'Ta ni yóò tọ́jú mi lẹ́yìn ikú Oreoluwa' - ìyáìyá àgùnbánirọ̀ tó kú sínú ìjàmbá ọkọ̀ Eko figbe bọnu

Oríṣun àwòrán, Others
Ńṣe ni ìbànújẹ́ sọ orí àgbà kodò ní ilé àwọn mọ̀lẹ́bí àgùnbánirọ̀ kan tó pàdánú ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Eko àti ọkọ̀ ojú irin tó wáyé lọ́jọ́bọ̀.
Àwọn ẹbí àgùnbánirọ̀ náà ní ikú arábìnrin náà ṣì ń ṣe àwọn ní kàyéfì nítorí ọmọ dáadáa ni ọmọ náà jẹ́.
Aina Oreoluwa Juliana, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n jẹ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mẹ́fà tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá náà ní agbègbè PWD.
Ní iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Eko ni Aina Oreoluwa ti ń ṣe àgùbánirọ̀ ọlọ́dún kan kó tó di pé ikú òjijì tó múu lọ.
Ní ọjọ́bọ̀ ni ọkọ̀ iléeṣẹ́ ìjọba Eko tó kó ènìyàn 85 kó sẹ́nu ọkọ̀ ojú irin kan ní agbègbè PWD.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ní ìwádìí fi hàn pé awakọ̀ ọkọ̀ náà lọ ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ náà.
Sanwo-Olu ní nínú àwọn 85 tó wà nínú ọkọ̀ náà, ènìyàn mẹ́fà ló kú tí àwọn mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sì farapa yánnayànna.
Àwọn 42 ni ìpalára ti wọn kò pọ̀ púpọ̀, tí àwọn mẹ́jọ tó kù sì fara ha lásán.
Ìyáìyá Aina Oreoluwa bú sẹ́kún

Oríṣun àwòrán, Others
Nígbà tí ìyáìyá Aina ń bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀, ó ní àkọ́bí ọmọọmọ òun ni Aina jẹ́ àti pé òun ni ó ń tọ́jú òun.
Ìyá náà pẹ̀lú ọgbẹ́ ọkàn ní Aina ló má ń bá òun ṣe gbogbo nǹkan nínú ilé tó sì jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún òun pé kò sí ẹni tí yóò máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí fún òun mọ́.
“Tó bá rẹ̀ mí, òun ló máa ń bámi ra oògùn, kìí fẹ́ kí ìyà kankan tàbí kí èrà rìnmí rárá, ta ni mo fẹ́ máa pè báyìí.”
Bákan náà ni ìbátan rẹ̀ kan, Tope Aina sọ wí pé àwọn máa ṣe àyẹ̀wò òkú rẹ̀ nítorí kò sí ọgbẹ́ kankan lára òkú rẹ̀.
Tope ní lẹ́yìn púlásítà kan tí wọ́n lẹ̀ mọ lórí láti fi kọ orúkọ le lórí, kò sí ọgbẹ́ kankan ní ara rẹ̀ àti pé yóó wu àwọn láti mọ nǹkan tó ṣe okùnfà ikú rẹ̀ gan.
Bákan náà ni mọ̀lẹ́bí rẹ̀ mìíràn tó tún bá BBC sọ̀rọ̀ ní Oreoluwa ní èròńgbà láti lọ sí UK lẹ́yìn tó bá sin orílẹ̀ èdè bàbá rẹ̀ tán láti lọ kàwé si.
“Ó jẹ́ ohun tó bani lọ́kǹ jẹ́ gidi pé ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ṣẹlẹ̀ sí ìdílé wa, mi ò gbàgbọ́ pé Oreoluwa ti kú náà nìyẹn.”
Gómìnà Sanwo-Olu ṣàbẹ̀wò sí ìyáìyá Oreoluwa, Buhari bá ẹbí kẹ́dùn

Oríṣun àwòrán, @BABAJIDE SANWO-OLU/TWITTER
Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ṣàbẹ̀wò sí àwọn ẹbí Oreoluwa àtàwọn ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níní ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Sanwo-Olu àrọwà sáwọn ẹbí náà láti gba àdánù wọn gẹ́gẹ́ bí àmúwá Ọlọ́run àti pé bó ṣe wu Olúwa lọ ń ṣọlá.
Bákan náà ni ààrẹ Muhammadu Buhari bá ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá náà kẹ́dùn.
Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run mú àwọn tó farapa lára dá ní kíákíá.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
''Àwọn 32 tó farapa nínú ìjàmba ọkọ̀ relúwẹ́ ní Eko tí kúrò ní iléwòsàn''

