Ẹ wo bí ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù U20 Naijiria ṣe fọwọ́ rẹ́ orílẹ̀èdè Tunisia nímú níbi ìdíje ẹlẹ́kùnjẹ̀kùn Áfríkà

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ agbaboolu ti ọjọ ori wọn ko tii ju ogun ọdun (U20 ) lọ ti orilẹ-ede Naijiria gba goolu mẹrin wo àwọ̀n ikọ agbaboolu labẹ ogun ọdun orilẹ-ede Tunisia. Ninu idije lati mo ẹniti yoo gbe ipo kẹta laarin awọn agbaboolu ti ọjọ ori wọn ko tii ju ogun ọdun lọ eyiti orilẹ-ede Egypt gba alejo rẹ. Ẹgbẹ agbaboolu Naijiria to ti jawe olubori ninu idije ẹlẹkunjekun Afrika lẹẹmeje ri ni ó padanu ṣọwọ orilẹ-ede Zambia pẹlu ami ayo kan eyiti o jẹ ko kuna lati de ipele asekagba. Laarin iṣẹju mẹsan akọkọ ni Ibrahim Muhammed ti gba goolu akọkọ wọle, o jẹ goolu keji ti yoo gba wọle ninu idije yii lẹyin to gba ọkan ninu goolu meji ti ẹgbẹ agbaboolu Naijiria fi jawe olubori orilẹ-ede Mozambique ninu isori akọkọ.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Football Federation/Facebook
Ahmed Abdullahi gba goolu keji wọle labala ekeji ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
̀Goolu yii ni yoo jẹ akọkọ rẹ ninu idije ọjẹwẹwẹ yii lẹyin to padanu goolu penariti ti Orilẹ-ede Zambia fi jawe olubori fún ipele asekagba. Ọmọ elese ayo Jude Sunday lo gba goolu kẹta ati kẹrin wọle fun ẹgbẹ agbaboolu orilẹ-ede yii lati gba ami baba lẹyin ti wọn jawe olubori sipo kẹta. Pẹlu ijawe olubori yii orilẹ-ede Naijiria wa lara ikọ mẹrin ti yoo ṣoju ẹkun adulawọ ninu idije ọjẹwẹwẹ agbaye ti ọjọ ori wọn ko tii ju ogun ọdun lọ ti yoo waye ni orilẹede Indonesia laarin oṣu karun si ìkẹfa.
Akọni mogba wọn Ladan Bosso ni iṣẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ ni nitori oun gbọdọ wa atamatase mẹrin ninu idije abẹle orilẹ-ede yii NPFL lati jẹ ki ọwọ iwaju ikọ na mu yanyan sii ṣaaju idije agbaye awọn ọjẹ Wẹwẹ. O ni awọn yo ṣiṣẹ lori akude ti wọn kọju ninu idije ile adulawo lati pegede ninu idije ifee ẹyẹ agbaye ọdun yii.











