Tí ẹ bá dìbò fún mi, n kò ní gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Oyo - Teslim Folarin

Aworan oludije sipo gomina nipinlẹ OYO, Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Teslim Folarin ti ni iroyin ofege ni iroyin to n ja kiri pe oun ni ero lati gba isẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ijọba ti isejọba gomina Seyi Makinde ati gomina tẹlẹ Abiola Ajimobi gba si ẹnu isẹ kete ti oun ba ti di gomina ipinlẹ Oyo.

O sọ eleyi nigba to n ba awọn osisẹ ijọba sọrọ niluu Ibadan lọjọ Aje, Folarin ni ko si ohun to jọ mọ bẹẹ rara nitori oun ko ri idi kan pato ti oun yoo fi fẹ gbe irufẹ igbesẹ naa.

"Osisẹ ijọba ni mi tẹlẹ lorilẹede Amẹrika fun ogun ọdun, ki n to bẹrẹ oṣelu sise lorilẹede Naijiria.

"Igbakeji mi, Taiwo Okunlola, naa jẹ osisẹ ijọba fun ogun ọdun, Tisa fun ọdun mẹjọ ati ọdun mẹrinla gẹgẹ olukọ ni fasiti.

"Awa mejeeji ko le ja awọn osisẹ kulẹ nipinlẹ Oyo, ko si mimi kankan to le mi awọn ati isẹ wọn."

Folarin ni oun fi da gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo ati osisẹ loju pe awọn yoo pese igbe aye to rọrun fun igbaladun wọn.

"A o rii pe a san owo awọn osisẹ lasiko to yẹ, ti ẹ ba ṣe fẹ ẹ ni a maa ba yin fẹ ẹ gẹgẹ bi aṣoju yin.

O ni: "Igbega lẹnu isẹ yoo maa wa loorekoore fun awọn osisẹ, awọn osisẹ-fẹyinti naa ko ni gbẹyin, gbogbo ohun to tọ si wọn ni wọn yoo ri gba lọwọ ijọba wa."