Kọmiṣọnna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi ni awọn oṣiṣẹ mejilelọgbọn lo ti kuro ni ile iwosan lẹyin ti wọn ti gba ilera to peye.
Eyi ko ṣẹyin bi ọkọ akero ni ilu Eko ṣe ko si ẹnu reluwe ni agbegbe Ikeja nipinlẹ Eko.
Abayomi lasiko to n ba awọn akọroyin nipinlẹ Eko ni ileewosan ẹkọni Lagos State University Teaching Hospital, Lasuth ni eniyan mejilelọgọrun lo fi ara gba ninu iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, iye awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa ni mẹfa, ti awọn mọkanlelogun si ti kuro ni ileewosan Lasuth bayii.
O fikun un pe awọn eniyan fi ẹjẹ silẹ lati ṣeranwọ fun awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa, to si dupẹ lọwọ wọn.
‘’Titi di asiko ti mo n ba yin sọrọ yii, ko si ẹlomiran to tun padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa yatọ si awọn mẹfa ti tẹlẹ.’’
‘’Bakan naa ni awọn to n gba iwosan lọwọ wa ni alaafia, ti ko si ewu fun wọn ni ileewosan’’
A ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ọpọlọ awakọ̀ BRT tó kó sẹ́nu ọkọ̀ ojú irin - Iléeṣẹ́ ọlapàá Eko

Kọmiṣọna ọlọpaa ẹkun Railway Command niluu Eko, CP Yetunde Longe ti sọ pe awọn ti bẹrẹ ayẹwo ọpọlọ fun awakọ BRT to ko sẹnu ọkọ oju irin laarọ Ọjọbọ.
Longe lo fi ọrọ naa lede lasiko to n ba akọroyin sọrọ nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ti fasiti ilu Eko, LASUTH.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ gbe awakọ naa lọ sile iwosan ọhun lati ṣe awọn ayẹwo kan fun un lẹyin ijamba naa.
Longe sọ pe awọn n ṣe iwadii iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ ni pato, awọn yoo si ṣe ayẹwo oku awọn eeyan ọhun.
O ni “Awakọ naa wa pẹlu wa bi a sẹ n sọrọ yii, a o fa le awọn dọkita lọwọ fun ayẹwo.”

“Nitori ẹni to wa nibi ọkọ oju irin naa ke si pe ko duro nitori ọkọ naa n bọ amọ o kọ ọrọ si ẹni naa lẹnu, eredi ree ti a ṣe gbọdọ ṣe ayẹwo ọpọlọ fun.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
“Gẹgẹ bii awakọ, ara awọn ayẹwo ti wọn gbọdọ ṣe ree nitori ki wọn to ya nibi ti ọkọ oju irin n gba, ọkọ oju irin naa yoo maa fun fere pe oun n bọ, awọn awakọ ero si gbọdọ duro.”
Nigba ti awọn akọroyin bere lọwọ rẹ boya ohun ti wọn fi n di ọna wa ki awọn ọkọ oju irin ma ba maa gba awọn ọkọ ero to n kọja nibẹ, o ni ohun ti wọn fi n di ọna naa ko si nibẹ mọ.
Amọ o ṣalaye pe ọkunrin kan wa nibẹ to mu aṣọ pupa lọwọ, to si ke si awakọ BRT naa pe ko duro amọ o kọ eti ikun si.
Longe pari ọrọ rẹ pe awakọ BRT ọhun yoo foju bale ẹjọ to ba jẹbi ọrọ naa, awọn si ti n wa awọn ẹri ti wọn yoo fi gbe lọ sile ẹjọ.
Eeyan mejilọgọrun lo fara gba ninu ijamba naa, nigba ti awọn mẹfa jade laye.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Dẹ́rẹ́bà tó wa bọ́ọ̀sì to kọlu rélùwéè l’Eko ti jọ̀wọ́ ara rẹ́ fún ọlọ́pàá

