Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ iná "Akere Spare parts market", Sanwo-Olu, Rhodes-Vivour lọ báwọn èèyàn kẹ́dùn

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ ina to sọsẹ ni ọja Akere ni agbegbe Apapa nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin fi ransẹ si awọn akọroyin, o ni isẹlẹ naa lo waye ni dede ago mẹta oru, ti baba, ẹni ọdun marundinlaadọrun kan si tun padanu ẹmi rẹ.
Bakan naa ni awọn ontaja ninu ọja naa ti kọminu lori ọpọ dukia ti wọn padanu. Iroyin kan to n ja kiri pe awọn agbegbọn kan lo wa si ọja naa ni dede ago mejila abọ oru, ti wọn si dana sun ọja, tun ṣekupa ọkunrin to n sọ ọja naa amọ BBC ko le fidi rẹ mulẹ.
Ẹwẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu sọ pe iṣẹlẹ yii ko ni nnkan ṣe pẹlu erongba oṣelu awọn oloṣelu.
Ajọ to n ri si isẹlẹ ina ati iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ni apa ibọn wa lara oloogbe naa, eyi to fihan pe awọn agbebọn naa mọọmọ sọ ina si ọja ni.
Hundeyin ni Kọmisọna fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinkẹ Eko, Idowu Owohunwa ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko lati fi ọkan wọn balẹ nitori ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n risi ọrọ ọdaran ti bẹrẹ iwadi lori nnkan to fa isẹlẹ naa.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo kede esi iwadi ni aipẹ.
Sanwo-Olu pasẹ pe ki iwadi bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ
Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo- Olu ti pasẹ pe ki awọn ẹsọ alabi bẹrẹ iwadi lori ohun to fa bi ina ọhun ṣe ṣẹyọ ninu Ọja Akere ni agbegbe Apapa nipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade ti Kọmisọna fun ọrọ iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso fi lede, pe pẹlu ibanujẹ ọkan ni gomina fi ba awọn ontaja kẹdun lori kudia wọn ti wọn padanu.
Gomina Sanwo-Olu ti ṣe abẹwọ si ọja naa, to si fi ọkan awọn ara Ọja naa balẹ pe ijọba yoo wa nnkan ṣe lori rẹ.
Gomina rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko lati kọ eti ikun si gbọyii sọyii pe isẹlẹ ina naa ni nnkan se pẹlu ọrọ oṣelu.
Gbadebo Rhodes-Vivour gbe Milọnu mẹẹdogun kalẹ fun awọn ontaja Akere
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Eko, Gbadebo Rhodes Vivour ti pẹlu gomina Babajide Sanwo-Olu lati ba awọn eeyan ninu ọja Akere kedun, to si gbe owo to to milọnu mẹẹdogun naira kalẹ fun awọn ontaja.
Rhodes Vivour ni isẹlẹ naa ba ohun lọkan jẹ pupọ ati bi ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye ṣe ba isẹlẹ naa lọ.
Ta ló dáná sun ọjà "Akere Spare parts market" l'Eko, tó tún yìnbọn pa bàbá ọdẹ ọjà náà?
Ni owurọ Ọjọru lawọn ontaja lọja ẹya ara ọkọ, Akere Spare parts market to wa lagbegbe Olodi-Apapa ni Ajegunlẹ nilu Eko ji ba ajalu ijamba ina to suyọ ninu ọjọ naa eleyi to ba awọn ọja ti owo rẹ le ni ẹgbẹlẹgbẹ naira.
Baba agba ẹni ọdun marundinlaadọrin kan, to jẹ baba ọdẹ ọja naa pẹlu ku sinu ajalu ina naa.
Gẹgẹ bi ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Margaret Adeṣẹyẹ ṣe ṣalaye pe nnkan bii agogo mẹta kọja iṣẹju mejidinlọgbọn loru Ọjọru ni ina naa bẹrẹ.
O ni nigbati awọn oṣiṣẹ panapana de ọja naa ni wọn rii pe ọpọlọpọ awọn ọja ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ lo ti gbina eleyi to ni o mu ki awọn oṣiṣẹ panapana lati ẹka Sari-Iganmu ati Ilupeju darapọ mọ wọn.
Ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko naa tun ṣalaye pe ilakaka awọn oṣiṣẹ panapana naa ni ko jẹ ki ina ọhun ran de ile epo kan atawọn ibugbe to wa nitosi ọja naa.
O ni ọgbẹ ọta ibọn wa lara ọkunrin ti wọn ba oku rẹ ninu ọja naa ati pe ijamba ina naa mu ifura dani eleyi to nilo iwadii.
Ahesọ ọrọ lori ohun to fa ina naa?

Oríṣun àwòrán, lagos fire service
Ọpọlọpọ gbọyisọyi lo ti n waye lori ohun to ṣokunfa ajalu ina yii.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn ẹya kan ni wọn wa nidi rẹ lawọn miran n sọ pe ọrọ naa lọwọ oṣelu ninu
Ijọba ipinlẹ Eko ni ko sẹni to mọọmọ dana sun ọja yii,
Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Eko, Gbenga Ọmọtọṣọ sọ pe ko si ẹnikẹni to mọọmọ dana sun ọja yii gẹgẹ bi awọn ahesọ ọrọ kan ṣe n lọ kaakiri lori ẹrọ ayelujara.
“Iroyin to n tẹ wa lọwọ n sọ pe, nibudo ti wọn n ko epo si ni ọja naa ni ina yii ti bẹrẹ.
“Ṣugbọn iwadi ti bẹrẹ lati mọ ohun gan to ṣẹlẹ ni pato.”
Nigba ti wọn bii lere pe ohun ti awọn kan n sọ ni pe awọn eeyan kan lo kọlu ọja naa loru ti wọn si yinbọn pa ọdẹ to n ṣọ ọja naa, kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ Eko ni oun ko tii gbọ ẹkunrẹrẹ iroyin lori eyi.
“Were pọnbele ni ẹnikẹni to ba lọ n dana sun okoowo olokoowo.”
Iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ina to jo ọja Akere – kọmiṣọna Ọlọpaa Eko

Oríṣun àwòrán, lagos fires service
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti rọ awọn eeyan lati ṣe pẹlẹpẹlẹ ki wọn maa si da omi alaafia laamu nitori iṣẹlẹ ajalu ina naa.
Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko fi sita sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ajalu ina naa .
Kọmiṣọna ọlọpaa, Idowu Owohunwa sọ pe wọn ti gbe iwadi naa fun ẹka ọtẹlẹmuyẹ SCID lati ṣi aṣọ loju awọn ohun to yii ka.
Bakan naa lo ke si awọn eeyan lati yẹra fun pipa iṣẹlẹ naa laro ẹlẹyamẹya abi ẹlẹsinjẹsin.












