AbdulRahman AbdulRazaq borí ìbò, wọlé fún sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Kwara

Abdulrahman Abdulrazaq

Oríṣun àwòrán, @RealAARahman

Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, tijawe olubori ninu ibo gomina gomina to waye lọjọ Abamẹta.

Eyii n tumọ si pe gimina ọhun ti wọle fun saa keji.

AbdulRazaq, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC fidi Alhaji Shuaib Yaman Abdullahi, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Hakeem Oladimeji Lawal ti ẹgbẹ oṣelu SDP ati Ọjọgbọn Shuaib Oba Abdulraheem, ti ẹgbẹ oṣelu NNPP janlẹ.

Lara awọn ijọba ibilẹ ti AbdulRazaq ti bori ni Asa, Ekiti, Offa, Oyun, Irepodun, Isin, Oke-Ero, Ilorin South, Ilorin East, Patigi, Ifelodun atawọn mii.

Bi apapọ esi ibo ti APC, PDP, SDP, LP ati NNPP gba ninu ibo gomina ni Kwara ree, eyi to gbe gomina AbdulRahman AbdulRazaq wọle fun saa keji.

APC 273,424

PDP 155, 490

SDP 18, 922

LP 1647

NNPP 4398

Total votes 470, 771

Rejected 10, 274

Àwọn nǹkan tó yẹ kóo mọ̀ nípa AbdulRazaq, Lawal, Abdullahi, àwọn olùdíje sípò gómìnà Kwara nìyí

Awon oludije sipo gomina Kwara legbe oselu SDP, APC, PDP

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Bí àjọ INEC ṣe ti sún ọjọ́ ètò ìdìbò gómìnà àti ti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ kúrò ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkànlá oṣù Kẹta sí ọjọ́ Kejìdínlógún Oṣù kan náà, èrò àwọn Nàìjíríà ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Àmọ́ṣá, gbogbo ètò ń lọ láàrìn àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, ìpolongo ìdìbò náà sì ń lọ káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n káàkiri Nàìjíríà.

Ìpínlẹ̀ Kwara jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpínlẹ̀ níbi tí àwọn aráàlú yóò tún ti ní àǹfàní láti yan ẹni tí yóò máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ wọn fún ọdún mẹ́rin mìíràn.

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, BBC News Yorùbá ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn olùdíje mẹ́ta nínú àwọn tó ń wá ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Yàtọ̀ sí gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tó ń ṣe ìjọba ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ tó tún ń wá sáà mìíràn lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, a tún ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP àti SDP.

Èyí ni láti mú àwọn nǹkan tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa àwọn olùdíje náà wá fún-un yín.

Abdulrahman Abdulrasak (APC)

Gomina Abdulrahman Abdulrasaq

Oríṣun àwòrán, Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù Kejì ọdún 1960 ni wọ́n bí AbdulRahman AbdulRazaq sínú ẹbí AGF AbdulRazaq ti ìlú Ilorin ní ìjọba ìbílẹ̀ Ilorin West, ìpínlẹ̀ Kwara.

Bàbá rẹ̀ ni agbẹjọ́rò àkọ́kọ́ ni ẹkùn árèwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Capital School, Kaduna láàárín ọdún 1966 sí 1968, Bishop Smith Memorial School, Ilorin láàárín ọdún 1970 sí 1971.

Lẹ́yìn náà ló tún padà sí ìpínlẹ̀ Kaduna láti lọ tẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Government College Kaduna níbi tó ti gbà ìwé ẹ̀rí girama ìyẹn West Africa Senior School Certificate Examination (WASSCE) lọ́dún 1976.

Ní ọdún 1999 tí Nàìjíríà padà sí ètò ìṣèjọba alágbádá ni AbdulRahman AbdulRazaq darapọ̀ mọ́ òṣèlú.

Ó dupò gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Congress for Progressives Change (CPC) àmọ́ tó fìdí rẹmi.

Bákan náà ló ti fìgbà kan díje sípò Sẹ́nétọ̀ láti ṣojú ààrin gbùngbùn ìpínlẹ̀ Kwara lọ́dún 2011 àti 2015 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí kò sì rí ọwọ́ mú.

Ní ọdún 2019 ni AbdulRahman AbdulRazaq tún pakítí mọ́lẹ̀ láti díje dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó sì gbégbá orókè.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà ṣe ń pòùngbẹ ìjọba tuntun lẹ́yìn tí ìdílé àwọn Saraki ti ṣe àkóso ètò òṣèlú ̀ Kwara láti ọdún 1999.

