Àìkójú òṣùwọ̀n INEC ló mú kí a gbé wọn lọ ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ 'Temporary Voters Card'

Oríṣun àwòrán, INEC

Oríṣun àwòrán, Segun Kofoworola
Awọn agbẹjọro to pe INEC lẹjọ lori ọrọ lilo Temporary Voter’s Card, TVC, ti sọ pe awọn ṣe bẹẹ nitori aikoju oṣuwọn INEC.
Aṣoju awọn agbẹjọro ọhun, Victor Opatola ṣalaye fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan pe INEC kuna ninu ojuṣe rẹ, eyii ti ko jẹ ki ọpọ araalu le dibo lọjọ idibo.
Opatola ni “Eredi ti a ṣe pe INEC lẹjọ ni pe awọn eeyan kan ti ṣe gbogbo ohun to yẹ labẹ ofin lati le ni kaadi idibo alalopẹ wọn, PVC, amọ INEC fun wọn ni TVC wọn si sọ pe ẹni ti ko ba ni PVC ko le dibo.”
“Itumọ eleyii ni pe awọn eeyan naa ko le dibo bo tilẹ jẹ pe wọn ṣe ohun gbogbo to yẹ ki wọn ṣe labẹ ofin.”
“Eredi ree ti a fi lọ sile ẹjọ nitori awọn eeyan naa ti ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere lati le dibo amọ INEC lo kuna lati fun wọn ni PVC.”
Opatola ṣalaye pe niwọn igba ti orukọ, aworan ati ika awọn eeyan naa ti wa lọdọ INEC, ajọ ọhun ko lagbara lati sọ pe ki awọn eeyan naa ma.”
Gẹgẹ bii alaye rẹ, TVC yii le ṣiṣẹ lọjọ idibo nitori ohun kan naa lo wa lori BVAS ati ẹrọ ‘card reader’ ti wọn n lo tẹlẹ.
O pari ọrọ rẹ pe iṣẹ kan naa ni PCV ati TVC n ṣe, ko si yẹ ki INEC dẹkun ẹnikẹni lati dibo nitori ko ni PVC niwọn igba to ni TVC.
O fi kun pe ẹtọ gbogbo ọmọ Naijiria ni lati dibo, niwọn igba ti irufẹ ẹni bẹẹ ba si ti forukọsileẹ, to si ni kaadi TVC naa lọwọ, o yẹ ko dibo.
“Ko tọ si INEC lati kọ aṣẹ ile ẹjọ”

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi
Nigba to n da si ọrọ ọhun, amofin ati ajafẹtọ ọmọniyan kan, Dele Farotimi ti ni idajọ ododo ni ile ẹjọ to da ẹjọ naa da, ati pe INEC gbọdọ tẹlẹ aṣẹ ile ẹjọ ọhun.
O ni ṣe lo da bii pe INEC kii fẹ ki awọn eeyan dibo, bi bẹẹ kọ, ko yẹ ko si iyatọ kankan laarin lilo TVC ati PVC.
Farotimi sọ pe “Niwọn igba ti ile ẹjọ ko tii da ẹjọ naa nu, gbogbo ẹni to ba ti de ibudo idibo pẹlu TVC ni wọn gbọdọ da lohun lati dibo.”
“Gbogbo ohun to wa lori ẹrọ INEC fun ẹni to ni PVC naa lo wa lori ẹrọ kan naa fun ẹni to ni TVC, ko si iyatọ, o yẹ ki wọn le dibo.”
Ilé ẹjọ pàṣẹ fún INEC kó fàyè gba ‘Temporary Voter Card’ fún ìdìbò

Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ fun ajọ eleto idibo, INEC, lati faye gba lilo kaadi idibo to wa fun igba ranpẹ, Temporary Voter Cards, lọjọ idibo gomina to n bọ yii.
Agbẹjọro meji kan lo pe ẹjọ pe o yẹ ki INEC gba awọn laaye lati le dibo pẹlu kaadi naa.
Awọn agbẹjọro ọhun, Kofoworola Olusegun ati Wilson Allwell, ninu ẹjọ ti wọn pe lọjọ kẹjọ, oṣu Keji, eyii to ni nọmba FHC/ABJ/CS/180/2023, pe INEC nija pe niwọn igba ti orukọ wọn ti wa lọdọ INEC, ti awọn si ni nọmba idanimọ gẹgẹ bii oludibo, o yẹ ki wọn le dibo pẹlu kaadi idibo ti wa fun igba diẹ.
Opatola Victor, to ṣoju awọn olupẹjọ ọhun nile ẹjọ tun bẹ ile ẹjọ naa lọwẹ lati mọ boya wọn lẹtọọ lati dibo latari aṣiṣe INEC.
Lẹyin naa lo bẹ INEC pe ko paṣẹ fun INEC lati gba awọn eeyan ọhun, ti wọn ti forukọsilẹ laaye lati dibo pẹlu kaadi idibo to wa fun igba diẹ.
Ninu idajọ rẹ, adajọ Obiora Atuegwu Egwuatu, sọ pe ko si ibi kankan ninu iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ati iwe ofin eto idibo to sọ pe kaadi idibo alalopẹ nikan ni awọn araalu gbọdọ fi dibo.
Egwuatu wa dajọ pe “olujẹjọ gbọdọ gba awọn olupẹjọ laye lati dibo pẹlu kaadi dibo alakoko ranpẹ wọn, eyii ti olujẹjọ fun wọn, lẹyin to ti gba orukọ ati aworan wọn silẹ ṣaaju.”
Adajọ ọhun tun sọ siwaju si pe, awọn araalu lẹtọ lati fi kaadi idibo naa dibo ninu eto idibo gbogbogbo ti ọdun 2023 yii lẹyin ti wọn forukọsilẹ lọdọ INEC gẹgẹ bii ilana ofin.
Amọ adajọ naa ko faye gba ki gbogbo araalu lo kaadi naa lati fi dibo nitori wọn ko pe ẹjọ ọhun lorukọ gbogbo araalu.
A o pe ẹjọ kotẹmilọrun – INEC
Ẹwẹ, INEC ti sọ pe oun yo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ naa.
Agbẹnusọ INEC, Rotimi Oyekanmi lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ni esi si idajọ ọhun.
O ni “INEC ti gba iwe idajọ ile ẹjọ giga kan l’Abuja, eyii to faye olupẹjọ meji lati fi kaadi idibo wọn to wa fun igba diẹ dibo.”
“Ajọ yii ti n gbe igbesẹ ni kankan lati pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ yii.”












