Wo ohun tí Akeredolu ń ṣe láti rántí àwọn èèyàn tó kú lásìkò ìkọlù sí ṣọ́ọ̀ṣì Owo

Akeredolu ati ibudo iranti

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede pe ijọba oun ti bẹrẹ kikọ ibudo igbafẹ ni iranti awọn eeyan to ku lasiko ti awọn agbebọn kọlu Sọọsi Katoliki St Francis nilu Owo.

Atẹjade kan ti akọwe feto iroyin fun gomina Akeredolu, Richard Olatunde fi sita, eyi to wa loju opo Facebook gomina lo sisọ loju ọrọ yii lọjọ Satide lẹyin abẹwo to se sibi ti isẹ de duro nibudo iranti naa.

Akeredolu ni ibudo iranti naa, to wa ni aarin ilu Owo yoo jẹ oju ni gbese nigba to ba pari tan, to si leri leka pe ijọba oun ko ni gbagbe awọn eeyan to ba isẹlẹ isekupani naa rin.

O wa leri leka pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ẹni to se abẹwo silu Owo ni kete ti isẹlẹ naa waye, ni yoo wa si ibudo iranti naa nigba to ba pari tan.

"Bola Tinubu ni yoo wa si ibudo iranti naa lẹyin ọsẹ kan to ba gori aleefa bii aarẹ"

Akeredolu ni “Ko baa jẹ nigba ojo tabi ẹẹrun, ibudo igbafẹ iranti yii gbọdọ pari ni osu karun ọdun yii, ti aarẹ Naijiria tuntun, Bola Tinubu yoo si wa si lẹyin ọsẹ kan pere to ba gori oye.

A ti setan lati mase gbagbe eeyan mọkanlelogoji to ku lasiko isẹlẹ naa ati awọn eeyan miran to si n wo ọgbẹ ti wọn ni lasiko isẹlẹ ikọlu ọhun.

Obinrin kan tiẹ wa, ti wọn ge ẹsẹ rẹ mejeeji, ti a si ti pese ẹsẹ atọwọda fun eyi to ti n lo, ti eto imupadabọsipo rẹ si n lọ deedee, to si ti n gbe igbe aye bii ti tẹlẹ.”

Bakan naa ni atẹjade ọhun tun ni lara awọn ibudo miran ti yoo wa ni agbegbe ibudo igbafẹ iranti naa ni ibudo iko nnkan isẹmbaye lọjọ si.

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

'Iléeṣẹ́ tó bá kọ̀ láti gba owó àtijọ́ yóò di títì pa'

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe oun yoo gbe ileeṣẹ eyikeyi to ba kọ lati gba owo naira atijọ lọwọ awọn araalu ti pa.

Olubadamọran agba si gomina ipinlẹ naa lori akanṣe iṣẹ, Ọmọwe Doyin Odebowale lo sọ bẹẹ lori eto ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ kan nilu Akure.

O ni ẹnikẹni to ba kọ lati gba owo ₦500 ati ₦1000 atijọ yoo foju wina ofin.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, inira ti awọn eeyan n dojukọ lojojumọ lori ọrọ owo naa ko rọrun rara, ijọba yoo si ṣe gbogbo ohun to yẹ lati din iya awọn eeyan naa ku.

O fi kun pe gbogbo awọn awakọ ero ni ipinlẹ Ondo gbọdọ maa gba owo atijọ ọhun.

Ṣaaju ọrọ Odebowale yii ni gomina Oluwarotimi Akeredolu ti kọkọ ba awọn olugbe ipinlẹ Ondo sọrọ, nibi to ti parọwa si wọn pe wọn gbọdọ maa gba owo atijọ naa lọwọ ara wọn.

Akeredolu sọ ninu atẹjade rẹ pe niwọn igba ti ile ẹjọ ti dajọ pe ki awọn maa na owo naa, ko si ohun to ni ki awọn araalu ma gba owo ọhun.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, ko si anfaani ti yoo ṣe awọn araalu lati maa kọ owo naa laarin ara wọn.

O ni o lodi si ofin lati maa ko owo naa lẹyin ti ile ẹjọ ti ni o si ṣe itẹwọgba titi di opin ọdun yii.

Amọ ṣa, ọpọ arraalu lo ni awọn n kọ owo naa nitori awọn ẹlomiran n kọ laarin igboro, ati pe Aarẹ Buhari ati gomina CBN, Godwin Emefiele ko tii sọ nnkankan nipa rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn kan sọ, wọn ni awọn ile ifowopamọ ko gba owo naa lọwọ awọn.

Oṣiṣẹ ileeṣẹ ifowopamọ kan to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn ti ko owo naa sinu ẹrọ ATM wọn, amọ awọn araalu to gba ṣaaju ti n wọn pada si banki nitori bi awọn araalu ṣe kọ lati gba lọwọ wọn.