2023 Nigeria Elections: Sé iléẹjọ́ le wọ́gilé èsì ìbò tó gbé Bola Tinubu wọlé bí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nduka Orjinmo
- Role, BBC News, Abuja
Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ igbiyanju lori nnkan ti ọpọ ni igbagbọ pe ko ni ṣeeṣe lati lọ si ileẹjọ lati yi esi idibo aarẹ to waye lopin ọsẹ to kọja ni Naijiria, to jẹ ọkan lara orilẹede Adulawọ to tobi ju.
Peter Obi ati Atiku Abubakar, awọn to gbe ipo keji ati ipo kẹta ninu eto idibo to fa kiki julọ lati igba ti ijọba ologun ti kọgba wọle lọdun 1999 ti morile ileẹjọ lati tako si esi idibo to kede Bola Tinubu ti ẹtgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bii aarẹ pẹlu ida mẹtadinlogoji ibo.
Nigba ti Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP ṣapejuwe esi idibo gẹgẹ bi ijọba awaarawa lẹyin to ni ida mọkandinlọgbọn ibo, ti Peter Obi ti ẹgbẹ Labour Party, to ni ida mẹdọgbọn ibo ti sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe esi idibo naa dabi pe wọn ja awọn lole ni, to si se ileri pe oun yoo gba ẹtọ oun pada.
Sugbọn ẹri wo ni wọn ni lọwọ ati n jẹ o ṣeṣe fun wọn lati yii esi idibo?
Nigba wo ni awọn ẹgbẹ oṣelu yii le gbe ẹjọ wọn kalẹ?
Gbogbo ọjọ to n tako idibo ni wọn gbọdọ ṣe agbekalẹ rẹ laarin ọjọ mọkanlelogun lẹyin ti wọn kede esi idibo.
Fun idi eyi, Peter Obi ati Atiku Abubakar gbọdọ fu ẹjọ wọn ransẹ si ileẹjọ kotẹmilọrun ati ileẹjọ to n gbọ ọrọ nipa esi idibo niluu Abuja to to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2023.
Nigba i igbesẹ yii yoo ya kiakia pẹlu ẹjọ naa, yoo gba ẹri lọwọ gbogbo agbegbe ti idibo ti waye ninu eto idibo aarẹ to waye ninu oṣu keji.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọjọ mẹlo ni ileẹjọ yoo gbe ọjọ ro?
Esi lati ọdọ ileẹjọ to awuyewuye lori ọrọ idibo yoo jade lẹyin ọjọ ọgọsaan ti wọn gbe ẹjọ naa wọle , ti Obo ati Atiku yoo si ṣe ẹjọ lọọtọtọ, tio esi yoo si jade ni igba ọtọọtọtọ.
Bakan. esi ati idajọ ileẹjọ to n gbọ awuyewuye lori idibo kọ ni yoo jẹ opin, awọn ẹgbẹ oṣelu ni anfani lọ ileẹjọ agbe orilẹede Naijiria, ti gbogbo igbesẹ naa ko si kọja oṣu meji lọ sugbọn idajọ yoo waye laarin oṣu mẹjọ.
Ṣe ẹjọ sise yoo ṣe idiwọ fun bibura fun Tinubu?
Rara!!!
Ko sese ki ileẹjọ to awuyewuye gbe idajọ kalẹ ko to di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2023, to se se pe wọn yoo ti bura fun Tinubu gẹgẹ bii aarẹ
Koda ti ileẹjọ ba yi esi naa pada tabi kede oludije miiran gẹgẹ bi ẹni to wọle, irufẹ idajọ naa o ma pada de ileẹjọ agba fun orilẹede Naijiria .
Ki ni ofin sọ nipa si se afihan esi idibo?Wetin di law tok about transmission of results?
Nigba ti awọn akọroyin bi Peter Obi pe ẹri wo lo ni lọwọ to ni pe oun lo bori eto idibo, Obi kọ lati sọrọ sugbọn Atiku ni ni mago mago wa ninu igbekale ati abajade esi idibo.
Sugbọn ti a ba ni kalọ pẹlu ọrọ ti awọn asoju PDP sọ nibi ti wọn ti kede esi idibo ki awọn ẹgbẹ mejeeji to binu jade, o ṣeṣe pe ẹjọ ti wọn dale lori bi INEC se kuna lati gbe edi ibi lọ sori ayelujare lati ibi ti idibo ti waye.
Wọn buwọlu ofin kan lọdun to kọja lati se atọna fun eto idibo ọdun 2023 to ni "Idibo ati ikede esi ibo ni yoo wa ni ilana ti Ajọ INEC ba fẹ ko jẹ."
Ofin ọhun nilo pe ajọ INEC naa kede ilana fun eto idibo, wọn si se agbekalẹ igbesẹ kọkan lati akọsilẹ ibo nibi ti ibo ti n waye ati awọn ibo ni ẹkun ijọba kọkan."
Ajọ wa kede ilana ti wọn nibi ti wọn ti salaye pe:
- Wọn yoo lori ẹrọ ayarabi asa tabi ki wọn gbe esi idibo lati ibi ti wọn lọ sibi ti wọn kede rẹ
- Lilo ẹrọ BVAS lati gbe esi ibo lọ si EC8A ti yoo wa lọ sori ẹrọ opo ti wọn ti le wo esi lori ayelujara IReV
Lilo ẹrọ BVAS lo jẹ tuntun ti wọn se agbe kalẹ lati jẹ ko yara lati gbe esi idibo lọ si bi ti wọn yoo ti ka, ti ko si ni fi aye silẹ fun magomago, bakan naa ọpọ eeyan ti fi ẹsun kan ajọ INEC pe ko gbe esi ibo naa sori ayelujara, eyi to fa awuyewuye pe wọn yi ibo ni.