Dẹrẹba to wa ọkọ bọọsi BRT to forigbari pẹlu reluwe nilu Eko l’Ọjọbọ ti jọwọ ara rẹsilẹ fawọn agbofinro.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo sọ eyi nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to ṣe abẹyin si ile iwosan nla fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH.
Awakọ to wa ọkọ bọọsi BRT awọn oṣiṣẹ ijọba naa ti kọkọ sa lọ ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ki o to di pe o pada fara rẹ han.
Gomina Sanwo-Olu ni awakọ naa ti wa ni akoso awọn ọlọpaa bayii.
Awọn marundinlọgbọn ti gba itọju kiakia wọn si ti n gbe wọn lọ si awọn ile iwosan ijọba miran kaakiri ipinlẹ Eko.
Gomina Sanwo-Olu tun fi kun un pe ijọba ero marundinlaadọrun 85 lo wa ninu ọkọ bọọsi naa, mejilelogoji ninu wọn ni ohun to ṣe wọn ko fi bẹẹ pọ pupọ, mọkandinlọgbọn ninu wọn lo fara ṣeṣe pupọpupọ, ti mẹjọ ninu wọn si farapa fẹẹrẹfẹ.

Eeyan mẹfa lo ti jade laye ninu awọn eeyan to farakaasa ijamba naa. Meji ninu wọn ni wọn gbe de ile iwosan loku, ṣugbọn mẹrin miran jade laye lẹyin ti wọn gbe wọn de ile iwosan.
O fi kun un ninu alaye rẹ pe awọn ọmọde ti wọn jẹ akẹkọọ ti wọn n lọ pẹlu awọn obi wọn to jẹ oṣiṣẹ ijọba Eko wa ninu ọkọ bọọsi naa nigba ti ijamba naa waye.
Sanwo-olu kéde ọjọ́ ọ̀fọ̀ l’Eko nítorí ìjàmbá bọ́ọ̀sì BRT àti rélùwéè, Mínísítà pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede ọjọ mẹta lati fi ṣọfọ lori iṣẹlẹ ijamba reluwa ati bọọsi BRT ijọba Eko to kọlu ara wọn nilu Eko.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo kede eyi lasiko to n daro lori ijamba naa eyi to ti gba ẹmi eeyan mẹfa bayii.
Agbẹnusọ fun gomina Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile ṣalaye ninu atẹjade kan pe awọn oṣiṣẹ ijọba yoo ṣiwọ iṣẹ laago mejila lọjọ Ẹti gẹgẹ bi ara idaro naa.
Ọkọ awọn oṣiṣẹ ijọba ni ọkọ bọọsi BRT to kọlu reluwe naa, awọn oṣiṣẹ ijọba si ni gbogbo awọn ero to wa ninu kọ bọọsi BRT naa.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko tun paṣẹ pe ki wọn rẹ gbogbo awọn aṣia to ba n fẹ ni ipinlẹ Eko silẹ de ilaji opo wọn pẹlu.
“Inu ibanujẹ ni gomina wa bayii, bakan naa lo fi ọrọ ibanikẹdun rẹ ranṣẹ si gbogbo awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa pẹlu adura pe ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.”
Gomina Sanwo-Olu rọ awọn eeyan lati maa gbadura fun awọn mọlẹbi awọn to ku naa ati aanu fun ipinlẹ Eko.
Gomina Eko ko ṣai dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Eko ti wọn darapọ m awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi gbogbo lati doola awọn eeyan to wa ninu ijamba naa nigba to ṣẹlẹ.
Minisita paṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa

Ẹwẹ, minisita fun igbokegbodo ọkọ ofurufu, Hadi Sirika ti paṣẹ fun ajọ iwadi abo fun iṣẹlẹ ijamba ọkọ lorilẹede Naijiria, NSIB lati bẹrẹ iwadii lori ijamba to waye laarin ọkọ bọọsi BRT ati reluwe nilu Eko lowurọ ọjọbọ.
Ninu atẹjade kan eyi ti James Odaudu to jẹ amugbalẹgbẹ fun minisita, Hadi Sirika fi sita, Minisita naa sọ pe ohun to bani ninujẹ gbaa ni ijamba naa, pẹlu idaniloju pe ajọ iwadi abo fun iṣẹlẹ ijamba ọkọ lorilẹede Naijiria, NSIB lati mọ awọn ohun to ṣe okunfa ijamba naa lọna ati lee mu aba wa lati dena iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.
Awọn eeyan n fi ẹjẹ silẹ fun awọn to wa ninu ijamba naa

