'Mo bẹ̀rẹ̀ sí ni mu igbó "Heroin" lọ́dún 27, bí gbogbo nǹkan ti mo ní ṣe dàwó lójú ayé mi nìyí'
Fady yàn láti tú àṣírí ara rẹ̀ fún ikọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ BBC, Africa Eye.
"Igba ti ọmọ yii wa ni kekere ni mo ti maa n mu igbo pẹlu iya rẹ, nibayii, oun gaan ati aburo rẹ ti gba igba heroine mimu bayii."
Fady jẹ ko di mimọ pe o wọpọ ki baba maa fi iwa mimu igbo le ọmọ lọwọ ni Seychelles. Bakan naa, o ni pẹlu aduru iyi ati apọnle ti Seychelles ni loju gbogbo agbaye, ilu naa lo ni iṣoro heroin ju lagbaye.

"Heroin ni oogun ara riro mi.”
Mo fẹran ọkọ ati awọn ọmọ mi o amọ mo fẹran heroin ju". Obinrin kan sọ eyi fun BBC.
Fady ṣalaye bi heroin ṣe ti pa ọpọlọpọ ni Seychelles, paapaa ọmọ ọrẹ rẹ Rashid, to jẹ ọmọde.
Ohun to buru nibẹ ni pe ọmọ naa maa n bi iya rẹ pe ko fun oun ni igbo titi ti ti oun ni rara amọ o ni ọmọ naa ni igbo ko lee pa oun amọ heroin ọhun gan lo pada pa a.





