Ẹni tí mo ṣe lóore ló gún mi lọ́bẹ ní ọrùn, gún ẹ̀gbọ́n mi ní apá – Portable

Oríṣun àwòrán, Collage
Gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikiola ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable, ti fẹsun kan awọn kan pe wọn na oun ati ẹgbọn oun obinrin nipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ile ọti rẹ to wa ni ipinlẹ naa ni ikọlu naa ti waye, ikọlu ọhun si pọ to bẹẹ ti ẹgbọn rẹ fi di ero ile iwosan.
Portable ṣafihan ẹgbọn rẹ ọhun nibi ti wọn ti n fa omi si lara, to si sọ pe awọn eeyan naa gun oun ni ọrun ati ni apa.

Oríṣun àwòrán, Portable
“Ẹni ti mo ṣoore fun ri lo gun mi”
Portable sọ pe ẹni mimọ oun ni ọkan lara awọn to kọlu oun, koda, oun ti ṣe iranlọwọ fun ẹni naa ri.
Portable ni “Nile aye yii, ti o ba ti n ṣe oriire, maa ṣora fun awọn eeyan nitori awọn eeyan ko fẹ ilọsiwaju ẹlomiran.”
“Ẹni to fi nkan gun mi yii, a ti wa ọjọ ti pẹ, mo ti ṣe loore ri.”
“Nigba to fun eeyan loyun, emi ni mo san owo ile iwosan ti mo tun ṣe ikomọ fun un... oun kan naa yii lo wa gun mi ni nnkan lori pe wọn n na ẹgbọn mi.”
”Ẹni to gun ni nnkan yii, mo ra alupupu fun o, alupupu naa ṣi lọwọ rẹ, mi o si gba kọbọ.”
Gẹgẹ bii iṣe rẹ, Portable binu pupọ to si n pariwo pe ọlọpaa maa ko gbogbo wọn.
Lẹyin naa lo gba awọn ololufẹ rẹ nimọran lati maa ṣọra fun awọn eeyan, paapaa lẹyin ti ọna wọn ba ti la tan.
Awọn ara adugbo fẹsun kan Portable pe o n dukoko mọ wọn

Oríṣun àwòrán, Portable
Ninu iroyin kan naa, awọn eeyan agbegbe ibi ti ile ọti Portble wa, ti fẹsun kan pe o n dukoko mọ awọn nitori pe o ti lowo lọwọ.
Wọn ni Portable wa si adugbo naa pẹlu awọn ọlọpaa ati aja lati wa halẹ mọ awọn lẹyin to ni awọn kan na ẹgbọn oun.
Ninu fidio kan loju opo Instagram, ni a ti ri awọn ọlọpaa kan pẹlu ọkọ, bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ ohun ti wọn n ṣe pato.
Amọ oniruru ẹsun lawọn eeyan ọhun fi kan Portable ninu fidio naa, ti awọn mii ninu wọn si n fi epe ranṣẹ si.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Portable yoo fa wahala pẹlu awọn ọrẹ tabi awọn eeyan agbegbe to n gbe.
Bo tilẹ jẹ pe Portable ti olowo lọwọ, o kọ lati kuro ni agbegbe to ti dagba, gbogbo igba to ba lọ sibẹ lo si maa n fun awọn eeyan agbegbegbe ọhun lowo to ba n kọja.















