Wo ohun tí Sanwo-Olu sọ nípa bí ológun ṣe ṣíná ìbọn fún àwọn olùwọ́de EndSARS ní Lekki Toll Gate

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọrọ nipa ipa to ko lasiko iwọde EndSARS to waye lọdun 2020, paapaa lẹyin ti awọn ologun ṣina ibọn fun awọn oluwọde naa ni Lekki Toll Gate.
Sanwo-Olu lo tu pẹrẹpẹ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise TV.
O ni oun gbe awọn igbesẹ to yẹ lati pana ọrọ naa ni itubi inubu ko to di rogbodiyan lalẹ ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
Sanwo-Olu sọ pe “Emi ni gomina akọkọ ni Naijiria to lọ ba awọn oluwọde lati pẹtu si wọn ninu.”
“Emi ni gomina akọkọ ti yoo gbe igbimọ kalẹ lati ri si ọrọ awọn to fi oniruuru ẹsun kan awọn ọlọpaa ki wọn le ri idajọ ododo gba.”
“Emi ni gomina to gbe ẹbẹ awọn oluwọde lọ siwaju Aarẹ Buhari.”
“Koda, loru ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, mo lọ kaakiri awọn ile iwosan lati yọju si awọn to farapa... bẹẹ si ni mo ṣe iranlọwọ iṣe atawọn nnkan mii fun awọn ti ọrọ naa kan amọ igba akọkọ ree ti mo maa mẹnuba.”
Ta lo paṣẹ fun awọn ologun lati dana ibọn ya awọn oluwọde?
Nigba ti awọn akọroyin bere lọwọ Sanwo-Olu ẹni to paṣẹ fun awọn ọmọ ogun lati yinbọn si awọn oluwọde ni Lekki, Sanwo-Olu ni ọrọ naa kọja agabra oun, ati pe oun ko laṣẹ lori awọn ọmọ ogun.
O ni “Ta lo paṣẹ ki awọn ologun yinbọn? Ta lo paṣẹ fun CPS ọlọpaa lati kọ ọrọ si mi lẹnu nilegbee Magodo lọjọsi?”

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
“Lọjọ idibo ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, awọn ọmọ ogun pọ laarin ilu ju awọn ọlọpaa lọ, ta lo paṣẹ fun awọn ọmọ ogun naa lati wa si Eko?”
“Nitori naa kii ṣe ojuṣe mi lati paṣẹ kankan fun awọn ọmọ ogun.”
“Ti ẹ ko ba gbagbe, iwọde naa ti bẹrẹ lati nnkan bii ọsẹ mẹta ṣaaju iṣẹlẹ naa, mi o lagbara kankan lori awọn ọmọ ogun, mi o si lagbara kankan lori ileeṣẹ ọlọpaa, idi ree ti a fi n tiraka lati ṣagbekalẹ ọlọpaa ipinlẹ.”
Sanwo sọ sọ siwaju si pe ile ni oun wa lale ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye pẹlu awọn alabaṣiṣẹ oun kan ki oun to gbọ pe igboro ti daru.
O tun mẹnuba ọrọ ẹlẹyamẹya to n milẹ titi nipinlẹ Eko lasiko eto dibo yii, eyii to bu ẹnu atẹ lu.














