Tí mo bá wọlé bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, ẹ ò lè gbóòrùn ìṣòro ààbò rárá - Harrison ẹgbẹ́ oṣèlú AAC Ogun
Ọmọba Harrison Adeyemi ni oludije fun ipo gomina labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu African Alliance Congress to si wa lara awọn to fẹ ba gomina Dapo Abiodun figagbagba ninu eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ Abamẹta to n bọ yii.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba, Harrison ṣe atupalẹ idi to fi yẹ ki awọn ara ipinlẹ Ogun dibo fun un gẹgẹ bi gomina wọn tuntun.


"Tí mo bá wọlé bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, ẹ ò lè gbóòrùn ìṣòro ààbò rárá".
Harrison tun ṣalaye ohun toju awọn oloṣelu maa n ri bi wọn ba n gbe ipolongo ibo kaakiri agbegbe wọn.
"A o tii yan adari to peju nipinlẹ Ogun. Wọn n ṣe ofin, amọ wọn ko lo o".
Ọmọba Adeyemi Harrison sọ idi to fi yẹ ki awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ronu daadaa ki wọn si dibo fun oun.
O tun mẹnu ba bi awọn olori ilu, olori ẹsin ṣe maa n gboju le ki oloṣelu mu owo wa fun wọn ki wọn to sọ fun awọn eeyan wọn pe ki wọn dibo fun un.












