Kó sí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party l'Eko - Jandor, PDP

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko ti ni irọ nipe awọn olori ẹgbẹ oṣelu naa ati ti Labour Party ti fowọsowọpọ lati koju ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ Satide to n bọ.
Hakeem Amode, akọwe agba ẹgbẹ, ninu atẹjade to jade lọjọ Aje ni iroyin ofege iroyin to n ja kiri pe oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdulazeez 'Jandor' Adediran ti juwọ lẹ kuro ninu idije eto idibo gomina.
O ni o se pataki lati tete wogile ero oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebo Rhodes Vivour pe oun ti se ipade pẹlu awọn olori to wa ni ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko.
Vivour lo ṣalaye pe awọn ti bẹrẹ ipade pẹlu awọn olori ẹgbẹ oṣelu PDP, ti wọn yoo si jọ ṣisẹ pọ lati gba ipinlẹ Eko lọwọ oko ẹru.
O ni "awọn eeyan to wa lẹyin ero yii ko gbe erongba le ori owo, a n dibo fun igbagbọ ati ireti pe a yoo ni Eko tuntun, ti wọn yoo si jade ju ti tẹlẹ lọ."
Sugbọn Amode ni ọrọ naa tabuku si ẹgbẹ oṣelu PDP nitori ko si ẹni to lee naka si ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to ni ẹgbẹ oṣelu PDP.
"Ẹnikẹni ti Gbadebo Rhodes Vivour ba sọrọ, n sọrọ fun ara wọn ni nitori ẹgbẹ oṣelu PDP ko mọ nipa ibaṣepọ kankan ati pe Jandor ko ṣetan lati juwọlẹ fun ẹnikẹni.
"A n fi akoko yii sọ fun awọn alatilẹyin wa pe ati gbogbo awọn eeyan nipinlẹ Eko pe gbogbo igbinyanju ẹgbẹ oṣelu PDP ni lati gba awọn eeyan kuro lọwọ oko ẹru ẹgbẹ oṣelu APC."
Ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Labour Party léwu púpọ̀ - Jandor

Oríṣun àwòrán, Instagram
Bakan ni oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdulazeez 'Jandor' Adediran ti ni ibaṣepọ kankan ko le waye laarin oun ati akẹgbẹ rẹ lati ninu ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebo Rhodes Vivour.
Jandor, nigba to n sọrọ lori ẹrọ mohunmaworan kan ṣalaye ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ Labour Party dabi pe ki eeyan joko le ori ado oloro ni, ti o si le fa ọpọlọpọ awuyewuye lẹyin idibo.
O ni;
"Ẹgbẹ oṣelu PDP joko lati yanayana ibaṣepọ yii, a dẹ rii pe oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Labour Party ṣi ni ẹjọ to n jẹ lọwọ lori iyansipo rẹ ni ilẹẹjo to ga ju lorilẹede Naijiria.
"A dẹ tun rii pe o tun ni isoro kan pẹlu iwe ofin to n ri si eto idibo to ni ti ẹnikẹni ba kuro lati inu ẹgbẹ oṣelu kan si omiran, o ni lati wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa fun oṣu kan, ti ẹgbẹ oṣelu rẹ si gbọdọ ti forukọ silẹ ṣaaju eto idibo abẹlẹ.
"Pẹlu gbogbo eleyi, a rii pe igbesẹ naa yoo fa ọpọlọpọ awuyewuye lẹyin eto idibo. A fẹ fowọsowọpọ pẹlu wọn ṣugbọn a gbọdọ gbe ohun ti yoo fun wa ni anfani lati bori siwaju."















