'Tó bá wu INEC kó sún ìdìbò nígbà igba, a mọ ẹni tí a máa dìbò fún'

Awọn ọmọ Naijiria kan ti bu ẹnu atẹ lu bi ajọ eleto idibo, INEC, ṣe sun eto idibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ siwaju.
Lara awọn eeyan naa ni Dele Farotimi, to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, onwoye ọhun to n lọ lọrọ eto oṣelu ati awọn agbẹjọro.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Farotimi sọ pe INEC ko ṣee fọkan tan nitori awọn ohun to ti ṣe sẹyin.
O ni “Wọn kii ṣe ẹni ti a le fọkan tan, eleyii ti wọn tun ṣe yii dabi igba ti eeyan ba kan sọ pe ara ile ẹ tun ti de ni.”
“Oriṣiriṣi ọna ni a le tumọ bi wọ sun idibo yii siwaju si.”
“Fun awa ti a n gbe ilu Eko ti a si n woye ohun to n lọ, a le juwe rẹ gẹgẹ bii igba ti wọn ba fun Sanwo-Olu laaye diẹ si ko ma baa fidirẹmi.”
“Gẹgẹ bi awa ṣe ri, wọn n wo boya ti wọn ba fun gomina wọn to ti fẹ fidirẹmi yii laye si, boya yoo gbiyanju lati bori.”
Farotimi sọ siwaju si pe INEC ṣe ọpọ ileri ṣaaju idibo Aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji, amọ nnkan mii lawọn araalu ba nibudo idibo.
O ṣalaye pe o nira fun awọn araalu lati gba INEC gbọ pe wọn sun eto idibo naa siwaju nitori wọn ni erongba rere.
Farotimi ni “ Ọrọ INEC da bi igba ti wọn ba pe eeyan ni ole, to tun n lọ gbe ọmọ ewure jo.”
“Awa araalu ti mọ ibi ti a n lọ, ẹru ibi ti a n lọ lo n dẹru ba INEC atawọn ti wọn ko fẹ lọ sibi ti a n lọ.”
“Bo wu wọn ki wọn fun wọn ni oṣu kan si , bi ẹ ba ju ọbẹ soke nigba igba, ibi pẹlẹbẹ naa lo maa fi lelẹ.”
Agbẹjọro naa pari ọrọ rẹ pe kii ṣe ifẹ araalu ni INEC ni lọkan ti wọn fi sun eto idibo naa siwaju.
Lẹyin naa lo ni ki awọn aralọ lọ wa kaadi idibo alalopẹ wọn ki wọn si mura lati di ibo wọn fun ẹni ti ọkan wọn n fẹ lai ṣe oju aanu kankan.
Wo iye ìgbà tí INEC ti sún ètò ìdìbò síwájú ní Naijiria

Alẹ Ọjọru ni iroyin gbode pe ajọ eleto idibo, INEC ti sun eto idibo gomina atawọn aṣofin ipinlẹ siwaju kaakiri Naijiria.
Iroyin yii lo ba ọpọ ọmọ Naijiria lojiji, bẹẹ lawọn mii sọ pe awọn ti n woye pe o ṣeeṣe ki wọn sun eto idibo naa siwaju.
Ero awọn araalu ṣọtọtọ lori igbesẹ INEC lati sun eto idibo naa, bi awọn kan ṣe n sọ pe ọgbọn alumọkọrọyi lati ṣe magomago lasiko eto idibo ọhun ni INEC n da, lawọn mii n sọ pe yoo fun INEC lanfaani lati tunbọ mura daadaa.
Ẹwẹ, kii ṣe igba akọkọ ree ti INEC yoo sun eto idibo siwaju fun idi kan tabi omiran.
BBC ṣe akojọpọ igba mẹrin ọtọtọ ti INEC ti sun eto idibo siwaju ni Naijiria
Idibo gomina ọdun 2023

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii lo yẹ ki eto idibo gomina ati ile aṣofin ipinlẹ waye kaakiri Naijiria, iyen lẹyin ti eto idibo Aarẹ ti kọkọ waye ṣaaju.
Amọ nigba ti eto idibo naa yoo fi ku nnkan bi ọjọ mẹta pere, INEC sun eto idibo naa siwaju.
Ajọ INEC ṣalaye pe awọn gbe igbesẹ yii nitori ki awọn le tete bẹrẹ iṣẹ lori atunṣe awọn ẹrọ Bimodal Voter Accreditation System (BVAS) ti wọn lo lasiko idibo aarẹ ati ti ile igbimọ aṣofin apapọ, tori ki wọn baa le ri awọn ẹrọ BVAS naa lo lasiko idibo ti ipinlẹ
Gẹgẹ bii ohun ti INEC, ọjọ kejidinlogun, oṣun Kẹta kan naa ni eto idibo naa yoo pada waye.
Atundi ibo ọdun 2020
Atundi ibo ọdun 2020 lo yẹ ko waye lawọn ipinlẹ mọkanla amọ wọn sun idibo naa siwaju.
Awọn ipinlẹ naa ni Eko, Bayelsa, Borno, Cross River, Imo, Kogi, Plateau, Enugu, Bauchi, Kastina ati Zamfara.
Alaga INEC nigba naa, Attahiru Jega lo fi ọrọ naa lede nibi ipade awọn akọroyin niluu Abuja.
INEC ni igbesẹ ọhun ko ṣẹyin iwọde EndSARS to n mi gbogbo Naijiria titi lasiko naa.
Gẹgẹ bi ohun ti Jega sọ, eto abo awọn araalu ati oṣiṣẹ INEC ṣe pataki si awọn, lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ naa.
Eto dibo gbogbogbo ọdun 2019
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti gbaradi lati dibo lọjọ kẹrindinlogin, oṣu Keji, ọdun 2019, amọ niggba ti wọn yoo fi ji lori ibusun wọn, iroyin to gbode ni pe INEC ti sun eto idibo naa siwaju.
Nnkan bii aago meji abọ oru ọjọ to yẹ ki idibo naa waye ni INEC sun siwaju.
Alaga ajọ INEC Mahmood Yakubu lo fi ikede naa sita ni olu ọọfisi INEC to wa nilu Abuja.
Ọjọ tuntun ti wọn sun eto idibo naa si ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, nigba ti eto idibo gomina waye lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta, ọdun 2019.

