Àgbà ẹgbẹ́ PDP méjì rẹ́wọ̀n he lórí gbígba rìbá N142m àti ìbò yíyí

EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC

Awọn agba ẹgbẹ oselu PDP meji nipinlẹ Bauchi ti ri ẹwọn ọdun meji he lori ẹsun pe wọn lẹdi apo pọ lati gba riba, ti wọn si tun yi ibo.

Orukọ awọn agba oselu mejeeji naa ni Aminu Umar Gadiya ati Saleh Hussaini Gamawa.

Ile ẹjọ giga tipinlẹ Bauchi lo sọ awọn oloselu naa sẹwọn ọdun meji lori pe wọn jẹbi kiko owo tuulu to to milliọnu mejilelogoje ati ẹgbẹrun lọna ojidinlẹẹdẹgbẹta naira (N142,460,000.00).

Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ EFCC fisita lati ọdọ akọwe iroyin rẹ, Wilson Uwujaren, o ni Adajọ Hassan Dikko lo sọ awọn oloselu naa sẹwọn ninu ẹsun ti ajọ EFCC gbe wa siwaju rẹ.

Ọjọ Kẹrin osu kẹfa ọdun ati ọjọ kẹrindinlogun osu Kẹwa ọdun 2018 ni awọn mejeeji naa yọju sile ẹjọ lori ẹsun onikoko meji ọhun.

Awọn ẹsun mejeeji naa lo da lori gbigba owo riba to le ni miliọnu mejilelogoje naira ati yiyi esi ibo aarẹ to waye lọdun 2015 nipinlẹ Bauchi.

Lati ọjọ keji osu kẹta ọdun 2023 ni awọn ẹlẹwọn mejeeji yoo maa sẹwọn wọn ni tẹle n tẹle lori awọn ẹsun mejeeji ti wọn fi kan wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Òṣìṣẹ́ ọmọ ogun orí omi fìyà jẹ ọlọ́pàá, ló bá di èrò àtìmọ́lé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshoot

Awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpaa kan ni ipinlẹ Delta ni wọn ti rí iya he lọwọ awọn oṣiṣẹ ọmọ ogun ori omi orilẹ-ede yii.

Ninu fọnran to gba ori ẹrọ ayelujara la ti ri awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ologun ori omi ti wọn ṣẹṣẹ gba ṣiṣẹ, to n na awọn ọlọpaa ti agọ ọlọpaa Enerhen.

Ninu fọnran naa ni ẹnikan to wọ aṣọ ọlọpaa ti orukọ rẹ n jẹ Kingsley, ti ẹjẹ bo oju rẹ tí aṣọ ara rẹ tun ti faya di ọkunrin kan mú ti awọn akẹgbẹ rẹ si n bẹẹ lati fi aṣọ ọkunrin naa silẹ.

Fọnran mii tun ṣe afihan ibi ti ọlọpaa kan àti oṣiṣẹ ọmọ ogun ori omi ti n bara wọn wọya ija.

Awọn ti wọn ko fẹ ki a darukọ wọn ni ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ ọmọ ogun ori omi fẹ fi ọrọ naa ṣe oku oru nitori wọn o fẹ ki awọn ara ilu mọ nnkan to ṣẹlẹ gan.

Ohun to fa ija naa gan ni a ko le fi idi rẹ mulẹ amọ awọn kan n sọ wi pe ọrọ owo lo da ija silẹ laarin wọn.

Igba akọkọ tabi ekeji kọ niyi ti ifanfa maa waye laaarin awọn ile iṣẹ ologun ati ọlọpaa amọ igba akọkọ niyi ti wọn yoo gbe ija naa wọ agọ ọlọpaa lọ.

Ni bayii ile iṣẹ ogun oju omi ni awọn ti fi oṣiṣẹ rẹ to wa ninu fọnran naa si atimọle.

Alukoro fun ajọ ọmọ ogun ori omi, Adedotun Ayo-Vaughan ni awọn oṣiṣẹ rẹ to wa ninu fọnran naa ti wa ní atimọle lati gbọrọ ẹnu wọn, ti wọn o sì fi iya to tọ jẹ wọn.