INEC ni idi ti awọn ko fi gbe esi naa sori ayelujara lori bi ero se pọ lori ayelujara sugbọn lẹyin ọsẹ kan ti idibo pari, INEC ko ti gbe ida mejila esi ibo sori ayelujara.
Agba agbẹjọro to ba ileeṣẹ BBC sọrọ, Yemi Candide ni pe Ilana INEC ko ki n se ofin ati pe eto idibo ko le ri ija kulẹ nitori ko t;ele ofin.
"Ti ai tẹle ofin ko se akoba esi idibo, ko le esi idibo jẹ. Ti awọn esi kan ni awọn agbegbe kan ko ba ni ariwo ninu, atunse le waye tom ba yẹ."
.

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn ẹri wo lo tun wa?
Lẹyin Mr Obi sọ pe oun ni oun bori ibo, o le pe fun pe ki wọn kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to bori. Ọpọlọpọ ẹsun ati ariwo ni awọn agbegbe bi Rivers, Delta, Imo, Sokoto ati ipinlẹ Eko, nibi ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti fi ẹsun kan osisẹ INEC pe o ledi pupọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn ẹsọ alabo to ṣe madaru si eto idibo lasiko ti wọn fẹ kede ibo.
Awọn oloye to fi esi ti INEC gbe jade lori ayelujara wọn ati i ti awọn oludibo kọ silẹ we arawọn ni ko jọ arawọn rara. Labour Party se agbekalẹ opo kan to fun awọn ọdọ ni anfani lati sọ nipa magomago ti wọn ba kéfin ni agbegbe ti wọn ti n dibo, ki wọn si ma awọn esi ibo ni agbegbe w'ọn sibẹ lati le fi we arawọn ti wọn kede esi ibo.
Awọn esi ibo kan lorilẹede Ayelujara INEC ni wọn gbe fun ipinlẹ miiran ti wọn wọgile awọn kan. Koda awọn eeyan kan fidi rẹ mulẹ pe esi ibo ni agbegbe wọn jọ iti o wa lori ayelujara INEC.
Ti Obi ba kẹfin pe mọdaru wa ninu ikede esi idibo, eyi to ni o mu idinku ba ibo ni awọn agbegbe kan, to si jẹ afikun si ti ẹni to jawe olubori, yoo nilo lati gbe iwe esi ibo to yanranti kalẹ ati ti ori ayelujara ti wọn lati fi ṣe iforukọ silẹ awọn oludibo ni awọn agbegbe naa.
Lati yege ni ileẹjọ, awọn alatako ni lati fi han pe magomago ni ọwọ ninu esi idibo to jade.
Ki ni wọn ni lati fihan?
Gẹgẹ bi ofin idibo ẹ sọ, ẹni to pe ẹjọ gbọdọ fidi rẹ mulẹ pe ai tẹle ofin lo sakoba fun esi ibo ti wọn kede.
BI isẹlẹ magomago tabi rogbodiyan lo da idibo ru yoo ni lati waye tẹlẹ ni gbogbo ibi ti idibo ti waye .
Iyatọ to wa laarin Tinubu ati Abubakar lo sumọ milọnu meji, ti Obi si wa lẹyin wọn ẹgbẹrun lọna ọọdẹgbẹrin ibo.
Sugbọn eto idibo to waye sẹyin maa waye pẹlu isoro bi rogbodiyan, fifipa muni dibo tabi jiji apoti ibo lọjọ ibo, ko ti si oludije kankan to ti fi idi rẹ mulẹ iru isoro bẹ n lẹ se akoba fun esi ibo. de abala kan.
Lọjọ 2003 nigba aarẹ to wa lori ipo bayii, Aarẹ Muhammadu Buhari tako ibo to gbe Olusegun Obasanjo wọle, adajọ ile ẹjọ to ga ju ni awọn lilo ẹlẹri egbẹrun lọna aadọtalenigba lati le tẹsiwaju lori aarẹ ko lo wọle tabi lati fi bori ẹjọ naa
Nigba ti atunse ti wa sofin bayii, ti wọn si nilo irufẹ ẹlẹri to to yẹn mọ, o ṣe afihan iru pejnija ti awọn to n pe ẹjọ la kọja.
Bakan na, eyi ni iwe ofin akọkọ ti wọn se lati fifi ẹrọ ayarabiasa gbe esi ibo, to si ti bẹrẹ sini ni ipenija lati ọjọ ibo, wọn ti gbe awọn esi naa so ri ayelujara INEC,eyim ti yoo irọnu fun awọn olupẹjọ ni anfani si gbogbo ẹri ti wọn nilo.
N jẹ ẹgbẹ alatako le bori ẹjẹ yii?
Sugbọn ko si esi ibo aarẹ to ri ayipada ri, o sẹlẹ ni awọn eto idibo miiran lorilẹede Naijiria .
Ti Obi si jẹ ọkan lara awọn to jẹ anfani rẹ.
O duro fun ọdun mẹta ko to bọ sori ipo gomina lẹyin to jawe olubori eto idibo gomina nipinlẹ Anambra lọdun 2003.
O fi ileẹjọ to n gbo awuyewuye lori idibo ati ileẹjọ kotẹmilọrun pe oun lo gbe ibo to pọju ninu eto idibo, ti wọn si kede gẹgẹ ẹni to bori.




Who is Rabiu Kwankwaso?
Who is Peter Obi of the Labour Party?
Who is Atiku Abubakar?
Who is Bola Tinubu of the APC? 








