Èmi olùdíjé Labour Party ní Oyo, mi ò juwọ́lẹ̀ fééyàn kankan tàbí Seyi Makinde - Tawfiq Tayo
Oludije oṣelu Labour Party ni ipinlẹ Oyo ti fesi si awuyewuye to n lọ kaakiri pe oun atawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti n lu ilu atilẹyin wọn fun Seyi Makinde.
O bu ẹnu atẹ lu iroyin to n lọ nigboro Oyo to si ti de gbogbo orilẹede Naijiria bayii wipe, awọn ọmọ ẹgbẹ Labour Party ni ipinlẹ Oyo ti lọ darapọ ti wọn si n ṣe atilẹyin fun Seyi Makinde nisisiyii.
Tawfiq ni iwa to buru jai ni adari ẹgbẹ awọn, Atayese Sodiq Tunji hu ati pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ Labour Party ni ilu Abuja ti ni awọn yoo gbe igbesẹ lori iwa aitọ ti o wu yii tori ko si alaṣẹ ẹgbẹ kankan to fun un ni aṣẹ lati ṣe nnkan to ṣee yi lati lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Oyo.

"Nigba ti ẹgbẹ wa ti ṣe ibo to gbe oludije wọle ti mo si ti jawe olubori, ko si ninu iwe ofin wa wipe taa ba fẹ dibo, ti ẹnikẹni o ba sọ fawọn loke pe awọn o ṣe ẹgbẹ mọ, wọn o le dede sọ pe awọn fẹ lọ ṣatilẹyin fun awọn ẹgbẹ taa ti jọ sọ tẹlẹ pe wọn o ṣe daadaa fun Naijira.
O ni: Gbogbo ayé ló ń fẹ́ràn ẹgbẹ wa Labour Party báyìí, Ọ̀rọ̀ rírùn ní ká ní ibi táà ti kúrò làá tún wá padà sí".
Tawfiq ni ko si ododo ninu ọrọ Atayese awọn si n fi asiko yii sọ fun gbogbo eeyan ati awọn ara ipinlẹ Oyo wipe ni Ọjọ Satide ọjọ idibo, ki wọn rii pe wọn jade lọ dibo.











