Ọmọ ọdún mẹ́tàlá rí ìbọn he lẹ́yìn ilé, ó pa ọmọ ọdún mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Ogun, ariwo sọ!

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Semiu Adegesin, lori iku ọmọ ọdun mẹta kan, Esther Samuel.
Ọlọpaa mu Adegesin lori ẹsun aibikita, eyii to yọri si iku ọmọ kekere naa.
Afurasi ọhun wọ ijọgbọn lẹyin to fi ibọn rẹ, eyii ti ọta wa ninu rẹ silẹ lẹyinkunle ile wọn nibi ti awọn ọmọde ti n ṣere.
Iroyin ni ọmọ ọdun mẹtala kan, Babalola, lọ gbe ibọn naa nibi ti Adegesin fi silẹ si, to si yin in sin ọmọ ọdun mẹta naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe awọn mu afurasi ọhun lẹyin ti awọn eeyan gbe ọrọ naa wa si agọ awọn to wa ni Imasayi.
Atẹjade ti Oyeyemi fi ṣọwọ si awọn akọroyin ṣalaye pe abule Kukudi, ni Imasayi, ni Babalola ti yinbọn pa ọmọ ọdun mẹta ọhun.
O ni “Nigba ti awọn ọlọpaa de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, inu agbara ẹjẹ ni a ti ba oku ọmọde naa.”
“Iwadii akọkọ ti a sẹ fihan pe Semiu Adegesin, to ni ibọn naa, fi ọta sinu ibọn ọhun, o si fi silẹ lai bikita lẹyinkunle ile ti awọn ọmọ kekere ti n ṣere.”
“Ibi to fi silẹ silẹ si ni Balogun to jẹ ọmọ ọdun mẹtala ti gbe ibọn naa, to si yin in si oloogbe.”
“Wọn gbe oloogbe naa digbadigba lọ sile iwosan ijọba to wa ni Ilaro, amọ dokita to wa lẹnu iṣẹ sọ pe o ti ku.”
“Laipẹ lẹyin naa ni a fi ṣikun ofin mu ẹni to ni ibọn ọhun lọ si agọ wa fun iwadii.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Frank Mba, ti ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun.
Ọlọpaa ti wa rọ awọn eeyan agbegbe naa ki wọn ṣe surru nigba ti iwadii n lọ lọwọ.














