Ìdájọ́ 'Tribunal' ló mú kí wọn dìbò fún wa l‘Osun - PDP

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun ti ṣàlàyé ìdí tí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà ṣe dìbò fún ẹgbẹ́ wọn níbi ìbò sípò Ààrẹ àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ náà ṣe wí, àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà tú yáyá jáde dìbò fún PDP nítorí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò gbé kalẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló jáwé olúborí ìbò gómìnà Osun.
Ẹ ó rántí pé ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò èyí tí adájọ́ Tershe Kume ṣáájú rẹ̀ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC, Gboyega Oyetola ló jáwé olúborí ìbò gómìnà Osun tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 2022.
Àtẹ̀jáde kan tí adarí ìròyìn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Osun, Oladele Bamiji fi léde ní ìdájọ́ náà ru ọkàn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun sókè.
Bamiji ní àwọn ènìyàn rí ìdájọ́ náà pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC fẹ́ gbà ògo tí kìí ṣe ti wọn lò ni ìdájọ́ náà jẹ́.
Ó tẹ̀síwájú pe ìdí nìyí tí àwọn ènìyàn náà kò ṣe fàyè gba APC láti rí ipò kankan dìmú nínú ìbò náà.
PDP ló yege nínú ìbò sípò Sẹ́nétọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti ipò ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin mẹ́sàn-án ìpínlẹ̀ náà lásìkò ìbò tó lọ yìí.
Àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ń fẹ́sùn kàn pé wọn ò jẹ́ kí àwọn ènìyàn jáde dìbò bí wọ́n ṣe fẹ́ ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn fi fìdí rẹmi.
PDP náà sì ti fèsì padà wí pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ pẹ̀lú àláfíà láìsí wàhálà kankan.
Bákan náà ni wọ́n ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn ló ṣẹ lórí esi ìbò ọ̀hún.
Tí ẹ bá gbèrò láti tún lọ sí ilé ẹjọ́, ẹ ma bá àwa náà níbẹ̀
"Èmi ó mọ ibi tí àwọn ọmọ APC ti rí àwọn ọmọ gànfé tí kò jẹ́ kí wọ́n ráyè dìbò nítorí gbogbo ibikíbi ni àwọn ọlọ́pàá wà."
"Kò ṣẹlẹ̀ ní ibikíbi, kódà ní ibùdó ìdìbò mi, àwa àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC jọ wà ni láìsí wàhálà kankan, ètò ìbò máa ń so ènìyàn pọ̀ ni, mi ò gbọ́ nípa ìwà ìpáǹle níbi kankan."
Bamiji tún tẹ̀síwájú pé àwọn tó fìdí rẹmi tún ti ń dúnkokò láti mórí lé ilé ẹjọ́ tó sì ti ń bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú nítorí àwọn ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ló yan gbogbo àwọn tó wà nípò.
Bákan náà ló ní kí ṣe àṣìṣe láti gbé àwọn lọ sí ilé ẹjọ́ lásìkò yìí nítorí gbogbo nǹkan tó bá gbà ni àwọn máa fún-un.












