Jàǹdùkú fẹ́ pa mí níbi ìpolongo ìbò Labour Party ní Epe, orí ló kó mi yọ lọ -Rhodes-Vivour

Ipolongo ibo Labour Party in Epe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oludije fun ẹgbẹ oselu Labour Party nipinlẹ Eko, Gbadebo Rhodes-Vivour, ti figbe ta pe awọn eeyan kan ti fẹ gba ẹmi oun.

Rhodes-Vivour ni se ni awọn janduku wa da ipolongo ibo oun to waye nilu Epe ru, ti wọn si n yin ọta ibọn sawọn alatilẹyin oun.

Ikede kan ti oludije sipo gomina naa fi soju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku lo sisọ loju ọrọ yii.Bakan naa lo ni Olawale Oluwo, ẹni to ti fi igba kan ri jẹ kọmisona nipinlẹ Eko labẹ gomina ana, Akinwumi Ambode ni ori ko yọ nigba ti awọn agbebọn na dabọn bolẹ.

Aworan Gbadebo Rhodes-Vivour

Oríṣun àwòrán, Gbadebo Rhodes-Vivour/Twitter

Gbadebo Rhodes-Vivour ni oun ati akẹgbẹ oun lẹgbẹ oṣelu Boot Party ni awọn dijọ kọwọrin nitori o ti gba lati ṣiṣẹ pọ pẹlu oun.

O ni bi awọn ṣe de adugbo Ita Opo ni awọn agbebon naa dabon bolẹ, ti wọn si di ọna abawọle si ilu naa.

Oludije gpmina naa ni awọn ẹsọ alaabo to kọwọrin pẹlu oun lo to tu wọn ka.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

APC Eko fèsì padà fún olùdíje gómìna fẹ́gbẹ́ Labour Party pé òjìji rẹ̀ ló ń dà á láàmú

Wayi o, ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Eko ti fesi pada fun oludije fẹgbẹ oselu Labour nipinlẹ Eko, Gbadebo Rhodes-Vivour lori ẹsun pe awọn eeyan kan fẹ gbẹmi oun.

Atẹjade kan ti akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Eko, Seye Oladejo fisita wa kede pe ojiji Gbadebo lo n dẹru ba, lo se ro pe awọn eeyan kan n lepa rẹ.

Ẹgbẹ APCni oselu to buru jai ni ki eeyan kan maa kona mọ omi oselu to n gbona lọwọ pẹlu ẹsun wọn fẹ seku pa oun eyi to ni o le ko ẹru nla bawọn araalu.

APC ni se lo yẹ ki Rhodes-Vivour tọ ileesẹ ọlọpaa lọ lati fi ẹsun banta-banta bi eyi to wọn leti nitori ko dara to ki oludije funpo gomina naa kan maa kede ẹsun lasan sita.

Mo máa fòpin sọ̀rọ̀ àwọn “agbero” bí mo bá di gómìnà Eko – Rhodes-Vivour

Gbadebo Rhodes-Vivour

Oríṣun àwòrán, Facebook

Olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ìpínlẹ̀ Eko, Gbadebo Rodes-Vivour ti ní gbogbo ìpèníjà tó ń kojú àwọn ará ìpínlẹ̀ Eko ni òun yóò wá ojútùú tóun bá jáwé olúborí lásìkò ìbò tó ń bọ̀ yìí.

Rhodes-Vivour sọ àrídájú ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò kan èyí tí ikọ̀ “Obidient Movement” gbé kalẹ̀ ní agbègbè Ikeja GRA, ìpínlẹ̀ Eko.

Ó ní ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn kò ní fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti fi ẹ̀tọ́ àwọn alátìlẹyìn wọn dùn wọ́n lásìkò ìbò dídì, wí pé àwọn kò ní gbà kí wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ wọn lójú mọ́lẹ̀.

Ó fi kun pé ètò náà jẹ́ ọkàn lára àwọn ọ̀nà láti fi gba ìpínlẹ̀ Eko kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń so ìpínlẹ̀ náà mọ́lẹ̀.

Èdè Yorùbá kọ̀ ni yóò mú ìṣèjọba rere wá - GRV

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó gbalẹ̀ pé kìí ṣe ọmọ Yorùbá àti pé kò le sọ èdè náà dáadáa, Rhodes-Vivour ní nǹkan tí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko ń fẹ́ ni ìṣèjọba rere láì fi èdè tàbí ẹ̀yà tí ènìyàn ti wà ṣe.

Rhodes-Vivour ní ọmọ ìpínlẹ̀ Eko tó jinlẹ̀ ni òun àti pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ ní àgbàyé tóun sì kajú òṣùwọ́n láti ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko.

Ó tẹ̀síwájú pé ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ ni àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko ń gbé láti ọjọ́ pípẹ́, pé àwọn olóṣèlú ló fẹ́ máa fi ẹlẹ́yàmẹ̀yà pín àwọn ènìyàn yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

Ó ní lára ohun tó jẹ́ àfojúsùn òun ni láti ri pé ìpínlẹ̀ Eko ṣiṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn àti pé gbogbo ìpèníjà àwọn “agbero” ni òun máa wá ojútùú sí.

Agbero ni orúkọ tó gbajúmọ̀ tí wọ́n ń pe àwọn ọmọ ìta tó máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn ọlọ́kọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko.

Bákan náà ló tún ṣe ìlérí pé àwọn máa pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ lójúnà àti fòpin sí àìníṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kìí ṣe ọ̀lẹ.

Rhodes-Vivour tún ṣèlérí pé tí òun bá di gómìnà Eko, gbogbo ètó ìlera, ẹ̀kọ́, ìpèsè omi àti ètò ìrìnnà ni yóò ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.