Ìdìbò ààrẹ ti ọdún yìí ló burú jù táà ti rí ní Nàìjíríà, ìdí sì ni pé ... - Alága PDP Ogun

Àkọlé fídíò, 2023 election: Ìdìbò ààrẹ tó wáyé lọ́dún yìí ni èyí tó burú jù táà ti rí ní Nàìjíríà

Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ipinlẹ Ogun, Sikiru Olawale Ogundele ti fesi si gbogbo ariwo to n lọ lode lori eto idibo aarẹ to waye ni Naijiria.

Ọgbẹni Sikiru Olawale Ogundele bu ẹnu atẹ lu bi ajọ INEC ṣe ṣakoso eto idbo naa to si ni ajọ ọhun ti tan awọn ọmọ Naijiria jẹ gidi gan.

O ni: " Ìdìbò ààrẹ tó wáyé lọ́dún yìí ni èyí tó burú jù táà ti rí ní Nàìjíríà."

Bakan naa lo mẹnu ba ibi ti ọrọ airi owo na buru de ni NAijiria, "bo ṣe kan olowo lo kan talaka".

Sikiru ni INEC parọ wọn si ṣe ẹtan fun awọn ọmọ Naijiria amọ wọn ko mu ileri wọn ṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ṣee ṣaaju idibo ti awọn ọmọ Naijria si gbe ọkan le wọn.

Alagag o#selu PDP Ogun

Ẹ̀gbẹ́ 10 ti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú PDP l'Ogun báyìí kódà, àwọn tó ń bínú nínú APC ti wà pẹ̀lú wa àmọ́ ...

Alaga PDP ni Ogun

Ọgbẹni Sikiru tun jẹ ko di mimọ pe ọpọlọpọ ẹgbẹ ni ipinlẹ Ogun lo ti ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu PDP eyi to si ni ko lodi si oṣelu.

"Ko si ọgbọn ti wọn le da ninu idibo to n bọ yii lati lọ ọ laṣọ tabi yi ibo, ko le bọ sii mọ, ko le ṣee ṣe mọ".

Bakan naa lo ni awọn to tun n binu ninu ẹgbẹ APC ti wa ni ibaṣepọ pẹlu awọn.