Labour Party Oyo kọrin àtìlẹyìn fún Seyi Makinde, Tawfiq Akinwale fọnmú

Tawfiq Akinwale, Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook

Bí ètò ìdìbò sípò gómìnà ní àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ku ọjọ́ mẹ́fà ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Oyo ti panupọ̀ láti dìbò fún gómìnà Seyi Makinde.

Àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ìpínlẹ̀ Oyo níbi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kẹta, ọdún 2023 darí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn láti dìbò fún gómìnà Seyi Makinde tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party nínú ìdìbò gómìnà tí yóò wáyé lọ́jọ́ Sátidé.

Tawfiq Tayo Akinwale tó jẹ́ olùdíje sípò gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nínú àtẹ̀jáde kan ní òun kò juwọ́ kalẹ̀ fún olùdíje kankan.

Akinwale ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni àwọn ti ṣe kó tó di àsìkò yìí, tó sì ṣe ìkìlọ̀ fún alága ẹgbẹ́ náà láti jìnà sí àwọn nǹkan tó le sọ ẹgbẹ́ àwọn di àtẹ̀mẹ́rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo.

Ó ní òun kò ju ọwa sílẹ̀ fún olùdíje tàbí ẹgbẹ́ kankan àti pé òun ṣì ni ojúlówó olùdíje sípò gómìnà fẹ́gbẹ́ Lanour Party.

A ti fẹnukò láti dìbò fún Seyi Makinde àmọ́ àwọn olùdíje sílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo lẹ́gbẹ́ wa ṣì ń díje - Alága Labour Party Oyo

Àwọn adarí Labour Party lásìkò tí wọ́n ń ṣèpàdé

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Àwọn adarí Labour Party lásìkò tí wọ́n ń ṣèpàdé

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour nípìnlẹ́ Oyo, Atayase Sadiq ní gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó so ìpínlẹ̀ Oyo ró ló panupọ̀ pé Seyi Makinde ni kí àwọn dìbò fún.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní èsì ìbò ààrẹ tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ti ṣàfihàn pé ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́ta gbòógì ló wà ní Nàìjíríà báyìí àti pé gbongbo Labour Party ti ń rẹ́sẹ̀ walẹ̀.

Atayase ní èyí ló mú kí àwọn wo sààkun nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ àwọn, kí àwọn sì ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje tó kájú òṣùwọ́n, tó sì ní ìwà ọmọlúàbí.

Ó ní àwọn wo olùdíje tí ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo wà ní oókan àyà rẹ̀ nítorí ohun tó jẹ ẹgbẹ́ àwọn lógún ni ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo.

Ó fi kun pé ìdí nìyí tí àwọn fi wo olùdíje àti ẹgbẹ́ tí òye àti ìmọ̀ àwọn nípa ìpínlẹ̀ Oyo ṣọ̀kan nípa ètò ààbò, ohun ọ̀gbìn àti ọrọ̀ ajé.

“Ìṣèjọba tó wà lóde lábẹ́ ìdarí gómìnà Seyi Makinde ni a rí tó le ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí la ṣe gbà láti darí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa láti dìbò fun.”

Bákan náà ló sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé ẹgbẹ́ àwọn ṣì wà digbí, àti pé gbogbo àwọn olùdíje ẹgbẹ́ àwọn tó ń wá ipò ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n ṣì ń díje.

Ó fi kun pé ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn ní àpapọ̀ ló ms sí ìpinnu yìí.

Teslim Folarin ni ipò gómìnà Oyo kàn, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ṣetán láti gbàjọba padà - Adebayo Shittu

Teslim Folarin, Adebayo Shittu ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Collage

Mínísítà fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, Adebayo Shittu ti ní ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Oyo ti ṣetán láti náa tán bí owó pẹ̀lú gómìnà Seyi Makinde láti gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀.

Ó ní ẹgbẹ́ APC máa gba ìjọba àti àkóso ìpínlẹ̀ Oyo níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà èyí tó máa wáyé lọ́jọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹta ọdún 2023.

Nígbà tó ń forí àṣeyọrí ẹgbẹ́ òṣèlú APC lásìkò ìbò ààrẹ àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ èyí tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá sọ ìfẹ́ táwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà ní sẹ́gbẹ́ wọn, Shittu ní àwọn tún máa borí nínú ìbò gómìnà.

Shittu sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé òun mọ̀ wí pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo fẹ́ràn láti máa bá àwọn tó ń ní ìlọsíwájú tò nítorí náà ni wọ́n ṣe tẹ̀lé ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú ìbò ààrẹ tó kọjá.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Tí kìí bá ṣe ìfaǹfa tó wáyé láàárín àwọn adarí ẹgbẹ́ lọ́dún 2019, a ò ní pàdánù ipò gómìnà sọ́wọ́ PDP nítorí àti ìgbà ìbò abẹ́nú ni ẹgbẹ́ ti ń ṣe ségesège.”

“Ọ̀pọ̀ àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ wa ló ṣiṣẹ́ fún àṣeyọrí Seyi Makinde lọ́dún 2019, ìdí nìyí tó fi gbégbá orókè nínú ìbò náà àmọ́ kò ṣe àmúlò ipò náà dáadáa.”

Shittu, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àjọṣepọ̀ tó wà láàárín òun àti Seyi Makinde àti ìdí tó ṣe ń polongo fún Teslim Folarin báyìí, ó ní Seyi Makinde ti fi ìgbà kan rí gbà láti ṣe igbákejì òun nígbà tí òun ń gbèrò láti wá tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ òun láti dupò gómìnà.

Ó ní yàtọ̀ sí èyí, ìgbà tí òun di mínísítà, Makinde fún òun ní ọkọ̀ èyí tó mú kí àwọn ènìyàn máa sọ wí pé òun ń ṣe ojú méjì nínú ẹgbẹ́ àwọn.

Ó fi kun pé èyí ló fà á tí wọn kò fi fún òun ní àǹfàní láti ṣe mínísítà fún ìgbà kejì mọ́.

Bákan náà ló ní òun ju ọwa sílẹ̀ fún Teslim Folarin nítorí ẹni tó máa ń gbọ́ràn, tó sì jẹ́ ẹni tí ènìyàn le fi ọkàn tán àti pé àwọn ti ṣetán láti ri pé àwọn ṣiṣẹ́ fun láti jáwé olúborí.

Lórí ọ̀rọ̀ bóyá ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Adebayo Adelabu ti Accord Party ń gbèrò láti darapọ̀, Shittu ní àsìkò ọ̀rọ̀ náà kò ì tíì tó sọ ní gbangba báyìí.