Awọn eeyan ti n fi ẹjẹ silẹ lawọn ile iwosan ti wọn gbe awọn eeyan to farakaasa ninu ijamba bọọsi ati reluwe lọ nilu Eko.
Amugbalẹgbẹ agba fun gomina Sanwo-Olu ṣalaye pe wọn ko awọn eeyan naa lọ si ilee iwosan ijọba General Hospital ni Gbagada, ibudo itọju awọn to lugbadi iṣẹlẹ pajawiri, Lagos State Accident and Emergency Center ni Toll gate nilu Eko.
Bakan naa ni wọn ko awọn miran lọ si ileewosan ijọba General hospital ni Lagos Island, ileewosan Folarin Coker Staff Clinic, ni Alausa Ikẹja ati ile iwosan nla ti fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH
Ọ̀kọ̀ reluwé tó gbé bọ́ọ̀sì há ẹnu, èèyàn 6 ti kú, 84 farapa!

Awọn alaṣẹ ieeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti fi aridaju han pe Bọọsi kan to jẹ ọ́kọ́ ijọba ipinlẹ Eko ni ọkọ̀ oju irin reluwe kan kọlu to si gbe hanu titi to fi rin gbẹẹrẹ lati agbegbe Ikeja titi de agbegbe Shogunle ni ipinlẹ Eko.
Oludari ẹka iha Iwọ Oorun-Guusu Naijiria, Ibrahim Farinloye sọ fun BBC Yoruba atawọn oniroyin to wa nibi iṣẹlẹ naa pe iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ ti di mẹfa bayii.
O ṣalaye pe eeyan meji ti ku tẹlẹ lati ibi iṣẹlẹ naa, kete ti wọn gbe gbogbo awọn to farapa de ileewosan LASUTH ni awọn mẹrin mii ku.
Nigba ti wọn kọkọ wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, aṣoju ajọ LASEMA ti kọkọ sọ pe ohun ti awọn ba nibẹ ni pe ọkunrin kan ati obinrin meji lo ti ku, amọ nigba ti ikọ to ko awọn to fara pa lọ ileewosan yoo fi de ibẹ, wọn gba iroyin pe iye awọn to ku ti di mẹfa.
Nnkan bi ago mẹjọ ku diẹ la gbọ pe wahala ṣẹlẹ loju irin ti ọkọ Reluwe naa kọlu bọọsi.
"Oṣojumikoro"

Awọn oṣojumikoro to wa nibẹ sọ fun akọroyin BBC Yoruba pe oṣiṣẹ ọkọ̀ oju irin sọ fun dẹrẹ́ba to n wa bọọsi ijọba naa pe ko ni suuru ko ma tii rekọja oju irin naa amọ o kọ eti ikun sii.
Awọn to ṣe oju wọn koro ni o sọ fun un pe ọkọ Reluwe n bọ wa kọja pe ko ni suuru amọ ko gbọ.
Bo ṣe wa bọọsi to n rekọja oju irin ọhun ni ọkọ reluwe de lọgan to si gbe e hanu.
Wọn ni ọkọ oju irin ọhun ti wọ inu ara bọọsi naa to si gbe e sẹnu rin lati Ikeja titi de Shogunle.

Aṣoju Ajọ LASEMA

“Wakati mẹrinlelogun la fi n ṣe iṣẹ pajawiri a si maa n ṣe ohun gbogbo lati doola ẹmi eniyan”. Oludari ajọ LASEMA sọ bẹẹ.
Bakan naa lo ni wọn ti gbe oku awọn to ba a lọ lọ si Mọṣuari.
O ṣalaye awọn irinṣẹ ti awọn oṣiṣẹ wọn lo ati gbogbo akitiyan ti wọn n ṣe lati tu ọkọ Reluwe ati bọọ́si to ti lẹpọ̀ yii ka.
Awọn mẹtẹẹta to ku yii jẹ awọ́n arinrinajo to wa ninu bọọsi naa.
Ni asiko ti akọroyin wa wa nibi iṣẹlẹ naa, a rii ti wọ́n ti n fi irinṣẹ nla ajọ LASEMA lati fi gbe bọọ́si naa.
Bakan naa ni wọn ti lọ gbe ori ọkọ Reluwe mii wa lati fi gbe eyi to gbe bọọsi hanu.
Ninu fidio naa, a rii ti awọn oṣiṣẹ n le awọn eeyan to wa lẹgbẹ ọkọ oju irin mejeeji kuro eyi to le tumọ si pe boya ọkan ti fẹ gbera lati fa eyi to ni ijamba lọ kuro loju irin naa.














