Ẹ̀ ń pariwo pé Igbo ni ìyá Gbadebo-Vivour, Ìya Seyi ọmọ Tinubu n kọ́? Ẹ wá gbọ́ ìtàn - Bode George

Ojúlówó ọmọ Yorùbá ni Gbadebo ọmọ mi, kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Igbo, IPOB - Baba Rhodes -Vivour

Aworan Gbadebo Rhodes-Vivour

Oríṣun àwòrán, Gbadebo Rhodes-Vivour

Olawale Rhodes- Vivour, baba oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ti iroyin ofege ni iroyin to n sapejuwe ọmọ gẹgẹ bi ẹya igbo.

O ni ọmọ oun ko ni nnkan se pẹlu ẹgbẹ to n pe fun ominira ile Biafra nitori ojulowo ọmọ kaarọ ojire ni ọmọ rẹ.

"Gbedebo ko ni akọkọ fun IPOB, Ọmọ to kawe to gba oye ni.

"A le wo aseyọri rẹ nipinlẹ Eko, ko ni nnkan se pẹlu IPOB rara."

Rhodes-Vivour sọ eleyi nigba to n bawọn akọroyin sọrọni agbegebe Ikeja nipinlẹ Eko, to si fidi rẹ mulẹ pe ọmọ Yoruba ponbele ni ọmọ oun to fẹ mu ayipade ba ipinlẹ Eko.

"Gbadebo jẹ aja fẹtọ ti ko nifẹ si irẹjẹ tabi oun ti ko ba ofin mu.

"O mọ oun to fẹ, to si ma tẹle oun to fẹ lati fi mu ayipada de awujọ rẹ.

"Ko ni ohunkohun pẹlu ẹya Igbo rara."

Ẹ̀ ń pariwo pé Igbo ni ìyá Gbadebo-Vivour, Ìya Seyi ọmọ Tinubu n kọ́? Ẹ wá gbọ́ ìtàn - Bode George

Àkọlé fídíò, Bode George on Lagos Governor: Àbòsí ni gbogbo ìsọkúsọ tí wọ́n ń sọ, ọmọ Koko-Aguda ni Bàb

Eekan oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Oloye Bode George ti ba BBC Yoruba sọrọ lori gbogbo awuyewuye ati fakinfa to n waye nipinlẹ Eko laarin awọn oludije si ipo Gomina.

Bode George kọkọ bu ẹnu at lu bi ajọ eleto idibo INEC ṣe ni awọn kudiẹ kudiẹ lasiko kiko ibo jọ sori ẹrọ ayarabiaṣa to si ni ṣe lo yẹ ki wọn dawọ gbogbo nkan ti wọn n ṣe duro na ki wọn si wa ojutuu si iṣoron to wa nilẹ.

Lori awọn ara ipinlẹ Eko to n pariwo pe ọmọ ẹya Igbo ni oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Paraty ni Eko, ọpọlọpọ oko ọrọ ni Oloye Bode George ju lu wọn to si ṣalaye pe ọmọ Eko pọnbele ni Gbadebo Rhodes-Vivour.

Bode George
Bode George

Orin "ilu le o ko sowo lode, ọkunrin n kigbe o obinrin n kigbe o..." ni baba fi bẹnu to si ni ki awọn ọmọ Eko jade nile lọjọ idibo lati lọ dibo fun "ẹni to ba wu yin, to maa sọ ilu dẹrọ; ẹni to ṣee fọkan tan ti ko ni kowo yin jẹ fun iyawo ati ọmọ to jẹ pe awọn nikan ni wọn n gbe sibi gbe sọhun..."

"Ọmọ Koko-Aguda ni idile Vivour"

Gbadebo Rhodes-Vivour

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Oloye Bode George ni:

"Ti iya Vivour ba jẹ Igbo nkọ? Ṣe oni la ti n fẹ Igbo ni?

O ṣalaye pe nilẹ Yoruba ati nilẹ Naijiria orukọ ọkunrin ni ọmọ n jẹ kii ṣe ti iya.

O beere ibeere lọwọ awọn eeyan to n pariwo Gbadebo Vivour kiri pe "Gomina Ondo, ẹ̀ya wo ni iyawo ẹ?

Gomina Osun, ta ni iya ẹ, oun tilẹ tun gbọ ede Igbo, Gomina ipinlẹ Oyo, kin lorukọ iyawo ẹ, Bayelsa lo ti wa."

Lo ba tun mẹnu ba Seyi, ọmọ Bola Tinubu pe ki wọn lọ beere pe ta ni iya ẹ.

Oloye Bode ni ọmọ ẹya Igbo ni iya to bi ọmọkunrin Seyi Tinubu, ọmọ aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan Bola Tinubu.

torinaa, o jẹ ko di mimọ fun awọn ara Eko pe ọmọ Koko Aguda ni awọn idile Vivour. "Ṣe Koko Aguda o wa ki n ṣe ipinlẹ Eko mọ?"

Koda, ṣe Igbo kii san owo ori l'Eko?"

"Gbogbo ọmọ Eko, ẹ jade lọ dibo kẹẹ ma baa sọkun lọla o!"

Oloye Bode George ke si gbogbo awọn ara Eko pe ki wọn ma gbọ gbogbo irọ to n lọ lode ki wọn rii daju pe gbogbo wọn jade lọ dibo.

O ni ki wọn ma joko sile ki wọn rii pe wọn lọ dibo yan ẹni to ba wu wọ ki wọn ma baa kabamọ lọla.