀rọ̀ lórí ìdùnnú lẹ́nu iṣẹ́ ẹni

Àkọlé fídíò, Ìnú mi kìí dùn nígbà trí mo ń ṣiṣẹ́ ni bánkì tó ìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ mẹkáníìkì

Bunmi: 'Race Driver' ni n bà ṣe ká ni Amẹrika ni wọ́n bi mi sí kódà Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn èèyàn pé mo lọ kọ́ṣẹ́ mọkaliiki.

Arábinrin to yan iṣẹ́ owọ́ àwọn to n tún ọkọ̀ ṣe ni Naijiria láàyò ṣalaye ìdí ti òun fi fiṣe akọ̀wé nile ifowopamọ silẹ̀ lọ kọṣẹ atun-ọkọ-ṣe.

Bunmi Solabi ti gbogbo eniyan mọ si 'Lady Mech' sọ fún BBC Yorùbá pé ẹ̀rín ti àgbàrá n rín pàdé odò lọ́nà ni òun naa ma n rin ti àwọn eniyan ba n fi oun ṣe yẹyẹ lẹnu iṣẹ mẹkaniiki nigba ti oun kọkọ bẹ̀rẹ̀.

Bunmi ṣalaye irufẹ atilẹyin ti ọkọ rẹ̀ ṣe fun un nigba to wòye pé ayọ̀ oun kò kún lẹnu iṣẹ banki.

O ni kí onikaluku gbe ìgbésẹ̀ láti ṣiṣẹ to ba wù wọn nitori pe idunnu lẹnu iṣẹ ẹni ṣe pataki.

Arabinrin akọni ti ọpọ gba pé o n ṣiṣẹ ọkunrin gba àwọn obinrin nimọran pé: ẹ ni agbára ati oore ọfẹ lati ṣe ohunkohun to wu yin nigba to wu yin, ẹ dijú gbé igbesẹ akin ki ẹ tẹsiwaju.

O ni agbára abo kọja ti ọmọ bibi nikan laye ode òní.