Eto idibo gbogbogo ọdun 2015
Ọjọ kẹrinla ati ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2015 lo yẹ ki eto idibo gbogbogbp waye lọdun 2015 amọ INEC sun siwaju.
Alaga ajọ INEC lọdun naa lọhun, Attahiru Jega sọ fun awọn akọroyin niluu Abuja pe awọn sun idibo ọhun lẹyin ti awọn agbofinro atawọn ologun sọ pe awọn ko ni le ṣiṣẹ lawọn ọjọ ti INEC mu fun idibo naa ṣaaju.
Alaga Jega ni awọn ẹṣọ alaabo ni igbesẹ awọn ko ṣẹyin bi awọn ṣe fẹ tẹkọ leti lọ si ipinlẹ Bornu lati lọ koju ikọ Boko Haram.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
INEC sún ìdìbò Gómìnà tó yẹ kó wáyé lọ́sẹ̀ yìí síwájú di March 18!

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria (INEC) ti sun eto idibo gomina ipinlẹ ati ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ eyi ti wọn ti kọkọ ni yoo waye ni Ọjọ Kọkanla Oṣu Kẹta siwaju di Ọsẹ kan sii iyẹ Ọjọ Kejidinlogun Oṣu Kẹta, Ọdun 2023.
Ajọ INEC ṣalaye pe awọn gbe igbesẹ yii nitori ki awọn le tete bẹrẹ iṣẹ lori atunṣe awọn ẹrọ Bimodal Voter Accreditation System (BVAS) ti wọn lo lasiko idibo aarẹ ati ti ile igbimọ aṣofin apapọ, tori ki wọn baa le ri awọn ẹrọ BVAS naa lo lasiko idibo ti ipinlẹ.
Ki ni pataki BVAS?

BVAS jẹ ẹrọ ti wọn n lo lati ṣe eto idibo bayii lorilẹede Naijira eyi to maa n ṣe ayẹwo orukọ oludibo fun iforukọsilẹ lati mọ boya lootọ ni wọn yoo le dibo.
Ẹrọ yii maa sọ pe “o lẹtọ lati dibo” nigba ti oludibo ba tẹ ika rẹ soju ẹrọ naa tabi ki wọn na oju wọn siwaju rẹ bi ika ko ba ṣiṣẹ.
BVAS yii tun ni kamẹra to lee yaworan esi idibo ibudo idibo ọhun ti yoo si tun gbe e sori ayelujara ti ajọ INEC fi n wo esi idibo iyẹn INEC Result Viewing (IReV) fun anfani ki awọn araalu naa le ni ẹtọ lati wo esi idibo lẹsẹsẹkẹ bi idibo ba ṣe n pari ni ibudo idibo kọọkan.
Ẹwẹ, sisun ti wọn sun eto idibo ti ipinlẹ siwaju yii n waye lẹyin ti ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ nipa eto idibo aarẹ (Presidential Election Petition Court) to wa ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun ni Abuja fun ajọ eleto idibo ni aṣẹ lati le ṣe atunṣe ẹrọ BVAS ti wọn lo fun idibo aarẹ eyi ti awọn ọmọ Naijiria kọminu lori bi ko ṣe ṣiṣẹ daadaa lasiko naa ti ajọ INEC naa si mọ.
Ababọ ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ile ẹjọ wa fohun ṣọkan lati ẹnu igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta sọrọ pe bi wọn ba file da ajọ INEC duro ki wọn ma ṣe atunṣe BVAS, yoo ṣe ipalara fun idibo ti gomina ati ile aṣofin ipinlẹ to m bọ.
Eyi lo mu ki ile ẹjọ da aba ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludije wọn, Peter Obi da tako igbesẹ ajọ INEC lati tun gbogbo ẹrọ BVAS ṣe.
Gẹgẹ bi ile ẹjọ ṣe sọ ọ, bi wọn ba gba aba naa ti Obi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ da wọle, yoo di pe “wọn n so okun mọ INEC lọwọ ni lati ma le ṣiṣẹ wọn”.
Bakan naa, ile ẹjọ ni pe ninu iwe kan ti INEC ti kọ gẹgẹ bi ẹri si ile ẹjọ fi aridaju han pe ko si eera kankan ti yoo rin gbogbo akọsilẹ nipa awọn oludibo to ti baba wa lori ẹrọ BVAS ọhun ko si si ohunkohun ti yoo sọnu nitoripe awọn yoo ko wọn pamọ, o si ṣee gbe jade pada ni irọrun latori ayelujara ikeji ti wọn lo bii ọna abayọ mii fun kiko nnkan pamọ.
Wakati diẹ lẹyin eyi ni ajọ INEC kede pe eto idibo gomina ati ti ile aṣofin ipinlẹ ti di sisun siwaju.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
















