Agbẹjọ́rò tó pa ìyàwó àtọmọ rẹ̀ láti bo ìwà àjẹbánu mọ́lẹ̀ rí ẹ̀wọ̀n he

Oríṣun àwòrán, Maggie Murdaugh/Facebook
Ilé ẹjọ́ kan ní South Carolina ti dá agbẹjọ́rò kan lẹ́bi ẹ̀sùn wí pé ó pa ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin láti fi dọ́gbọ́n bo owó tùùlù kan tó kó jẹ.
Láàárín wákàtí mẹ́ta ni adájọ́ náà fi gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wà lórí ẹjọ́ náà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà.
Alex Murdaugh tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ló ń kojú ẹ̀sùn méjì èyí tó dá lórí ìpànìyàn.
Ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n ọdún ni wọn jù ú sí fún ẹ̀sùn kọ̀ọ̀kan.
Ìròyìn ní Alex yìbọn pa ìyàwó àti ọmọkùnrin rẹ̀, Maggi àti Paul Murdaugh níbi ilé ajá wọn lọ́jọ́ keje oṣù Kẹfà ọdún 2021.
Alex Murdaugh kò tara rárá nígbà tí adájọ́ gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lálẹ́ ọjọ́bọ̀ ní Walterboro.
Adájọ́ ilé ẹjọ́ South Carolina Circuit, Clifton Newman ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Alex ló pa ìyàwó àti ọmọ rẹ̀.
Murdaugh ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun nítorí òun kò le pa ìyàwó àti ọmọ òun láti fi bo ìwà àjẹbánu.
Lẹ́yìn tí àwọn adájọ́ ẹlẹ́ni méjìlá náà gbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀, àwọn òǹwòran tò sẹ́yìn ilé ẹjọ́ náà láti wo ìdájọ́ ọ̀hún.
Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé?

Oríṣun àwòrán, Maggie Murdaugh/Facebook
Murdaugh tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ agbẹjọ́rò àgbà fún ìpínlẹ̀ rẹ̀, tí ẹbí rẹ̀ náà sì jẹ́ àgbà agbẹjọ́rò ní ẹkùn náà títí di ọdún 2016.
Àmọ́ nígbà tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ń lọ, wọ́n ní Alex jí ọ̀pọ̀ owó tó jẹ́ ti àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti fi gbé ìgbé ayé ńlá.
Ó tó ọdún kan kí wọ́n tó nawọ́ gán Murdaugh lórí ẹjọ́ náà.
Murdaugh sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kan tí wọ́n ń bínú lórí ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi kán tó wáyé lọ́dún 2019 tí ọmọ òun náà wà níbẹ̀ ló pa ọmọ òun láti fi gbẹ̀san.
"Mi ò lè ṣe Maggie àti Paul ní ìjàm̀bá lábẹ́ bí ó ti wù kó jẹ́."
Àwọn tó fẹ́sùn kàn Murdaugh ní fídíò kan tí Paul ṣe ní wákàtí díẹ̀ kí ìṣekúpani náà tó wáyé ló tú àṣírí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Paul àti màmá ẹ̀ kú sí ilé ajá wọn, tí Alex Murdaugh sì ń sọ fún àwọn agbófinró lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé òun kò dé ilé ajá lọ́jọ́ náà, òun ń sùn nínú yàrá ni.
Àmọ́ nínú fídíò Snapchat tí Paul ṣe kó tó kú ni wọ́n ti ń gbọ́ ohùn bàbá rẹ̀.
Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún gbọ́ ẹ̀sùn bí Murdaugh ṣe parọ́ ikú mọ́ ara rẹ̀ nítorí jìbìtì ètò adójútòfò kan lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tó pa ìyàwó àti ọmọ.
Àwọn ènìyàn fi ìdùnnú hàn sí ìdájọ́ náà

Oríṣun àwòrán, Maggie Murdaugh/Facebook
Jessica Williams, ẹni ọdún méjìdínlógójì àti ọmọ rẹ̀ dúró sí ìta ilé ẹjọ́ láti mọ ibi tí ẹjọ́ náà máa jásí.
Ó ní inú òun dùn pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ìgbẹ́jọ́ náà.
Àwọn tó ṣe ìwádìí ẹjọ́ náà ní Alex ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó jẹ tó fi mọ́ tí àwọn oníbàárà àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọ́n ní $3.7 ló kó jẹ nínú ọdún 2019 nìkan tí Murdaugh náà sì gbà nílé ẹjọ́.
Wọ́n fi kun pé ìdí nìyí tó fi pa ìyàwó rẹ̀ láti fi bo gbogbo àwọn ìwà àjẹbánu náà lójú mọ́lẹ̀.















