Wo àwọn alágbára obìnrin tó ń dupò Gómìnà làwọn ìpínlẹ̀ lórílẹ̀èdè Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọ lo gbagbọ pe ohun ti ọkunrin n ṣe, obinrin le se ju bẹẹ lọ ṣugbọn njẹ awujọ wa fun awọn obinrin ni anfani lati kopa ninu isejọba tabi kopa ninu igbesẹ to jẹ mọ ilọsiwaju awujọ wa.
Lati se ayẹyẹ ayajọ obinrin lagbaye, paapa lorilẹede Naijiria, Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe akọjọpọ ọrukọ awọn obinrin ti wọn yoo kopa ninu eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ Satide to n bọ yii.
Ọpọ awọn obinrin lo ti fi ẹhonu wọn han lati di gomina nipinlẹ wọn ṣugbọn awọn perete lo gba asia ẹgbẹ oṣelu wọn lati kopa fun ipo gomina lawọn ipinlẹ naa.
Dahiru Ahmed Aishatu - APC, Adamawa

Oríṣun àwòrán, Others
Dahiru Ahmed Aishatu, ni ọpọ mọ si Binani, ẹni to jẹ Sẹnẹtọ to n ṣoju aaringbungbun Adamawa.
Aishatu ni oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Pẹlu iriri Aishatu ninu oṣelu, igbagbọ wa pe o kaju iwọn lati lewaju ijọba ipinlẹ Adamawa, ti yoo si fi idi awọn ọkunrin ti wọn jọ dupo janlẹ.
Iwadii fihan pe o ti gbegba ibo lati du ipo gomina ri ti awọn kan si ni o fakọyọ daadaa amọ ko si aridaju bẹẹ si ni ko pada de ipo naa.
Chenge Roseline Ada - ADP, Benue State

Oríṣun àwòrán, Others
Chenge Roseline Ada, ti kọkọ jade dupo gomina lọdun 2007 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ati lọdun 2015 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC sugbọn o ri ija kunlẹ. Ni bayi Ada ti jade lati dupo laarin awọn gende ọkunrin labẹ asia ẹgbẹ ADP nipinlẹ Benue. Ada ni obinrin akọkọ ti yoo jẹ oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADP.
Aduragbemi Animasawun. Young Progressive Party, Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
Aduragbemi Animasawun-Euba ni o jẹ obinrin kan soso to dije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progresive Party nipinlẹ Oyo.
Animasawun ni ti awọn ipinlẹ Oyo ba fun oun ni anfani lati di gomina ọpọlọpọ nnkan oun yoo mojuto, ti ọrọ ajẹ ipinlẹ yoo si gbero si ju ti tẹlẹ lọ.
Johnson-Ogbuneke Gladys Ikonnaya Ugozika: Social Democratic Party, Abia.

Oríṣun àwòrán, Others
Dokita onisegun, oloselu ati onisowo ni Ugozika, ẹni to jẹ oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu SDP nipinlẹ Abia.
Ugozika ni oun ni igbagbọ iṣejọba obinrin yoo kopa ribiribi ninu ilọsiwaju ipinlẹ Abia ati orilẹede Naijria ni apapọ.
Akẹkọọ jade fasiti Naijiria, Nsukka ni Ugozika nibi to gbe kawe gboye imọ lori ọrọ isegun oyinbo ati isẹ abẹ.
Lancaster- Okoro Nnennaya Ngwamma: People's Redemption Party, Abia

Oríṣun àwòrán, Others
Lancaster- Okoro Nnennaya Ngwamma ni ọpọlọpọ iriri lori sise olori awọn ẹka ijọba ati aladani lorilẹede Naijiria. Lancaster ni pupọ isoro to n ba awọn obinrin ni awọn obinrin fun arawọn.
O ni ijọba yoo mu idẹrun de awọn eeyan nipinlẹ ti wọn yan gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa.
Beatrice Itubo, Labour Party- Ipinlẹ Rivers

Oríṣun àwòrán, Others
Arabinrin Beatrice Itubo, ni oludije sipo gomina ipinlẹ Rivers labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party. Itubo na ni alaga fun awọn osisẹ nipinlẹ Rivers.
Itubo ni oun setan lati gbe ipinlẹ Rivers lọ si ilẹ ileri.
Aipẹ ni awọn ẹẹya kan ninu ẹgbẹ oṣelu Labour Party kede pe awọn ti tẹlẹ oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP sugbọn Itubo ni mimi kankan ko mi oun rara.
O ni awọn eeyan mọ aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu Labour Party, ti wọn si setan lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu naa lati gba ipinlẹ Rivers kuro lọwọ oko ẹru.















