Ta ní Bola Tinubu, ẹni ọdún 70 tí Nàìjíríà dìbò yàn bí ààrẹ wọn?
Pẹlu bi ariwo ṣe pọ to lọwọlọwọ latọdọ awọn oludije ẹgbẹ alatako yala fun atunyẹwo esi tabi ki wọn wọn wọ ẹgbẹ to wa lori oye lọ ile ẹjọ latari esi idibo ti ajọ INEC gbe jade eyi ti wọn fẹsun kan pe irọ nla ni.
Bo tilẹ jẹ pe igbesẹ lilọ ile ẹjọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour Party gun le lori, ajọ eleto idibo INEC ti wo esi idibo ti wọ́n tẹwọ gba wọn si ti kede Bola Tinubu gẹgẹ bi ajaweolubori, koda o ti gba iwe ẹri mo yege. .

"Wọn ti dibo yan mi bi aarẹ orilẹede Naijiria, iṣẹ nla ni gbe le mi lọwọ yii, mo si n fi akoko yii sọ fun yin pe mo tẹwọ gba iṣẹ naa."
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti wọn mọ si Jagaban ni Naijiria figagbaga pẹlu awn eekan oloṣelu meji mii ti awọn araalu tun fẹran, igbakeji aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Gomina tẹlẹri Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ilumọọka ni Tinubu lagbo oṣelu Naijiria ati kaakiri agbaye.
Baba isalẹ nla tun ni pẹlu to maa n ran awọn oloṣelu lọwọ lati de ipo ti wọn ba yan laayo.
Tinubu ti wa ninu oṣelu lati ọdun 1992.












