Afurasí agbébọn ṣe kọlù sí ìjọ Jehovah Witness" òkú sún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ farapa yánáyáná

Oríṣun àwòrán, others
Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ti agbebọn kan ṣe si ile ijọsin awọn ajẹri Jehofa, ti awọn miran si farapa yana-yana.
Awọn oṣiṣẹ agbofinro ni ẹniti o ṣiṣẹ ibi naa ṣeeṣe ko wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ ọhun.
Ikọlu naa waye ni Ariwa Hamburg to wa ni orilẹ-ede Germany.
Awọn ile-iṣẹ iroyin Germany ni o kere tan eeyan mẹfa sì meje lo padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ naa.
Ninu ọrọ táwọn oṣiṣẹ agbofinro fi lede wọn ni, ko tii si iroyin pipe nipa idi ti agbebọn naa fi hu iwa ibi naa, nibi ti ọpọlọpọ eeyan ti farapa ni Deelböge agbegbe Gross Borstel ni Hamburg.
Awọn oṣiṣẹ agbofinro ni oku ẹniti o ṣeeṣe ko jẹ afurasi nibi isẹlẹ naa wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ti iṣẹ ṣi n tẹsiwaju.
Fídíò ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìjọ Jehovah Witness rèé:

Aṣoju ile iṣe ọlọpaa Holger Vehren ni bi aago mẹsan kọja iṣẹju maarundinlogun ni wọn pe ile iṣe ọlọpaa wi pe wọn gburo iro ibọn ninu ile ijọsin naa.
Holger ni ko si aridaju wi pe ẹniti o ṣiṣẹ ibi na sakuro nibi isẹlẹ ọhun ti awọn to farapa nipasẹ ọta ibọn si ti wá ní ile iwosan fun itọju.
Ninu fọnran, a ri awọn agbofinro ti wọn kọwọrin pẹlu awọn to farapa ti wọn si n mu wọn wọ inu ọkọ agboku ile iwosan fun itọju.
Minisita fun ọrọ abẹle Hamburg Andy Grote ninu ikanni ayelujara Twitter rẹ ni ijọba ti fi ọpọlọpọ awọn agbofinro ransẹ sibi isẹlẹ naa.
Ti wọn si rọ awọn araalu lati ma ṣe gbe iroyin ofege tabi sọ oun ti oju wọn ko ri nipa iṣẹlẹ naa.
Awọn ẹlẹsin ihinrere Jehofa ni wọn jẹ igun kan ninu awọn Kristẹni, ti wọn da silẹ lorilẹede Amẹrika.
















