A kò pa ẹ̀bí Oluomo Malay tì o! Ohun táa mọ̀ nípa ikú rẹ̀ nìyí - PDP Ondo

Àkọlé fídíò, Oluomo Malay: Ọkọ mi ò kí n ṣe tọ́ọ̀gì o, irọ́ ti pọ̀ nígboro lórí ikú rẹ̀, mo ṣì kéré sí
A kò pa ẹ̀bí Oluomo Malay tì o! Ohun táa mọ̀ nípa ikú rẹ̀ nìyí - PDP Ondo

Ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn yoo gbe igbeṣe to yẹ to lati ri daju pe awọn mọlẹbi Akinlabi Akinfolarin, ti ọpọ mọ si Oluomo Malay, ri idajọ ododo gba lori iku rẹ.

Alukoro ẹgbẹ ọhun nipilẹ Ondo, Kennedy Peretie, lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii ni ẹnikan to wọ aṣọ ọmọ ologun yinbọn pa oloogbe naa lasiko ti wọn n kede esi ibo sipo aṣojuṣofin niluu Idanre.

Peretei sọ pe oloogbe naa kii ṣe janduku rara bii iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri, ati pe igba ti oun ati agbofinro naa n ta ohun sira wọn ni ologun ọhun yibọn lu u.

O ni “Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi naa mọ itumọ ohun ti wọn ṣe... wọn si ti n wa ọna lati yanju ọrọ ọhun ni ẹrọpẹlẹ, amọ niwọn igba to jẹ pe iwa ọdaran ni, o ṣoro lati yanju labẹle.”

Oluomo Malay

Oríṣun àwòrán, Fessy West/BBC

“Aṣọ ologun ni ẹni to yinbọn lu wọ, o le jẹ ẹni ti kii ṣe ologun to kan wọ aṣọ ologun, amọ gbogbo ẹ la maa mọ ninu iwadii.”

Peretie tẹsiwaju pe ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ondo ti kọ iwe si awọn agbofinro fun iwadii, awọn ko si ni kọ mọlẹbi oloogbe naa silẹ lasiko ti wọn padanu ọmọ wọn yii.

O ni “A ti kọ iwe si awọn agbofinro lori ohun to ṣẹlẹ ni Idanre.”

“Mo le sọ fun yin pẹlu aridaju pe awọn ẹbi oloogbe yoo ri idajọ ododo gba lori iku rẹ, a ko si ni fi wọn silẹ lakoko yii.”

Ohun to waye ṣaaju

Wọ́n kàn pa ọkọ mi "Oluomo" t'ògo t'ògo lásìkò ìdìbò ààrẹ l’Ondo níwájú INEC; Ìjọba ẹ gbà wá o!

O ṣe ni laanu wipe ko si bi idibo Naijiria ṣe ni iroyin alafia tabi irọwọrọsẹ to ti kii ni kekere abamọ ninu lawọn apa ibi kọọkan.

Awọn miran ko tilẹ mọ pe idibo aarẹ Naijiria to ṣẹṣẹ waye tilẹ sọ awọn ẹbi kan sinu ibanujẹ ayeraye toripe awọn agba maa n ni ẹni to kan lo mọ.

Ni ti ẹbi Akinlabi Oluomo ni ilu Idanre nipinlẹ Ondo, inu ẹkun ati ibanujẹ ni wọn wa lati ọjọ ti idibo aarẹ ti waye.

Ẹbi Oloogbe

"Ọkọ mi kii ṣe tọọgi o tori o ka iwe"

Iyawo Oloogbe

"Ọkọ mi kii ṣe tọọgi o tori o ka iwe, bẹẹ si ni to ba rii pe wọn n ja nibi kan, a ti de ile".

Nigba ti BBC Yoruba de ile awọn Akinlabi Folarin ti gbogbo eeyan mọ si Oluomo, ipo ibanujẹ gbaa ni gbogbo wọn wa tori o ṣi ni baba ati iya laye, o tun fi iyawo ati ọmọ meji saye lọ.

Akinlabi to jẹ aṣoju fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party padanu ẹmi rẹ lasiko ti wọn n duro de esi idibo ni ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Keji ọdun 2023 ni ọfiisi ajọ INEC to wa ni ipinlẹ Ondo.

Arabinrin Oluwaseyi Akinfolarin ṣalaye pe irọ ni awọn eeyan n sọ ni igboro nipa iku ọkọ oun pe tọọgi ni amọ o ni kii ṣe bẹẹ rara tori ọkọ rere ni ọkọ oun.

Ẹbi Akinlabi

Oríṣun àwòrán, Oluomo Malay/Facebook

Adanu gidi lo jẹ fun mi; Akin o le pa Ewurẹ, wọn kan pa a t'ogo t'ogo ni - Baba, ẹgbọn Oluomo

Baba Akinlabi

Baba Akinlabi, Akinsohun Ige sọ fun BBC Yoruba pe ọmọ oun o gbo oun lẹnu ri.

Bakan naa ni ẹgbọn rẹ obinrin, Arabinrin Comfort Omowunmi ni Akinlabi ko tilẹ le pa adiyẹ ko si ki n ṣe oni wahala eniyan rara.

Ẹgbọn Akinlabi

'A jọ wa nibẹ ni, oju mi ni awọn Sọja yinbọn to si ba Oluomo'

Aburo Akinlabi

Bolusere Akinfolarin to jẹ aburo oloogbe ni wọn jọ lọ si ibi idibo lọjọ naa ti ohun gbogbo si ṣoju rẹ.

O ṣalaye lẹkunrẹrẹ akoko ti wọn lọ si ọfiiisi ajọ eleto idibo ni Idanre lati lọ mojuto kika esi idibo.

"A jọ wa nibẹ ni, gbogbo wa jọ duro niwaju ọfiisi lọjọ naa, a kan dede rii ti mọto awọn Sọja kan n bọ.

Wọn duro, ọkan lara wọn bọọlẹ o si yinbọn sita, ibọn yẹn lo ba Oluomo."

Boluṣere tun ṣalaye pe fun bii iṣẹju diẹ, awọn akẹgbẹ Sọja naa n jiyan wọn si n bii pe kilode to ṣe yinbọn amọ ko to to iṣẹju marun wọn gbera kuro nibẹ kia.

BBC Yoruba kan si agọ ọlọpaa ipinlẹ naa lati bere iha ti wọn kọ ati ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa amọ wọn ni awọn ko fẹ sọrọ si wa.