Nígbà yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú tí kò gba ti Saraki kó ara wọn jọ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tí wọ́n sì panupọ̀ pé "Ó tó gẹ́", àkọmọ̀nà tí wọ́n fi le Saraki nìyí nígbà náà.

Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ló tún ń díje fún sáà kejì lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC nínú ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 2023.

Olufolake Davies AbdulRazaq ni ìyàwó gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí Ọlọ́run sì fi ọmọkùnrin mẹ́ta ta ìdílé wọn lọ́rẹ.

Shuaib Yaman Abdullahi (PDP)

Shuaib Yaman Abdullah

Oríṣun àwòrán, Facebook

Shuaib Yaman Abdullahi ni olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP níbi ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ìran Nupe ní ìlú Ankurifun Shonga, ìjọba ìbílẹ̀ Edu, ẹkùn àríwá ìpínlẹ̀ Kwara ni Yaman Abdullah ti wá.

Inú ìdílé Alhaji Abdullah tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Alhaji Bacita ni wọ́n bí Yaman sí.

Ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 1957 ni wọ́n bi sáyé tó sì ti pé ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin báyìí.

Yaman lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Native Authority Primary School, Shonga láàárín ọdún 1964 sí ọdún 1969.

Lẹ́yìn náà ló tẹ̀síwájú lọ sí ilé Government Secondary School, Omu-Aran níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ girama láàárín ọdún 1970 sí 1974.

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Ahmadu Bello University, Zaria ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ okoòwò ṣíṣe ìyẹn Business Administration lọ́dún 1979.

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì akọ̀wé ẹ̀ka tó ń mójútó ètò ọrọ̀ ajé ní Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè lọ́dún 1980 kí wọ́n tó gbé lọ sí Iléeṣẹ́ aládani kan.

Ṣáájú ìdìbò ọdún 2019, Yaman jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tí òun náà sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó pariwo pé ó tó gẹ́ lọ́dún náà lọ́hùn-ún.

Ó díje ìbò abẹ́nú APC Kwara àmọ́ tó pàdánù tíkẹ́ẹ̀tì sọ́wọ́ gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq.

Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq wọlé ìbò 2019 tán ni Yaman kúrò nínú ẹgbẹ́ náà tó sì tà kọ́sọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP níbi tó ti jẹ́ olùdíje wọn báyìí.

Hakeem Oladimeji Lawal (SDP)

Hakeem Lawal

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ní oṣù kẹwàá ọdún 1974 ni wọ́n bi Hakeem Oladimeji Lawal tó ń dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP ní ìpínlẹ̀ Eko.

Òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Kwara, Mohammed Alabi Lawal.

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Chapel Primary School, Ilorin tó sì rí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Barewa College, Zaria nítorí bó ṣe já fáfá lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Nígbà tó parí ẹ̀kọ́ girama ló ta kọ́sọ́ sí orílẹ̀ èdè UK níbẹ̀ ló sì ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì, University tí Portsmouth níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò ọrọ̀ ajé.

Bákan náà ló tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga University tí Surrey fún ìmọ̀ onípò kejì (Masters) nínú ìmọ̀ ìsúná àgbáyé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ni Hakeem Lawal bá ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè United Kingdom kó tó dá ilé iṣẹ́ tí ara rẹ̀ sílẹ̀.

Ní ọdún 2014 ló kọ́kọ́ gbèrò láti ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣùgbọ́n tó pàdánù tíkẹ́ẹ̀tì, bákan náà ló tún gbìyànjú lọ́dún 2018 lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC tó sì tún fìdí rẹmi bákan náà.

Òun náà wà lára àwọn tó pawọ́pọ̀ lọ́dún 2019 lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC láti fi ó to gẹ́ lélẹ̀ àmọ́ tí òun náà fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáwé olúborí tán.

Ẹgbẹ́ òṣèlú SDP ni Hakeem Lawal ti ń díje báyìí tó sì ní nǹkan mẹ́ta ni òun máa gbájúmọ́ tí òun bá filè wọlé gómìnà Kwara.

Nígbà tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, ó ní nítorí kò sí ìyàtọ̀ sí àwọn ìpèníjà tó ń bá ìpínlẹ̀ Kwara fínra láti ìgbà tí ìjọba tó wà lóde lábẹ́ ìdarí gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ni òun fi fẹgbẹ́ APC sílẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé àwọn nǹkan tí òun máa gbájúmọ́ ni àwọn ohun amáyédẹrùn, ìpèsè iṣẹ́ àti gbígbé agbára wọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kwara.