Plastic to Petrol: Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ọ̀rá àti ike tí ò ń sọ dànù le mú owó gọbọi wálé fún ọ?

Àkọlé fídíò, Plastic to Petrol: Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ọ̀rá àti ike tí ò ń sọ dànù le mú owó gọbọi wálé fún ọ?

Ni orilẹede Naijiria, ko si inu ile kan ti wọn kii ti lo ọra tabi ike, o le jẹ ọra tabi ike fẹlẹfẹlẹ ni tabi eyi to le.

Ni ọpọ igba, ẹgbin ati panti ni awọn ọra ati ike yii ma n jẹ ninu ile ati laarin ilu eyi ti onile kan ati ijọ maa n lo owo gọbọi lati palẹ wọn mọ.

Amọ ọpọ eeyan ni ko loye pe awọn ọra ati ike ta n pe ni panti yii si le wulo fun ipese awọn eroja miran to le mu owo gọbọi wale fun wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fun apẹrẹ, ara meeriri kan ree, ẹ wa wo awọn ọmọ iya meji, ti wọn jẹ tẹgbọn-taburo lo n palẹ awọn ike ati ọra yii mọ lati fi se epo Bẹntiroolu.

Bẹẹ ni! Ẹ mase jẹ ko ya yin lẹnu lati gbọ pe awọn ẹgbin ta n fi oju tẹnbẹlu wọn yii le mu owo nla wọle fun wa.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn ọmọ iya mejeeji naa, ti wọn jẹ ọmọ orukan sọ pe iku awọn obi awọn ati airi taje se lo sun awọn de idi imọ yii.

Bakan naa, wọn tun se alaye fun wa nipa awọn ọgbọn atinuda ti wọn n lo lati sọ ọra ati ike di epo bẹntiroolu.

Bi o tilẹ jẹ pe ipese epo naa ko tii burẹkẹ pupọ amọ wọn mẹnuba awọn ipenija to n koju wọn eyio ti ko jẹ ki wọn le pese epo naa lọpọ yanturu.

Koda, wọn tun salaye ọpọ anfaani ti lolo awọn ẹgbin yii lati sọ aatan dọrọ n mu ba awujọ wa ati ọna ti wọn fi n wa iranlọwọ lọdọ ijọba ati araalu.